Ọ̀rọ̀ taa ni yóò jẹ Owa Obokun tuntun n'Íléṣà dá wàhálà sílẹ̀ láàrin àwọn ọmọ oyè

Oríṣun àwòrán, Other
Ile-ẹjọ giga tipinlẹ Osun ti da Gomina Ademola Adeleke, ati awọn afọbajẹ ilu Ilesa lọwọ kọ lati yan Owa Obokun tuntun fun ilẹ Ijesa.
Ọmọọba Debo Adeyemi ati awọn mẹwaa miran ni wọn pe ẹjọ lorukọ mọlẹbi Ofokutu ti agboole Bilaro Oluodo.
Awọn ti wọn pe lẹjọ ni Gomina Ademola Adeleke; Obanla ilu Ijesa, Oloye Folorunso Adeniyi, ati awọn afọbajẹ mọkanla; igbimọ ọba alaye nilẹ Ijesa; Kọmiṣanna feto idajọ, to fi mọ Kọmiṣanna fọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ.
Eyi waye lẹyin ti Owa Obokun tẹlẹ, Oba Adekunle Aromolaran papoda lọjọ kejila, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2024 Ọjọ kejila, lẹni ọdun mẹrindinlaadọrun un.

Oríṣun àwòrán, Ademola Adeleke/X
Awọn olufẹsunkan naa n rọ ile-ẹjọ lati da Adeleke, awọn aṣoju rẹ, to fi mọ awọn afọbajẹ ilẹ Ijesa lọwọ kọ lati yan Haastrup tabi ẹnikẹni gẹgẹ bi Owa Obokun tilẹ Ijesa titi digba ti ile-ẹjọ yoo fi gbe idajọ kalẹ lori ipo naa.
Onidajọ A. Aderibigbe, lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kejila, ọdun 2024 ti wa a paṣẹ pe ki awọn olujẹjọ to wa ninu iwe ẹsun naa dawọ duro lati yan ọba tuntun fun ipo Owa Obokun.
Bakan naa lo tun igbẹjọ siwaju si ọjọ kẹrinla, oṣu kinni, ọdun 2025.
Taani Olumobi Haastrup ti awuyewuye rẹ n kaakiri?
Ọkan lara awọn ọmọ to gbajumọ daadaa ninu idile ọba ti Ajimoko Haastrup Bilaro ni Ọmọwe Olumobi Haastrup to ti fi erongba rẹ han lati du ipo ọba Owa Obokun to ṣi silẹ nilẹ Ijesa.
Ikede ọhun lo waye lẹ lẹyin ti gbogbo eto ati ilana etutu ti pari lori ọba ana, Ọba Gabriel Adekunle Aromolaran to waja ti pari lọjọ kẹwaa, oṣu Kejila, ọdun 2024.
Ninu atẹjade ti akọle rẹ jẹ "Ikede Atokewa", eyi to tunmọ si 'Divine Declaration" ti wọn gbe jade lọjọ kejila, oṣu Kejila, eyi ti wọn fi ranṣẹ sawọn akọroyin lọjọ Aiku to kọja, Haastsrup jẹ ko di mimọ pe oun ti farajin fun idagbasoke ati ilọsiwaju ilẹ Ijesa lapapọ, to si ṣeleri pe oun yoo mu ilu naa de ipo giga gẹgẹ bi ọba alaye.
Oun ni olori ẹbi agboole Imobi Ijesa lati bii ọdun meje aabọ sẹyin.
Ohun to yẹ ki o mọ nipa ipo Owa Obokun
Ọkan pataki lara awọn ilu to wa nipinle Osun ni ilu Ilesa, to wa lara awọn ilu to wa ni ilẹ Ijẹṣa. Pupọ awọn ilu naa lo je pe wọn n pe orukọ Ijesa mọ wọn lara. Lara wọn si ni: Erin-Ijesa, Ijeda-Ijesa, Ipetu-Jesa, Ijebu-Jesa, Ipole-Ijesa, Ifewara-Ijesa, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ilu Ileṣa si lo jẹ olu-ilu fun gbogbo awọn ilu miran to wa nilẹ Ijẹṣa.
