Àjọ NAFDAC fi òfin de òògùn 44 lọ́jà, wo bí o ṣe le dá wọn mọ̀

Akojọpọ oogun to wa ninu ṣibi ounjẹ

Oríṣun àwòrán, PHILIPPE HUGUEN

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ajọ to n mojuto ounjẹ ati oogun lorilẹede Naijiria, NAFDAC ti kede pe ohun ti fi ofin de awọn oogun kan lorileede Naijiria fun eto ilera araalu.

NAFDAC sọ pe awọn oogun naa, yatọ si pe wọn ko nii ta wọn mọ lawọn ile itaja oogun, bakan naa ni wọn ko gbọdọ ṣe wọn jade mọ, ati pe wọn ko gbọdọ ko polowo wọn rara.

Laipẹ yii ni ajọ NAFDAC kesi gbogbo ọmọ Naijiria pe ayederu oogun to le ṣe akoba nla fun ilera ti wa lọja, ati pe ki wọn ṣọra nipa irufẹ awọn oogun naa.

NAFDAC jẹ ko di mimọ pe ọwọ awọn ti tẹ awọn eeyan to wa nidi kiko awọn ayederu oogun ọhun lọ sita, ti wọn si ni awọn ti ti ṣọọbu ti wọn ti n ṣe e jade.

Ninu atẹjade ti ajọ naa gbe jade soju opo wọn lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun 2024, NAFDAC sọ pe awọn ti gba iwe aṣẹ lori awọn oogun naa.

"Eyi ni lati fi to gbogbo eeyan leti wi pe awọn ọja wọnyi lati buwọ lu lati gba iwe aṣẹ wọn, bẹẹ si lati fi ofin de tita wọn.

"Ni bayii, wọn ko ni aṣẹ mọ lati ṣe awọn oogun yii jade, ko wọn wọle tabi ko wọn jade, pin wọn kaakiri, ṣe ipolowo wọn, ta wọn tabi lo wọn mọ laarin Naijiria," NAFDAC ṣalaye.

Iru awọn oogun wo ni NAFDAC ko kuro lọja?

  • Abacavir Sulfate/Lamivudine, 60mg/30mg Tablets, pẹlu nọmba Nafdac - C4-1180, ti ileeṣẹ Healthline Limited ṣe
  • Amaryl M Tablets, pẹlu nọmba Nafdac - A4-2619, ti ileeṣẹ Sanofi Aventis Nigeria ltd ṣe
  • Amaryl M SR Tablets - A4-7296, ti ileeṣẹ Sanofi Aventis Nigeria ltd ṣe
  • Aprovasc 150mg/5mg tablets, pẹlu nọmba Nafdac - B4-2687, ti ileeṣẹ Sanofi Aventis Nigeria ltd ṣe
  • Artemether/Lumefantrine 40mg/240mg Tablets, pẹlu nọmba Nafdac - B4-5745, ti ileeṣẹ Healthline Limited ṣe
  • ASAQ(Artesunate amodiaquine Winthrop) 100mg/270mg Tablets, pẹlu nọmba Nafdac - A4-3357, ti ileeṣẹ Sanofi Aventis Nigeria ltd ṣe
  • ASAQ(Artesunate amodiaquine Winthrop) 25mg/67.5mg Tablets, pẹlu nọmba Nafdac - A4-3406, ti ileeṣẹ Aventis Nigeria ltd ṣe
  • ASAQ(Artesunate amodiaquine Winthrop) 50mg/135mg Tablets, pẹlu nọmba Nafdac - A4-3405, ti ileṣẹ Sanofi Aventis Nigeria ltd ṣe
  • Betopic Eye drop, pẹlu nọmba Fadac - 04 2404, ti ileeṣẹ Novartis ṣe
  • Coaprovel 300mg/25mg Tablets, pẹlu nọmba Nafdac - B4-2317, ti ileeṣẹ Sanofi Aventis Nigeria ltd ṣe
  • Combination 3 Tablets, pẹlu nọmba Nafdac - A4-6459, ti ileeṣẹ Bayer East Africa Limited ṣe
  • Efavirenz 600mg Tablets, pẹlu nọmba Nafdac - A4-1318, ti ileeṣẹ Healthline Limited ṣe

