Sheik Muyideen Ajani Bello ti kú

Muyideen Ajani Bello

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Agba Alfa, to tun jẹ olukọ ẹsin Islam, Sheik Muyideen Ajani Bello, ti ku.

Owurọ ọjọ Ẹti ni iroyin jade pe Ajani Bello jade laye.

Ninu ọrọ to ba BBC Yoruba sọ, gbajugbaja Alfa ati olukọ ẹsin Islam, Alhaji Taofeeq Akeugba Gold, sọ pe owurọ ọjọ Ẹti, ọjọ kẹfa, oṣu Kejila, ọdun 2024 ni baba naa jade laye ni ile rẹ to wa niluu Ibadan.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, oloogbe Bello ti sun mọ ẹni aadọrun ọdun, ki ọlọjọ o to o de.

Irọlẹ oni ni isinku rẹ yoo waye ni ilana ẹsin Islam.

Ọkan lara ẹbi oloogbe sọ fun BBC pe, baba sẹ aisan ranpẹ ko to o ku.

A o maa ṣe afikun iroyin yii bi a ṣe n ko o jọ.

Nnkan to yẹ ki o mọ nipa Sheik Muyideen Ajani Bello

Ogbontarigi ni Sheik Muyideen Ajani Bello ninu ẹkọ ati imọ ẹsin Islam.

Ọmọ bibi ilu Ibadan, nipinlẹ Oyo si ni pẹlu.

Iroyin sọ pe apa Ariwa ni baba naa gbe fun eyi to pọ ninu igbeaye rẹ, ko to o fi ilu Ibadan ṣe ibugbe lati nnkan bi ogun ọdun sẹyin.

Bakan naa ni awọn akọsilẹ kan sọ pe ọmọ ọdun mẹwaa ni Bello wa to ti bẹrẹ sii ṣe waasi.

Baba rẹ to gbajumọ daadaa nigba naa labule Agberigbe, to wa niluu Iwo lo kọ ọ ni keu.

Muyideen Ajani Bello ni iroyin sọ pe o ṣiṣẹ olukọ ni Ansa-ru-deen College to wani Saki, ipinlẹ Oyo.

Sheik Ajani Bello tun ṣiṣẹ gẹgẹ bi olukọ nile ẹkọ girama kan niluu Abẹokuta, nibi to ti kọ iṣiro ati Biology