'Ọ̀rẹ́ kọ̀ mí, mo di ẹni tó n dá á ṣe nígbà tí Ọlọ́run gbàdúrà mi gẹ́gẹ́ bí i Baba Kamo'

Àkọlé fídíò,
'Ọ̀rẹ́ kọ̀ mí, mo di ẹni tó n dá á ṣe nígbà tí Ọlọ́run gbàdúrà mi gẹ́gẹ́ bí i Baba Kamo'

Gbajumọ apanilẹẹrin ti ọpọ mọ si Baba Kamo, ti sọ pe ọpọlọpọ ọrẹ ni oun sọnu lẹyin ti okiki oun kan nidii iṣẹ naa.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan pẹlu BBC ni Ọgbẹni Yahya Habeeb Olatunji ti sọ pe ẹlomii ninu wọn ri oun ni iri pe oun ko ranti wọn 'nigba ti ọlhun ti da a lohun'.

"Amọ, ọrọ ko ri bẹẹ nitori pe ẹni ti awọn eeyan ro pe o ti de oke, naa ṣi n gbiyanju ni."

Ọgbẹni Olatunji sọ pe ibanujẹ ni iru nnkan yii jẹ fun oun nitori pe, o sọ oun di ẹni to n da ṣe ile-aye, lai ni alabaaro kankan.

O ni orukọ Baba Kamo ti oun n jẹ, wa lati ara awọn fnran awada ti oun n ṣe, kii ṣe pe oun bi ọmọ to n jẹ Kamo.

Baba Kamo

Oríṣun àwòrán, Baba Kamo / Dr whiteberry

Lori bo sẹ n ri owo si nidii iṣẹ apanilẹrin, Baba Kamo s pe iṣẹ naa lowo lori pupọ, ṣugbọn awọn inawo to wa nidii ṣiṣe awọn fnran jade, mu ko ma ni owo to to.

"Lootọ lo ni owo lori ṣugbọn wahala ibẹ pọ."

Fun Baba Kamo, nnkan to wu u lori julọ nidii iṣẹ apanilẹẹrin ni ọjọ ti gomina ipinlẹ Kwara fun ni ami ẹyẹ.