Ọlọ́pàá mú afurasí babaláwo méjì tó fẹ́ẹ́ fi òògùn abẹnugọ̀ǹgọ̀ dán ààrẹ wò

Babaláwo kan tó ń lo oogun

Oríṣun àwòrán, Eric Lafforgue/Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn ọkunrin meji kan ti bọ sọwọ ọlọpaa lorilẹede Zambia bayii, lori ẹsun pe wọn fẹẹ fi asasi ṣe jamba fun aarẹ orilẹede naa, Hakainde Hichilema.

Ọgbẹni Jasten Mabulesse Candunde ati Leonard Phiri ni wọn fi ọwọ ofin mu ni Lusaka ti i ṣe olu-ilu orile-ede naa lori ẹsun ọhun.

Gẹgẹ bi atẹjade ti awọn ọlọpaa ibẹ fi sita lọjọ Ẹti, ogunjọ oṣu Kejila ọdun 2024 ṣe wi, " iṣẹ ti wọn waa ṣe ni lati fi oogun ṣe jamba fun Aarẹ Hakainde''

Ni apa Guusu ilẹ Africa yii, ọpọ eeyan lo ṣi ni igbagbọ ninu pe ajẹ wa, ati pe wọn le pa awọn.

''Oogun abẹnugọngọ ọlọkan-o-jọkan la ba lọwọ awọn ta a mu yii, koda, ọ̀gà (Chamelion) ti ko ti i ku gan-an wa lara ohun ti wọn gbe dani''

Atẹjade awọn ọlọpaa naa lo sọ bẹẹ.

Wọn fi kun un pe awọn afurasi naa jẹwọ pe, awọn to ran wọn niṣẹ naa ṣeleri lati fun wọn ju miliọnu meji owo Zambia lọ, bi wọn ba ri lo fun Hakainde Hichilema.

Ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe awọn ọkunrin meji naa ṣi wa lahaamọ, wọn yoo foju ba ile-ẹjọ laipẹ.

Wọn ni wọn yoo jẹjọ ẹsun pe oṣó ni wọn, nini oogun lọwọ, ati hihu iwa ika si ẹranko inu igbo ti wọn gbe dani.

Ta a ló rán àwọn afurasí níṣẹ́ láti ṣe jamba fun ààrẹ?

Hakainde Hichilema.

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Aarẹ Zambia,Hakainde Hichilema.

Atẹjade ọlọpaa lori ẹni to fẹẹ fi oogun ẹlẹyẹ dan aarẹ wo, sọ pe Nelson Banda, aburo Jay Jay Banda ti i ṣe ọmọ ile igbimọ aṣofin Zambia lo ran wọn.

Wọn ni ọlọpaa mu Jay Jay Branda ni Zimbabawe to jẹ alamuleti fun Zambia lori ẹsun idigunjale.

Ọlọpaa ṣalaye pe Jay Jay ko gba pe oun digunjale, ṣugbọn ko sẹni to ri i nigboro lati igba naa.

Bakan naa ni wọn fẹsun kan an, pe o sa lahaamọ ti wọn fi i si loṣu Kẹjọ.

Wọn ni Nelson paapaa ti na papa bora.

Ṣugbọn awọn awoye ọrọ sọ pe bi wọn ṣe mu awọn afurasi yii ni ọwọ kan oṣelu ninu.

Olori ẹgbẹ oṣelu alatako, Patriotic Front; Edgar Lungu, sọ pe ète oṣelu ti wọn hun papọ leyi, o ni ko si otitọ nibẹ.