Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Àkójọpọ̀ àwọn ìròyìn káàkiri Nàìjíríà tí kò ṣe é má gbọ̀ ọ́.
Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́

Awaye 'ku o si, ọrun nikan lare ma bọ

Bẹẹ ni, amọ, ta lo ku?

Ilumọọka alfa to tun jẹ olukọ ẹsin Islam, Sheik Muyideen Ajani Bello, lo jade laye

Alhaji Taofeeq Akeugba Gold sọ fun BBC Yoruba pe owurọ ọjọ Ẹti ni Sheikh Bello jẹ Ọlọrun ni pe ni ile rẹ to wa niluu Ibadan.

K'Eledua dẹlẹ fẹni 're to lọ'

'''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''

Iroyin to tẹ wa lọwọ lati ipinlẹ Kano ti sọ pe

Awọn ẹṣọ eleto aabo duro wamu wamu siwaju aafin Emir ilu Kano

Ti wọn ko si jẹ ki ẹnikẹni wọle tabi jade lati inu aafin naa

Ki lo n ṣẹlẹ gan an?

Kan soju opo BBC.Com/Yoruba fun ẹkunrẹrẹ iroyin naa

''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''

Ẹ fura o, irufẹ oogun ayederu mẹrinlelogoji lajọ NAFDAC ti fofin de ni Naijiria

NAFDAC ni ọwọ awọn ti tẹ awọn eeyan to n kawọn ayederu oogun ọhun wọle

Ajọ naa ni, ayederu oogun le fa awọn aisan miran ti ko si ninu agọ ara tẹlẹ yatọ si iku aitọjọ

Bawo laraalu ṣe le dawọn oogun naa mọ?....ẹ kan si wa...