Bobrisky, Betta Edu, àtàwọn ohun míì táwọn èèyàn wá jù lórí ayélujára ní 2024

Oríṣun àwòrán, Others
Ẹka ayelujara ti a mọ si Google, nibi ti awọn eeyan ti maa n wadii ohun ti wọn ba fẹẹ mọ, ti fi atẹ ohun tawọn eeyan beere nipa ẹ ju ni Naijiria ni 2024 sita.
Atẹjade Google sọ pe Bobrisky, ọkunrin to maa n ṣe bii obinrin, Better Edu ti i ṣe minisita ọrọ ọmọniyan ki wọn too yọ ọ nipo nitori ẹsun ajẹbanu ati opo ina agbara, national grid, wa lara ohun tawọn eeyan beere lọwọ Google ju lorilẹede yii ni 2024.
Bakan naa ni wọn darukọ olorin taka-sufee; Shallipopi, gẹgẹ bi ọkan lara awọn ti wọn beere ju lọwọọ Google nipa rẹ .
Foonu olowo nla, Iphone 16 naa wa lara nnkan tawọn eeyan gugu rẹ ju ni 2024.
Atẹjade Google sọ pe ọrọ oṣelu jẹ awọn eeyan Iwọ-Oorun Afrika logun pupọ, wọn beere nipa rẹ gan-an.
Wọn tun gugu nipa ọrọ aje ati idibo ilẹ America to waye kọja.
Orin orilẹede Naijiria to yipada (National anthem) naa wa lara nnkan tawọn eeyan gugu ju.
Wo bí Google ṣe tò ó
Ìròyìn
Ibo America, orin orilẹ ede Naijiria tuntun, owo oṣu to kere ju, opo ina agbara, ibugbamu Ibadan, idibo ipinlẹ Edo, iwọde ni Naijiria, idaṣẹsilẹ awọn oṣiṣẹ, ooru to mu ni Naijiria ati owo tijọba fẹẹ maa ya awọn akẹkọọ fun iranwọ.
Awọn ọmọ Naijiria ti wọn gugu nipa wọn
Bobrisky, Betta Edu, Shallipopi, Khaid, Bukunmi Oluwashina, Sharon Ooja, Adanma Luke, Yahaya Bello, Mike Ejeagha, Farooq Oreagba.
Awọn eeyan kaakiri agbaye
Donald Trump, Kai Cenat, Kamala Harris, Tyla, Diddy, Joe Biden, Skepta, Paul Biya Tyra Banks, ati Vybz Kartel.
Awọn ti ere idaraya
Nico Williams, Stanley Nwabali, Leny Yoro, Cole Palmer, Ruben Amorim, Manuel Ugarte, Pedro Neto, Rodri, Joshua Zirkzee, ati Dani Olmo.
Awọn ti wọn di oloogbe tawọn eeyan gugu wọn ju
Junior Pope, Mr Ibu, Herbert Wigwe, Sisi Quadri, Ifeanyi Ubah, Aduke Gold, Onyeka Onwenu, Amaechi Muonagor, Liam Payne, ati Rukayat Gawat.
Àṣà
Demure, Steeze, Pet peeves, Moots, Naira Mutilation, Taraban Refect, Pookie, Ozeba, Abido shaker.
Orin
Ogechi, Ozeba, Omemma, Marhaba, xxxtentacion Hope,
Commas, Twe Twe, Abanikanda.
Piece of my heart, Egwu, Double, Twe Twe remix ft Davido, Tshwala bam .
Erè
A Tribe Called Judah, Treasure In The Sky, Damsel,
Rebel Ridge, Dune, Venom, Breath Of Life, Avatar, The Last Airbender, Lisabi, The Idea Of You.
Foonu
Iphone 16, Infinix Note 40, Redmi 13C, Redmi 14C, Infinix Hot 40
Infinix Hot 50 Pro Plus Redmi A3, Tecno Pop 9, Tecno Spark 20, Infinix Smart 8
Eré oníṣe
Supacell, My Demon, Queen Of Tears, Queen Woo, Shogun, Yellowstone, House Of The Dragon, Deadpool, The Boys, Marry My Husband.
Ìbéèrè
Elo ni dola kan si naira lonii?
Bi o ṣe le jẹ ki irun rẹ da bii ti oyinbo.
Ta a lo bori ninu ibo ilẹ America?
Bi o ṣe le pokiki ẹgbẹ elere idaraya ti o fẹran .
Ki lo de ti fifi bulọọku wẹ ṣe dara fun amupada iṣan?
Ta a lo gba ami ẹyẹ ballon d'or ni 2024?
Iṣẹju winni-winni (seconds) meloo lo wa ninu ọjọ kan?
Ta a lo gba ami ẹyẹ Grammy ni 2024?
Ki ni itumọ steeze?
Elo ni Iphone 16?
Taiwo Kola-Ogunlade to n ri si ikede fun Google ni gbogbo Iwọ-Oorun Africa, sọ pe ohun to kan awọn eeyan ni 2024 ni wọn beere nipa ẹ ju.















