A gbọ́dọ̀ fún àwọn ọ̀dọ́bìnrin láàǹní láti di olórí ìlú lọ́jọ́ ọ̀la – Oluremi Tinubu

Oluremi Tinubu

Oríṣun àwòrán, Oluremi Tinubu

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Aya Aarẹ Naijiria, Oluremi Tinubu ti rọ gbogbo awọn Oriade lati fun awọn ọdọ lobinrin ni ore ọfẹ ẹlẹkeji lati le mu ki wọn ṣe e mu yangan lawujọ.

Ninu ipade ti Oluremi Tinubu ba awọn Oriade ṣe nipinlẹ Osun lo ti rọ gbogbo awọn oriade naa ati gbogbo awọn olori ẹṣin lati pawọ pọ lati ri wi pe, awọn ọmọ obinrin mojuto ẹkọ wọn.

Ile ẹkọ Alternative High School for Girls ni iluu Osogbo ni ipade naa ti waye.

O ni "Wiwa mi si ipinlẹ Osun kii ṣe fun ti oselu rara.

Oluremi Tinubu

"Ṣugbọn mo wa fun dida awọn ọmọbinrin pada kuro ninu iṣẹ ti ko tọ ti wọn n se kaakiri; mo si tun wa fun idagbasoke ilu, ipinlẹ ati orile-ede Naijiria lapapọ."

Oluremi Tinubu tun tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ wi pe gbogbo awọn Oriade gbọdọ wa ni isọkan lati le ja fun ẹtọ ara ilu ti wọn jọba le lori ati lati le wa iṣọkan laarin awọn ara iluu ati laarin awọn Oriade to ku.

Iyawo Aarẹ tun fi kun pe oun ti ṣe ileri lati mu ki idagbasoke ba eto ẹkọ fun awọn ọmọ obinrin ni Naijiria, nitori oun n fẹ ki wọn jẹ adari ni nipinlẹ, ni orilẹede ati ni gbogbo agbaye.

Gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke fi idunnu rẹ han si aya Aarẹ fun erongba rẹ lati mu ki iyipada ba awọn ọdọ lobinrin.

Adeleke wa fi da Oluremi Tinubu loju wi pe iṣejoba oun yoo tun mu iyipada ba ipinlẹ ọsun siwaju si.

Gomina ọhun tun wa fi kun ọrọ rẹ pe, oun yoo rí daju wi pe, iyipada yoo de ba awọn ọdọ lobinrin nipa eto ẹkọ nì ipinlẹ Osun.

Ooni ti Ile Ife, Ọba Adeyeye Ogunwusi naa ki Oluremi Tinubu gidigidi fun gbogbo akitiyan rẹ lori awọn ọdọ lobinrin ati lori awọn Oriade gbogbo lati le mu ki ajọsepọ to dan mọran wa laarin wọn.

Ooni wa fi da Oluremi Tinubu loju wi pe, idagbasoke yoo wa laarin Oriade ara iluu lapapọ.