Ìdí tí Tinubu àti ilé ìgbìmọ aṣòfin ṣe dá ìjíròrò dúró lórí àbá òfin owó orí tuntun

Aare ile igbimọ aṣofin Naijiria

Oríṣun àwòrán, Nigerian Senate/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

L’Ọjọru, ọsẹ yii, ile igbimọ aṣofin Naijiria kede wi pe awọn ti n ṣiṣẹ lori erongba ofin tuntun nipa owo ori sisan, eyi ti Aarẹ Bola Ahmed Tinubu gbe lọ siwaju wọn.

Igbakeji Aarẹ ile igbimọ aṣofin, Barau Jibrin – lo dari ijokoo naa – lo ṣe ikede yii lasiko ipade wọn waye.

Jibrin tun kede wi pe awọn ti gbe igbimọ ti yoo ṣatupalẹ iwe ofin tuntun owo ori naa lati ṣe awọn atunṣe lori rẹ, pẹlu bo ‘se n fa awuyewuye, paapaa lati ẹkun Ariwa Naijiria.

Lọsẹ to kọja, ipinnu mẹrin ti wọn fẹnu ko si lo gba ipele kika keji kọja nile igbimọ aṣofin, ko to di pe Aarẹ ile igbimọ naa, Godswill Akpabio gbe owo silẹ fun igbimọ to n ṣiṣẹ lori rẹ, ṣaaju ipele kika kẹta, gẹgẹ bi ofin ile igbimọ naa ṣe la a kalẹ.

“Inu wa dun wi pe Aarẹ gbọ ohun ti araalu n sọ, ṣugbọn o ṣee ṣe ka ma ni eredi lati buwọ lu ipinnu naa,” Sẹnetọ Abdul Ningi lo sọ eyi ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu BBC lẹyin ti wọn gbe ipinnu naa kalẹ.

Lara awọn sẹnetọ to wa ninu igbimọ yii lati ri Sẹnetọ Titus Zam lati ipinlẹ Benue; Sẹnetọ Orjir Uzor Kalu lati ipinlẹ Abia; Sẹnetọ Sani Musa lati ipinlẹ Niger, ati Sẹnetọ Abdullahi Yahaha lati ipinlẹ Kebbi.

Eyi lo waye lẹyin ọjọ kan ti Aarẹ Tinubu paṣẹ pe ki minisita fọrọ iṣẹ ode ṣiṣẹ papọ pẹlu ile igbimọ aṣoju-ṣofin lati ṣagbeyẹwo awọn agbegbe to n fa awuyewuye ninu iwe ofin naa.

Ipinnu lori iwe ofin naa lo ti n fa awuyewuye ati ariyanjiyan kaakiri orileede Najiria, nigba ti awọn apa kan ni Naijiria ti n sọ pe wi pe lara awọn ohun to wa ninu iwe ofin owo ori tuntun naa yoo ṣakoba nla fun awọn apa kan nilẹ naa.

Ki lo de ti Tinubu sọ pe ki wọn ṣi duro?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Nirọlẹ ọjọ Iṣẹgun, minita feto iroyin ni Naijiria, Mohammed Idris, gbe atẹjade sita wi pe Aarẹ ti paṣẹ pe ki minisita feto idajọ lati dari ile igbimọ aṣofin lati ṣagbeyẹwo ofin naa.

Atẹjade ọhun sọ pe Tinubu tẹwọgba ‘ariyanjiyan alalaye’ to n lọ nigboro, to si tọka si awọn ohun to wa ninu aṣẹ naa, to fi mọ awọn “iroyin ẹlẹjẹ to n lọ kaakiri” lori ofin naa.

“O yẹ ki ẹ mọ irọ ati iroyin ẹlẹjẹ ti n lọ kaakiri nipa ile igbimọ aṣofin ati awọn ofin pẹlu ilana ti ijọba Tinubu n gbe kalẹ.

“O dara lati mọ pe ko si igbimọ ọtẹ kankan ti ijọba gbe kalẹ, to jẹ ki n ro pe ohun to fa iyara lati bẹrẹ sii ṣiṣẹ pẹlu ofin naa niyan.

“Idi ree ti Aarẹ Tinubu ṣe paṣẹ fun ileeṣẹ apapọ to n ri sọrọ ofin ati awọn oṣiṣẹ rẹ ti wọn ṣiṣẹ lori ipinnu ofin naa, lati ṣiṣẹ papọ pẹlu ile igbimọ aṣofin, lati rii pe gbobo ohun to n fa awuyewuye dopin, ko to di pe wọn buwọ lu.”

Ileeṣẹ naa tẹnumọ ọn wi pe ofin yii “ko nii ṣe ipalara fun eyikeyi ipinlẹ tabi ẹkun lorileede yii tabi ko fa iparun fun eyikeyi ileeṣẹ ijọba kankan”

‘Ko tii to asiko to yẹ’

Lọsẹ to kọja, ẹgbẹ awọn aṣofin kan lẹkun Ariwa Naijiria sọ pe awọn pinnu lati gbe ofin naa sẹgbẹ kan ni kete to di ariyanjiyan nile igbimọ wọn.

Sẹnetọ Abdul Ningi to n ṣoju ẹkun aarin gbungbun Bauchi sọ fun BBC pe kii ṣe pe awọn n sọrọ lori ki wọn pa ofin ọhun ti nikan.

“Ko yẹ ki wọn tii gbe ofin naa wa bayii... kii ṣe ọrọ wi pe wọn da ofin naa duro, niṣe la n tako igba ti wọn gbe ofin owo ori tuntun naa wa,” gẹgẹ bi sẹnetọ PDP ọhun ṣe sọ.

“Ohun to yẹ ka sọrọ le lori ni, a si ti ri awọn idi rẹ bayii. Ko si idi pataki to fi yẹ ki wọn gbe ọrọ owo ori wa nigba ti wọn ti yọ owo iranwọ ori epo, owo dọla ti lọ soke, bawo ni eeyan ẹlẹran ara ṣe le ṣe eyi? ile aye ko ri bẹẹ”

Sẹnetọ Ali Ndume naa ṣalaye ohun mẹta to sọ pe o jẹ idi pataki toun fi tako ofin naa, eyi to sọ pe erongba oun ko tii yipada.

“Akọkọ, wọn ko tii ba awọn gomina ati awọn adari wa sọrọ. Ẹlẹẹkeji, kii ṣe asiko yii lo yẹ ka maa sọrọ owo ori. Ẹlẹẹkẹta, ọrọ wi pe ka pin alekun owo (VAT) tako iwe ofin,” sẹnetọ APC lo sọrọ naa.

Ki ni awọn ipinnu owo ori sisan?

Ni ibẹrẹ oṣu Kẹwaa, ọdun yii, Bola Tinubu fi awọn aba mẹrin kan ranṣẹ sile igbimọ aṣofin lati buwọ lu.

Erongba wọn ni lati ṣatunṣe lori ọna ti wọn n gba lati gba owo ori to n wọle, ati bi wọn ṣe n pin in ni Naijiria nipaṣe bi wọn ṣe da awọn ileeṣẹ kan silẹ ati ayipada awọn ileeṣẹ ijọba kan.

Awọn ipinnu naa ni:

Abadofin owo ori ọdun 2024 (Nigeria Tax Bill 2024).

Abadofin iṣakoso owo ori (Tax Administration Bill).

Abadofin ipawowọle ni Naijiria (Nigeria Revenue Service Establishment Bill (new law).

Abadofin lori igbimọ apapọ fun pipawowọle (Joint Revenue Board Establishment Bill).