Àwọn ìpínlẹ̀ kan kò ní lè san ₦70,000 owó oṣù òṣìṣẹ́ tí ìjọba bá buwọ́lu owó orí tuntun – Gómìnà Zamfara

Oríṣun àwòrán, David Lawal/Instagram
Gomina ipinlẹ Zamfara, Dauda Lawal ti ni yoo nira fun ọpọ ipinlẹ lati san owo oṣu tuntun to jẹ 70,000 fun awọn oṣiṣẹ ti ijọba ati ile igbimọ aṣofin ba buwọlu owo ori sisan tuntun.
Lawal ni ijọba ni lati ro igbesẹ yii daada lati ma le fa akoba fun araalu.
"Awọn anfani wa ninu ofin yii bẹẹ ni o ni buburu tiẹ. Idi ree ti a fi gbọdọ se iwadii daada lori ofin naa.
"Ọpọ awọn ipinlẹ ni wọn ko ni ni anfani lati san owo oṣu tuntun ti aba afikun owo ori ba di ofin."
Bẹẹ ba gbagbẹ, ileeṣẹ aarẹ fi abadofin kan si ile igbimọ aṣofin lori afikun owo oṣu ori.
Iroyin ni awọn aṣofin kan ti wọn kọkọ sọ pe awọn ko faramọ abadofin naa ṣaaju asiko ti yi ohun wọn pada bayii lẹyin ti igbimọ Aarẹ to wa nidi ofin ọhun ṣalaye awọn ohun kan to ṣokunkun ninu rẹ.
Wayi o, ijọba ti ni ofin tuntun naa ko wa fun lati gba owo lọwọ awọn ọmọ Naijiriati ko rọwọ họri.
Nigba ti awọn igbimọ to wa nidi ofin owo ori naa yọsi siwaju awọn aṣofin, wọn ni awọn olowo ilu ni ofin owo ori tuntun naa kan, ko kan awọn alaini.
Koda wọn ni ko si ohun to kan awọn ti owo ti wọn n pa wọle lọdun ko ba to miliọnu kan naira
Taiwo Oyedele, to jẹ alaga igbimọ to n ṣakoso owo ori tuntun naa ti sọ pe ko kan awọn alaini.
Nigba to n sọrọ niwaju awọn aṣofin, o ni awọn ọlọla nikan ni ọrọ naa kan, ati pe ofin ọhun tun waye lasiko yii lati ṣe atunṣe si kudiẹ-kudiẹ to wa ninu bi ijọba ṣe n pin owo ori ti araalu n san.
Oyedele sọ pe "Abadofin mẹrin to ṣe koko ni igbimọ yii gbe wa eyii ti afojusun rẹ jẹ lati ṣe atunṣe si eto owo ori wa.
"Ofin naa fẹ ko gbogbo ofin owo ori si abẹ ofin kan ṣoṣo, ki a mu irọrun ba bi araalu yoo ṣe maa san owo ori ki a si yọ awọn to n pa owo kereje kuro.
"Obadofin naa yoo ṣamulo bi a o ṣe maa fi imọ ẹrọ gba owo ori ati bi gbigba rẹ yoo ṣe rọrun."