Gẹgẹ bi awọn akọsilẹ kan ṣe sọ, ọdun 1300 ni wọn da ilẹ Ijesa silẹ. Ajibogun Ajaka Owa Obokun Onida Raharaha to jẹ jagunjagun alagbara, ẹni to jẹ ọmọ-ọmọ Oduwuwa lo da ilu Ijesa silẹ, ṣugbọn Owulase to jẹ ọmọ-ọmọ Ajibogun Ajaka lo fi orukọ Ilesa lelẹ.
Eyi lo fi jẹ pe bi wọn ṣe n pe ilu naa ni Ijesa naa ni wọn tun n pe e ni Ilesa labẹ akọsilẹ ofin.
Ajibogun Ajaka jẹ Owa Obokun Adimula laarin ọdun 1150 si ọdun 1255; Awoka Okile lo jẹ lẹyin rẹ laarin ọdun 1260 si ọdun 1358. Obarabara Olokun Ẹṣin jẹ lọdun 1360 si ọdun 1459.
Awọn miran to tun ti jẹ Owa Obokun ni:
Owa Owari (1466 - 1522)
Owa Owaluse (1522 - 1526)
Owa Atakunmosa (1526 - 1546)
Yeyelagagba (1588 - 1590)
Yeyegunrogbo (1588 - 1590)
Owa Biladu I (1652 - 1653)
Owa Biladu II (1653 - 1681)
Yeyewaji (1681)
Owa Bilaro (1681 - 1690)
Owa Bilayiarere (1691 - 1692)
Owa Bilagbayo (1713 - 1733)
Yeyeori (1734 - 1749)
Awọn miran tun ni:
Ori Abejoye
Owa Bilajagodo "Arijelesin"
Owa Bilatutu "Otutu bi Osin" (1772 - 1776)
Owa Bilasa "Asa abodofunfun" (1776 - 1788)
Owa Akesan (1788 - 1795)
Owa Bilajara
Ogbagba (1807–1813)
Obara "Bilajila" (1813–1828)
Owa Odundun (1828–1833)
Gbegbaaje (1833–1839)
Ariyasunle (Adele - 1839)
Owa Ofokutu (1839–1853)
Ariyasunle (Adele fun igba keji -1853)
Owa Aponlose (1858 –1867)
Owa Alobe (1867–1868)
Agunlejika kinni lo jẹ laarin ọdun 1868 si 1869; Oweweniye naa jẹ lọdun 1871 s'ọdun 1875; 1875 ni Bepolonun jẹ ko to waja lọdun 1893; Alowolodu lo gba ipo naa l'oṣu kẹta ọdun 1893 si oṣu kọkanla ọdun 1894; Ipo naa ṣofo latigba naa titi di oṣu kẹrin ọdun 1896 ti Ajimoko kinni jẹ, to si jẹ titi di oṣu kẹsan-an ọdun 1901; Atayero lo ọdun mọkandinlogun laarin ọdun 1901 si 1920; Aromolaran akọkọ je lọdun 1920 si 1942.
Aarin ọdun 1942 naa ni wọn tun yan iyawo Ajimoko gege bi adele oba, toun je titi di osu kesan-an ọdun naa.
Ojo kewaa osu kesan-an ọdun 1942 ni iwon yan Fidipote Ajimoko keji to je titi ojo kejidinlogun osu kewaa ọdun 1956. Ojo naa ni won ti yan J. E. Awodiya gege bi adele oba, to si je adele wo ọdun 1957. Fiwajoye Ogunmokun to jẹ Biiladu kẹta lo jẹ lọdun 1957 si oṣu keje ọdun 1963.
Adele ni wọn tun yan l'oṣu keje ọdun 1963 naa titi ọdun 1966 ti wọn fi ri Ọba Peter Adeniran Olatunji Agunlejika keji to jẹ titi oṣu kẹsan ọdun 1981. Ipo naa ṣofo, wọn to yan adele titi ti wọn fi ṣawari Ọmọọba Gabriel Adekunle Aromolaran keji lọdun 1982.
Ilu Ileṣa nikan kọ ni ọrọ ọba jijẹ ti n fa awuyewuye.
Niluu Oyo nipinlẹ Oyo, wọn ko tii fi Alaafin tuntun jẹ lati bi dun meji ti Alaafin ana, Ọba Lamidi Adeyemi, ti waja.
Eyi ko ṣẹyin wahala to n waye laarin awọn ọmọ idile to n jọba, ti ọrọ naa si ti di ti ile-ẹjọ.












