Olùkọ́ dèrò àtìmọ́lé lẹ́yìn tí ẹgba ọwọ́ rẹ̀ fọ́ ojú akẹ́kọ̀ọ́ ní ìpínlẹ̀ Ogun

School

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti sọ pe oun ti fi ṣikun ofin mu olukọ kan lẹyin to ṣe ipalara fun akẹkọọ kan, eyi to mu ki akẹkọọ ọhun padanu oju rẹ ọtun.

Ile ẹkọ Owiwi Nursery and Primary School, to wa ni Obada Oko ni iṣlẹ ọhun to waye.

Ipele kẹfa ni akẹkọọ naa, Alao Idera, to jẹ ọmọ ọdun mọkanla wa.

A gbọ akẹkọọ ipele kẹrin ni fasiti Tai Solarin, to wa niluu Ijebu-Ode ni olukọ naa, Adeola Adeyemo, wa.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ṣe ni olukọ ọhun n ṣe iṣẹ isin gẹgẹ bii olukọ to n kọ iṣẹ lọwọ nile ẹkọ ti iṣẹlẹ naa ti waye.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Omolola Odutola, ti fidi iroyin naa mulẹ fun awọn akọroyin.

Nigba to n ṣalaye bi ọrọ naa ṣe waye, Odutola sọ pe ṣe ni Adeyemo mu ẹgba kan dani ninu iyara ikẹkọọ, asiko ti awọn akẹkọọ rẹ n sare wa siwaju rẹ ni ẹgba to mu dani gun oju Idera.

Ọlọpaa ni kete lẹyin iṣẹlẹ naa ni wọn gbe Idera digbadigba lọ ile iwosan ijọba apapọ, FMC, to wa niluu Abeokuta.

Nigba yi wọn fi deld iwosan, ẹgab to gun oju akẹkọọ naa ti ba oju ọhun jẹ, eyii to mu ki awọn dokita yọ ẹyin oju naa kuro.

Odutola pari ọrọ rẹ pe awọn ti fi ṣikun ofin mu olukọ naa bayii, o si ti wa ahamọ awọn fun iwadii.