Àkọsílẹ̀ òfin mẹ́wàá tó pẹ́ jùlọ lórílẹ̀ ayé bọ́ sórí igbá fún títà

Àkọlé fídíò, Àkọsílẹ̀ òfin mẹ́wàá tó pẹ́ jùlọ lórílẹ̀ ayé bọ́ sórí igbá fún títà
Àkọsílẹ̀ òfin mẹ́wàá tó pẹ́ jùlọ lórílẹ̀ ayé bọ́ sórí igbá fún títà

Awọn onimọ iwadi nipa awọn nnkan iṣẹmbaye ti n gbero ati ta okuta akọsilẹ ofin mẹwaa ti awn onimọ gbagbọ pe oun ni akọsilẹ ofin mẹwaa to pẹ julọ lagbaye.

Awọn onimọ to ṣe ayẹwo okuta akọsilẹ naa sọ pe ede Paleo-Hebrew ni wọn fi kọ ọ ati pe ofin mẹwaa ti Mose kọ silẹ fun awọn ọmọ Israẹli lasiko irinajo wọn ninu aginju lo wa ninu okuta akọsilẹ naa gẹgẹbi Bibeli n Kristẹni atawọn Hebrew ṣe sọ.

Okuta akọsilẹ naa gbe iwọn kilogiraamu mejilelaadọta ti wọn si ni iwọn ibu ati oro ti awọn olukọni igbani fi ṣe apejuwe ofin mẹwaa ti Mose kọ silẹ ni okuta akọsilẹ yii ni.

Lara awọn ofin to ṣi han lara okuta naa ni "Iwọ ko gbọdọ paniyan", "Bọwọ fun baba ati iya rẹ" ati "iwọ kogbọdọ ṣe agbere".