Mi ò l'érò láti ṣe òṣèlú, kádàrá ló sọ mí di alága káńsù ní UK - Yetunde Elebuibon
Ọkan lara awọn ọmọ gbajugbaja onimọ nipa aṣa ibilẹ ati ti Yoruba, Ifayemi Elebibon, Arabinrin Yetunde Elebuibon, ti ba BBC sọrọ lori bo sẹ rinrinajo rẹ to fi di aṣoju agbegbe Doncaster ni orilẹ-ede United Kingdom.
Arabinrin Yetunde Elebuibon to jẹ akọbi baba naa sọ pe lati kekere ni ipo adari ti ma n le oun kiri lai du ipo.
O ti n gbe ni ilẹ Gẹẹsi fun ọpọlọpọ ọdun, amọ lọdun 2022 lo gbe apoti ibo, to si wọle gẹgẹ bi aṣoju agbegbe Doncaster ninu iṣejọba.
"Mi o gbero lati di oloṣelu, o kan waye bẹẹ ni."
"Iṣẹ nọọsi lo kọkọ wu mi lati ṣe, amọ nigba to de asiko kan, oorun ileewosan ati abẹrẹ mu ki n yi eero mi pada."
Arabinrin Elebuibon ṣalaye pe erongba oun ati Araba ilu Osogbon ni pe ki oun pada si orilẹ-ede Naijiria lẹyin eto ẹkọ oun ni United Kingdom, "ṣugbọn bi kadara ṣe kọ pe ibi ti maa ma a gbe niyẹn".
Lori bi awọn ọmọ Naijiria ṣe n ya lọ si awọn orilẹ-ede ilẹ okeere, Arabinrin Yetunde Elebuibon sọ pe ipadanu nla ni fun orilẹ-ede ti awọn ọmọ rẹ n ṣi kuro.
"Idi ni pe ibi ti wọn ṣi lọ ni wọn o maa ṣe awọn nnkan meremere si fun idagbasoke rẹ, eyi ti ko ni ṣe e ṣe fun ilẹ baba wọn ti wọn ti jade."
O ni nnkan to yẹ ko jẹ awọn adari logun ni ipa rere ti wọn yoo fi lelẹ.

Ohun to yẹ ki o mọ nipa Yetunde Elebuibon
Gẹgẹ bi akọsilẹ nipa rẹ to wa lori ayelujara rẹ, ọdun mẹtadinlogun lo bẹrẹ si ni gbe ni Doncaster ni United Kingdom.
O n ṣiṣẹ labẹ ileeṣẹ eto ilera orilẹ-ede naa lati bi ọdun mẹtala sẹyin.
Ilu naa lo si n gbe pẹlu ẹbi rẹ.
Ṣaaju ko to di alaga kansu, lo ti n ṣe awọn akanṣe iṣẹ ati eto iranlọwọ fun araalu l'agbegbe rẹ, paapaa nipa imọ ẹrọ kọmputa ati ayelujara.













