Iná sọ ní ṣọ́ọ̀ṣì CAC Oke-Agbara n'Ibadan lásìkò ìsin orin 'Carol', ọ̀pọ̀ dúkìá jóná

Oríṣun àwòrán, Oyo State Fire Service
Lalẹ ọjọ Ẹti, ọjọ kẹtala, oṣu Kejila ọdun 2024 yii ni ina kan ṣẹyọ lojiji ninu ile ijọsin CAC kan n'Ibadan,lasiko ti awọn eeyan n ṣe ijọsin orin ọdun Keresimesi lọwọ.
Gẹgẹ bi awọn o ṣoju mi koro to wa nibẹ ṣe wi, wọn ni ina naa ka awọn olujọsin kan mọ inu ṣọọṣi ọhun.
Nnkan bii aago mẹsan-an aabọ alẹ ni a gbọ pe ina ọhun ṣẹyọ ni ṣọọṣi naa to wa ni Olohunda Road, nijọba ibilẹ Lagelu, niluu Ibadan.
Ẹnikan lara awọn to wa nibẹ, ṣalaye pe awọn olujọsin kan tilẹ ti sun ṣiwaju akoko isin iṣọ oru ti wọn tori rẹ lọ si ṣọọṣi lọjọ naa.
O ni wọn sun ki oorun le ti da lojuu wọn nigba ti iṣọ oru yoo ba fi bẹrẹ ni.
Ṣugbọn nigba ti ina ṣẹyọ lojiji to si ka wọn mọ, atijade ko dẹrun rara ni.
Bakan naa ni wọn sọ pe iya agbalagba kan wa lara awọn ti ina ka mọ.
A gbọ pe irin ẹsẹ nira fun mama naa tẹlẹ, nigba ti ina si ṣẹyọ lojiji, mama ko le jade.
Ileeṣẹ panapana ipinlẹ Oyo fidi iṣẹlẹ naa mulẹ.
Oludari ileeṣẹ naa, Akinyemi Akinyinka, to fidi ina ọhun mulẹ, lasiko ti a n ko iroyin yii jọ, sọ pe awọn ko ti i mọ ohun to fa idi ina ọhun.
O ni awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ panapana ti wa nibẹ, nigba tawọn ti gbọ nipa iṣẹlẹ naa lati ẹnu ẹnikan to n jẹ Kunle Junaid.
Akinyinka ṣeleri lati jẹ ki ohun to fa ina ọhun di mimọ pẹlu iwadii, iye eeyan to ṣee ṣe ko farapa tabi di oloogbe, ati iye ijamba ti ina ojiji naa fa gan-an.
A o le sọ pato ohun to ṣokunfa ijamba ina ṣọọṣi CAC n'Ibadan - Ileeṣẹ panapana Oyo
Ọga agba ileeṣẹ panapana ipinlẹ Oyo, Akinyinka Akinyemi, sọ fun BBC Yoruba ni nnkan bii ago mẹwaa ku iṣẹju mẹwaa lalẹ ọjọ Ẹti ọjọ kẹtala oṣu Kejila ni ileeṣẹ panapana ipinlẹ Oyo gba ipe lori ina to n jo ọhun.
O ni lẹsẹ kẹsẹ ni awọn oṣiṣẹ panpana si lọ si ṣọọṣi naa nibi ti ina ti n jo.
Ọgbẹni Akinyemi ni ''nigba ti a de ibẹ ni ri pe ile oniwaasu to wa lẹgbẹ ṣọọṣi ti mu ina tan.
Bayii ni a bẹrẹ si ni sa gbogbo agbara wa lati pa ina yii ki o maa ba ran mọ awọn ile mii to wa lẹgbẹ ṣọọṣi yii nibi ti isin orin Keresimesi ti n lọ lọwọ.''
Ọgbẹni Akinyemi ni ina ọhun ṣakoba fun ile oniwaasu ṣugbọn awọn oṣiṣẹ panapana gbiyanju lati pa ina to mu ṣọọṣi ati awọn ile mii to wa lẹgbẹ ṣọọṣi naa.
''Ko si ẹnikan kan to ku ninu iṣẹlẹ ọhun, amọ dukia ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu ṣofo.
Bo tilẹ jẹ pe ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu dukia ṣofo ninu ijamba ọhun, ileeṣẹ panapana ko jẹ ki dukia to to ẹgbẹlẹgbẹ biliọnu ba iṣẹlẹ naa.
A ko le sọ pato ohun to fa iṣẹlẹ ina yii tori iwadii si n lọ lọwọ, amọ ohun ti a gbọ ni pe ijamba ọhun ṣẹlẹ lasiko tawọn ọmọ kekere kan n fi ina ṣere nile oniwaasu nigba ti isin orin Keresimesi n lọ lọwọ ninu ṣọọṣi.
O ṣee ṣe ko jẹ wi pe nibi tawọn ọmọ kekere yii ti n fi ina ṣere ni ina ti ran mọ ile,'' Ọga agba ileeṣẹ panapana ipinlẹ Oyo lo sọ bẹẹ.















