Kí ló ń fa gbas gbos láàárín Portable àti ìyàwó Aláàfin tẹ́lẹ̀, olorì Dami?

Oríṣun àwòrán, Potrable/officialqueen_dami/Instagram
Ní Ọjọ́bọ̀, ọjọ́ Kejìlá, oṣù Kejìlá, ọdún 2024 ni fídíò kan gba orí ayélujára níbi tí gbajúmọ̀ akọrin tàkasúfèé nì, Habeeb Okikiola tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Portable ti ń fẹ̀sùn kan ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀, Olorì Dami tó fìgbà kan jẹ́ ìyàwó aláàfin àná, Ọba Lamidi Adeyemi kẹta.
Nínú fídíò náà ni Portable ti ń sọ̀rọ̀ lórí bí òun àti Olorì ṣe pàdé àti àwọn nǹkan tó ṣe fun nígbà tí wọ́n wà papọ̀.
Ó fẹ̀sùn kan olorì Dami pé ó kọ kúrò nínú ilé tí òun gbà fun ní Ibadan, tó sì tún kó ọjà kúrò ní ṣọ́ọ̀bù tí òun gbà fun.
Ó ṣàlàyé pé òwò nọ̀bì ni òun fi pàdé olorì Dami táwọn sì pinnu láti tẹ̀síwájú nínú ìrìnàjò ìfẹ́ àwọn.
Ó ní ó fi oògùn mú òun tí òun sì ń ba tọ́jú ọmọ tó bí fún aláàfin àná, tó sì fẹ̀sùn kàn pé olorì Dami kò bímọ fún òun fún ọdún méjì tí àwọn fi wà papọ̀.
Portable ní gbogbo ọjà tí òun rà sínú ṣọ́ọ̀bù náà ni Dami kó kúrò nínú ṣọ́ọ̀bù náà àti pé òun ti ń wá bí òun ṣe máa le kúrò nínú ilé òun kó tó di pé ó kó ẹ̀rù kúrò nílé.
Bákan náà ló sọ pé ẹ̀ẹmẹrin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni oyún ti jábọ́ lára Dami lẹ́nu ìgbà tí àwọn fi wà papọ̀.
'Gbogbo ìgbà ni Portable máa ń nà mí'
Nígbà tó ń fèsì, Dami nínú fídíò kan tó ṣe lórí ayélujára ní torí pé ọdọọdún ni àwọn obìnrin máa ń lóyún fún Portable ni òun ṣe kọ̀ láti lóyún fún-un.
Ó ní òun kò fẹ́ darapọ̀ mọ́ ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin tó ń bímọ fún Portable ni òun ṣe kọ́ láti lóyún fún-un fún ọdún méjì tí àwọn fi wà papọ̀ àti pé irọ́ ni pé oyún jábọ́ lára òun ní ìgbà mẹ́rin gẹ́gẹ́ bí Portable ṣe sọ nínú fídíò rẹ̀.
Dami, nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa bí òun àti Portable ṣe pàdé, ní Portable ló kọ́kọ́ bá òun sọ̀rọ̀ lórí ayélujára táwọn fi bẹ̀rẹ̀ eré ìfẹ́ àwọn.
Ó ṣàlàyé pé nítorí Portable dúnkokò mọ́ òun láti lo òun ni òun ṣe sá àsálà fún ẹ̀mí ara òun torí òun kò fẹ́ kí àwọn òbí òun fojú sunkún òun lásìkò yìí.
Ó sọ pé Portable kìí fi àyè gba òun láti lo ẹ̀rọ ayélujára kódà láti fi polówó ọjà òun ní gbogbo ìgbà tí òun fi wà pẹ̀lú rẹ̀ nítorí òun jẹ́ ìyàwó ilé.
"Ò ń pè mí ní ìyàwọ ilé, ṣé o ti fi òrùka sí mi lọ́wọ́ ni, ṣé o ti mọ àwọn ẹbí mi, ṣè bí o kàn fẹ́ mi pa mọ́ ni?"
Dami fẹ̀sùn kàn pé ọ̀pọ̀ àpá ló wà lára òun nítorí gbogbo ìgbà ni Portable máa ń na òun, tí òun kò sì lè tẹ̀síwájú pẹ̀lú ìgbé ayé bẹ́ẹ̀.
"Portable nà mí ọjọ́ kan títí tí mo fi dákú, ó yẹ kí n ti fi Portable sílẹ̀ tipẹ́, irọ́ ni a pa fún ìyá mi pé ọ̀tọ̀ ni nǹkan tó ṣe mi tí mo fi dákú."
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa aláàfin àná, ọba Lamidi Adeyemi tí Portable fẹ̀sùn kàn pé Dami lọ́wọ́ nínú ikú rẹ̀, Dami ní òun kò mọ nǹkankan nípa ikú aláàfin àti pé lẹ́yìn ọdún kan tí òun ti kúrò ní ààfin ni òun gbọ́ pé ó rẹ aláàfin.
Kí lo fa wàhálà láàárín Portable àti Dami?
Ní alẹ́ ọjọ́rú ni ìfaǹfà bẹ́ sílẹ̀ láàárín Portable àti Dami nígbà tí Portable darapọ̀ mọ́ fídíò kan tí Dami ń ṣe pẹ̀lú àwọn èèyàn kan.
Níbi fídíò náà Portable ti bẹ̀rẹ̀ sí ní bèèrè lọ́wọ́ Dami pé kí ló ń ṣe lórí ayélujára lálẹ́ àti pé ṣé kò mọ̀ pé ìyàwó ilé ni òun jẹ́?
Ó ní kò yẹ kí Dami máa wà lórí ayélujára ní àsìkò tó wà náà nítorí ìṣekúṣe ni wọ́n ń ṣe lásìkò náà.
Lẹ́yìn náà ló pa fídíò tó ń ṣe náà tó sì lọ kọ ọ́ sórí ayélujára rẹ̀ pé òun kò ní lè tẹ̀síwájú eré ìfẹ́ òun àti Portable mọ́ nítorí òun kò lè farada àwọn ẹ̀gbin tó fi ń rẹ́ òun lára mọ́.
Ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyí tí ìfaǹfà báyìí ń wáyé láàárín Portable àti àtàwọn ìyàwó àtàwọn obìnrin tí wọ́n bímọ fún-un.
Ní oṣù Kọkànlá ọdún yìí ni Portable fẹ̀sùn kan Dami pé ó ń le àwọn obìnrin kúrò ní ilé ọtí òun àti pé kò mọ rírì ipa tí òun ń kó lórí ọmọ rẹ̀ tó bí fún aláàfin tí òun ń ba tọ́jú.















