Kí ló fà á tí ọ̀wọ́ngógó Naira tún ń yọjú lórílẹ̀èdè Nàìjíríà lásìkò yí?

Aworan owo Naira

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn olugbe Naijiria tun ti kọminu bayii lori bi owo naira ṣe sa fẹrẹ nigboro ti awọn eeyan kii si i ri i gba lori ẹrọ apọwo ATM lawọn banki kaakiri, ayafi ti wọn ba lọ si ọdọ awọn oniṣowo POS.

Lati ile ifowopamọ de ọdọ awọn oni POS ni ko ti si owo naira, ti ọpọ awọn oni onisowo POS to ba ri owo diẹ gba gan n gbe owo lori wọn fun awọn araalu.

Ọpọ awọn oni POS ni wọn ti kogba wọle nitori airi owo gba ni ile ifowopamọ.

Ni apa ibi kan niluu Abuja, awọn oni POS n gba owo to to irinwo Naira, (N400) lori ẹni to ba wa gba ẹgbẹrun mẹwaa (Naira N10,000).

Esther Nwanna to jẹ oniṣowo POS niluu Abuja sọ fun BBC pe oun ni lati lọ banki marun un ki oun to le ri ẹgbẹrun lọna ọgọrun un Naira gbe sita (N100,000) gba sita .

"Ni owurọ yii, mo ni lati lọ banki marun un, ti ki i se pe wọn sumọ ara wọn ki n to ri ẹgbẹrun lọna ọgọrun Naira gba sita ."

Abubakar Jibril, ti oun naa n ṣe iṣẹ POS naa ni oun ni lati lọ ile ifowopamọ mẹrin ki oun to le ri owo gba.

Ki lo ṣẹlẹ?

Oṣiṣẹ Banki kan ba BBC sọrọ ni idi ti eyi fi n waye ni pe wọn fẹ ko owo atijọ kuro ni ilẹ patapata.

"Ti ẹ ba ranti, lasiko ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari, atunṣe ba owo naira, t banki apapọ si gbe gbedeke kalẹ fun owo naira atijọ ṣugbọn nitori ẹbẹ awọn gomina kan, wọn sun eyi siwaju.

Ni ọdun 2022, Muhammadu Buhari paṣẹ pe ki Banki apapọ Naijiria ṣe atuntẹ owo Naira ẹlẹgbẹrun kan, ẹlẹdẹgbẹta ati igba Naira odindi jade.

Ẹwẹ, awọn gomina kan yari pe awọn ko le fọwọsi igbesẹ naa, ti wọn si morile ile ẹjọ giga lorilẹede Naijiria lati tako igbesẹ ọhun, ti wọn si jare ni ile ẹjọ.

Ile ẹjọ ni ki awọn araalu ṣi maa na owo Naira atijọ nigba naa lọ.

Oṣiṣẹ banki n tẹsiwaju pe ko ṣeeṣe ki awọpn araalu ba na owo naira meji ọtọọtọ.

O ni awọn alaṣẹ n gbe igbesẹ yii pẹlu erongba lati fi ibẹru sọkan awọn araalu.

"Gbogbo igbiyanju yii ni lati fopin si owo naira atijọ ṣugbọn pẹlu ọgbọn, wọn ko fẹ fi ibẹru sọkan awọn araalu."

"Ohun ti wọn n se ni pe ti owo naira atijọ ba ti wọle sinu opo ijọba bayii, ko tun jade mọ."

Ki lo de ti awọn oni POS ko fi ri owo gba?

Oṣiṣẹ banki naa ni pẹlu ilana ofin, owo gbigba ni gbedeke fun gbogbo eeyan nipa iye owo ti wọn fẹ gba sita .

"Nitori wọn fẹ din owo ku , iye owo ti wọn fun awọn oni POS ni o ṣeeṣe ki wọn ti dinku.

"Awọn banki gan ko ni owo ni pamọ lọwọ yii lati fun awọn onibara wọn."

O wa rọ awọn eeyan lati bẹrẹ sini ma lo ayelujara lati san owo nitori ọlaju ti gbode, ti orilẹede Naijiria si ni lati kọwọrin pẹlu ọlaju.