Awọn oogun to ku ni

  • Elisca eye drop, pẹlu nọmba Nafdac – 2461, ti ileeṣẹ Sanofi Aventis Nigeria ltd ṣe
  • Flagyl Suspension, pẹlu nọmba Nafdac - A4-3947, ti ileeṣẹ Sanofi Aventis Nigeria ltd ṣe
  • Flagyl Tablet 400mg, pẹlu nọmba Nafdac - 04 5566, ti ileeṣẹ Sanofi Aventis Nigeria ltd ṣe
  • Iliadin Adult 0.05% Metered Nose Spray, pẹlu nọmba Nafdac - B4-9913, ti ileeṣẹ Fensyl MHP Consulting Ltd ṣe
  • Iliadin baby 0.01% nose drops, pẹlu nọmba Nafdac - C4-0106, ti ileeṣẹ Fensyl MHP Consulting Ltd ṣe
  • Iliadin kids 0.025% nose drops, pẹlu nọmba Nafdac - B4-9912, ti ileeṣẹ Fensyl MHP Consulting Ltd ṣe
  • Invanz 1g Injections, pẹlu nọmba Nafdac - 04 8118, ti ileeṣẹ MSD Idea Pharmaceuticals Nigeria LTD ṣe
  • Invega (Paliperidone) 3mg extended release tablets, pẹlu nọmba Nafdac - B4-8223, ti ileeṣẹ Janssen Pharmaceutical Companies ṣe
  • Invega (Paliperidone) 6mg extended release tablets, pẹlu nọmba Nafdac - B4-8222, ti ileeṣẹ Janssen Pharmaceutical Companies ṣe
  • Invega(Paliperidone) 9mg extended release tablets, pẹlu nọmba Nafdac - B4-8221, ti ileeṣẹ Janssen Pharmaceutical Companies ṣe
  • Janumet 50mg/1000mg Tablets, pẹlu nọmba Nafdac - B4-1771, ti ileeṣẹ MSD Idea Pharmaceuticals Nigeria LTD ṣe
  • Janumet 50mg/850mg Tablets, pẹlu nọmba Nafdac - B4-1637, ti ileeṣẹ MSD Idea Pharmaceuticals Nigeria LTD ṣe
  • Januvia 100mg Tablets, pẹlu nọmba Nafdac - B4-0023, ti ileeṣẹ MSD Idea Pharmaceuticals Nigeria LTD ṣe
  • Januvia 50mg Tablets, pẹlu nọmba Nafdac - B4-0335, ti ileeṣẹ MSD Idea Pharmaceuticals Nigeria LTD ṣe
  • Kombiglyze 2.5mg/1000mg tablets, pẹlu nọmba Nafdac - A4-9646, ti ileeṣẹ AstraZeneca ṣe
  • Kombiglyze 5mg/1000mg tablets, pẹlu nọmba Nafdac - A4-9645, ti ileeṣẹ AstraZeneca ṣe
  • Lamivudine/Nevirapine/Zidovudine 150mg/200mg/300mg, pẹlu nọmba Nafdac - A4-2813, ti ileeṣẹ Healthline Limited ṣe
  • Lamivudine/Nevirapine/Zidovudine 30mg/50mg/60mg, pẹlu nọmba Nafdac - A4-1319, ti ileeṣẹ Healthline Limited ṣe
  • Lexotan 3mg Tablets, pẹlu nọmba Nafdac - 04 8808, ti ileeṣẹ F. Hoffmann-La Roche Ltd. Basel, Switzerland ṣe
  • Mosegor Syrup Syrup, pẹlu nọmba Nafdac - 04 8106, ti ileeṣẹ Novartis ṣe
  • Nevirapine Tablets 200mg Tablets, pẹlu nọmba Nafdac - A4-1431, ti ileeṣẹ Healthline Limited ṣe
  • Onglyza 2.5mg tablets, pẹlu nọmba Nafdac - A4-8864, ti ileeṣẹ AstraZeneca ṣe
  • Onglyza 5mg tablets, pẹlu nọmba Nafdac - A4-8863, ti ileeṣẹ AstraZeneca ṣe
  • Penicillin G Sodium Sandoz Powder for Solution for Injection, pẹlu nọmba Nafdac - B4-6367, ti ileeṣẹ Novartis ṣe
  • Salbutamol 100mcg Inhaler, pẹlu nọmba Nafdac - B4-8493 ti ileeṣẹ Novartis ṣe
  • Sporanox (Itraconazole) 100mg capsule, pẹlu nọmba Nafdac - 04 2404, ti ileeṣẹ Worldwide Healthcare ṣe
  • Xyzal Oral Drops, pẹlu nọmba Nafdac - B4-9691, ti ileeṣẹ GlaxoSmithKline Pharmaceutical Nigeria Ltd ṣe
  • Zidovudine 300mg Tablets, pẹlu nọmba Nafdac - A4-1314, ti ileeṣẹ Healthline Limited ṣe
  • Uptivite Man Tablets, pẹlu nọmba Nafdac - A7-101014L, ti ileeṣẹ Gentlehills Limited ṣe
  • Mist Alba Suspension, pẹlu nọmba Nafdac - A11-0871, ti ileeṣẹ Gentlehills Limited ṣe
  • Gentle Hill Cough Syrup, pẹlu nọmba Nafdac - A11-0872, ti ileeṣẹ Gentlehills Limited ṣe
  • Gentlehills Vitamin C Syrup, pẹlu nọmba Nafdac - A11-0936, ti ileeṣẹ Gentlehills Limited ṣe

Ewu to wa ninu lilo ayederu oogun

Abajade iwadii ti London School of Hygiene and Tropical Medicine sẹ fun ajọ ilera l'agbaye, WHO, sọ pe ayederu oogun, paapaa oogun iba, le fa 116,000 iku lọdọọdun ni ilẹ olooru Africa.

Lọdun 2015 nikan, ẹka ajọ naa ni America sọ pe o le ni 122,000 ọmọde ti ọjọ ori wọn wa labẹ ọdun marun un, to ku nitori atederu ati oogun iba ti ko pojuowo ni ilẹ olooru Africa., lara eyi ti Naijiria wa.

Yatọ si iku aitọjọ, ayederu ati oogun ti ko pojuowo le fa awọn aisan miran ti ko si ninu agọ ara tẹlẹ.