Ẹnu pé mo fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ gba oyè PhD ni mo pàdánù ojú, ta ọpọ̀lọpọ̀ dúkìá mi sí – Ajagunfẹ̀yìntì tó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ọ̀mọ̀wé lọ́dún 85
Ẹnu pé mo fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ gba oyè PhD ni mo pàdánù ojú, ta ọpọ̀lọpọ̀ dúkìá mi sí – Ajagunfẹ̀yìntì tó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ọ̀mọ̀wé lọ́dún 85
Iṣẹ ologun ni Ọmọwe Ẹniọwọ Ọnafọwọkan Bọlaji Titilọla morile ileeṣẹ ologun ironu rẹ ni pe oun yoo di ọgagun lọjọkan.
Amọṣa nigba ti yoo fi di asiko ti o n reti igbega lẹnu iṣẹ ologun ni wọn gbe iwe idaduro lẹnu iṣẹ le e lọwọ.
Eyi domi tutu si i lọkan amọṣa o gbọran nu o si mu ilana irinajo miran pọn. Eleyi lo sọ ọ di ẹni to n gba imọ ijinlẹ Ọmọwe ninu imọ ẹkọ.
Ẹni ọdun marundinlaadọrun ni nigba to gboye ọmọwe yii.
"Mo padanu oju mi lori pe mo n kẹkọọ lati gboye ọmọwe yii" ṣugbọn o ni eyi ko da oun lọwọ kọ nitori pe oun ni afojusun ibi ti oun nlọ.