Òkú sùn níbi fàájì òpin ọdún tí Olori Naomi Ogunwusi ṣe f'áwọn ọmọdé nílùú Ibadan

Aworan ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye pẹlu aṣọ ati bata nilẹ

Oríṣun àwòrán, BBC/Naomi Ogunwusi

    • Author, Busayo James-Olufade
    • Role, Senior Journalist
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

O kere tan, ọmọde kan ku, ti ọpọ si farapa, nibi apejẹ ti olori Ooni Ile-Ife tẹlẹ, Naomi Ogunwusi, ṣe niluu Ibadan.

Ọjọru, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kejila, ọdun 2024, ni eto naa yẹ ko waye, amọ gbogbo rẹ ti foriṣanpọn nitori ohun to ṣẹlẹ

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ fun BBC Yoruba pe ko tii pẹ ti eto bẹrẹ, ti awọn eeyan fi bẹrẹ si ni tẹ ara wọn.

Awọn iroyin kan to n lọ lori ayelujara sọ pe ọmọ bii mẹrin lo ku, amọ BBC ko tii le fidi eyi mulẹ.

Bakan naa ni ọkan lara awọn ọga nileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo, amọ ti ko fẹ ka darukọ rẹ nitori pe ko ni aṣẹ lati ba akọroyin sọrọ, sọ fun akọroyin wa pe, ọmọ mẹta lo ku, ti pọ si wa nileewosan.

O ni eero to pọju, to mu ki awọn eeyan maa ti ara wọn, lo fa isẹlẹ buruku naa.

Lara oun ti awọn eeyan n sọ ni pe, kaakiri awọn ilu to sun mọ Ibadan ni awọn eeyan ti wa fun eto ayẹyẹ opin ọdun naa, paapaa lẹyin ti wọn gb ikede rẹ lori gbajugbaja redio kan to wa niluu Ibadan, lọsan Iṣẹgun.

Awọn kan ti ẹ sun si inu ọgba ile-ẹkọ Islamic High School, to wa ni agbegbe Bashorun, nibi ti eto naa ti waye, mọju.

Titi di akoko yii, awọn alakoso eto naa ko tii sọ ohunkohun lori iṣẹlẹ yii.

Igba akọkọ kọ ree ti Olori Naomi Silekunola Ogunwusi ṣe eto apejẹ naa.

Ọdọọdun lo maa n ṣe e labẹ ajọ ẹlẹyinju aanu rẹ to pe ni, Women in Need of Guidance and Support (WINGS).

Aworan eto naa

Taa ni Naomi Ogunwusi?

Olori Naomi ati Ooni Ogunwusi

Oríṣun àwòrán, Others

Silekunola Naomi ni iyawo alarede ikeji ti Ooni Ile-Ife, Ọba Adeyeye Ogunwusi, fẹ niṣu lọka.

Ṣáájú ìgbéyàwó wọn lọdun 2018, Ooni fi oju olólùfẹ́ rẹ han to si ni oun ti ri aayo ọkan oun to si juwe rẹ gẹgẹ bii Woli.

Asiko naa ni okiki arabinrin naa kan kaakiri agbaye nitori awọn eeyan n woye pe bawo ni ojisẹ Ọlọrun to maa n ṣe awọn eto igbagbọ oniruuru pẹlu isẹ ami àti iyanu yoo ṣe yàn lati lọ fẹ Ọba to n b'òrìṣà to si n ṣe àṣà ilẹ̀ Yoruba.

Silekunola Naomi bẹ̀rẹ̀ isẹ ìránṣẹ́ lekunrere gẹ́gẹ́ bíi Woli lọdun 2011 to si bẹ̀rẹ̀ En-Herald Ministries nigba to wa ni ọmọ ọdun mejidinlogun.

En-Herald Ministries jẹ ìpéjọpọ to da gbogbo ìjọ pọ eyi to kalẹ si ilu Akure ni Ìpínlẹ̀ Ondo.

Ó jẹ oludari ẹ̀mí ó sì tún jẹ́ Ajihinrere tó máa ń ṣe isọji ti ero si maa n pọ.

Ọdun 2021 ni Naomi Silekunola kede pe, opin ti de ba igbeyawo oun ati Ooni.

Iru awọn eto apejẹ tabi faaji bayii ko jẹ tuntun ni Naijiria, paapaa lati ọdọ awọn ẹlẹyinju aanu to ma n ṣe e lati fi bọ awọn ti ko ri ounjẹ jẹ tabi fun eto ironilagbara ọrọ aje.