‘Àìrí àkójọ nídìí iṣẹ́ ìmọ̀ kọ̀mpútà ló sọ wá di Taye-Kehinde alámàlà’

Àkọlé fídíò, 'Ìfẹ́ oúnjẹ sísè ló mu wa pa iṣẹ́ ìmọ̀ kọ̀mpútà tì táa fi di Taye-Kehinde alámàlà'
‘Àìrí àkójọ nídìí iṣẹ́ ìmọ̀ kọ̀mpútà ló sọ wá di Taye-Kehinde alámàlà’

Oúnjẹ ni Yorùbá pè ní ọ̀rẹ́ àwọ̀, tí ebi bá sì ti kúrò nínú ìṣẹ́, ìṣẹ́ bùṣe.

Ní ilẹ̀ Áfíríkà, ọ̀pọ̀ ló gbàgbọ́ pé ọmọbìnrin ló yẹ kí wọ́n máa bá ní ilé ìdáná nítorí wọ́n gbàgbọ́ pé iṣẹ́ obìnrin ni oúnjẹ sísè.

Àmọ́ bí ayé ṣe ǹ lọ ni à ń tọ̀ ọ́, àwọn ọkùnrin, lóde òní, ni àwọn náà ti ń da bẹbẹ láṣà nípa síse oúnjẹ tó dùn, tó sì máa gba àwo bọ̀.

Èyí ló gbé wa dé ọ̀dọ̀ àwọn ìbejì ọkùnrin yìí, Taiwo àti Kehinde Ibiejugba tí wọ́n gbajúmọ̀ fún orúkọ ilé oúnjẹ wọn KUIK NOSH tó wà ní ìlú Abuja.

Àwọn ìbejì yìí ní ilé tó jẹ́ pé ọkùnrin ló pọ̀ níbẹ̀ ni àwọn ti dàgbà, tó sì jẹ́ pé láti kékeré ni àwọn ti ń wọ ilé ìdáná.

Taiwo ati Kehinde Ibiejugba

Oríṣun àwòrán, KUIK NOSH/instagram

Wọ́n ṣàlàyé pé láti kékeré ni àwọn ti mọ̀ nípa àwọn èròjà tí wọ́n máa ń fi sí oúnjẹ láti jẹ́ kí oúnjẹ dùn nítorí ọgbà tí wọ́n fi ń gbin nǹkan wà nínú ilé tí àwọn ti dàgbà.

Wọ́n ṣàlàyé pé gẹ́gẹ́ bí akẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú ìmọ̀ ẹ̀rọ Kọ̀mpútà láti ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì ìlú Ilorin, àwọn gbìyànjú láti fi ìwé ẹ̀rí àwọn ṣiṣẹ́ àmọ́ àwọn kò rí àkójọ lórí iṣẹ́ náà.

Èyí ló mú wọn pinnu láti dá ilé oúnjẹ ti wọn sílẹ̀ ní ìlú Abuja nítorí wọ́n ní ìfẹ́ sí iná dídá.

Bákan náà ni wọ́n sọ pé láti fikún ìmọ̀ tí àwọn ti ní lórí oúnjẹ sísè, àwọn lọ sí ilé ẹ̀kọ́ tí wọ́n ti ń kọ́ èèyàn ní oúnjẹ sísè kí oúnjẹ àwọn le dá yàtọ̀.

Oúnjẹ ilẹ̀ òkèrè ni wọn kọ́kọ́ fi bẹ̀rẹ̀ òwò, "nítorí àwọn rò ó wí pé òun ló máa yá ní títà ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn bẹ̀rẹ̀ sí ni fi oúnjẹ ìbílẹ̀ wa si ní ìyàtọ̀ tó pọ̀ dé bá ọjà títà àwọn".

“Inú wa dùn sí nǹkan tí à ń ṣe nítorí nǹkan tó fún ayé wa ní ìtumọ̀ ni.”