A kò ní èróngbà láti f'òfin de omi inú ọ̀rá - Ìjọba Ìpínlẹ̀ Eko

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijọba ipinlẹ Eko ti kede sita pe awọn ko ni erongba lati fofin de omi inu ọra ti ọpọ mọ si Pure Water nipinlẹ naa.
Kọminsan fun ayika nipinlẹ Eko, Tokunbo Wahab lo kede eyi loju opo ikanni ayelujara X lọjọ Aiku nigba to n sọrọ lori fọnran kan to ṣafihan bi awọn eeyan kan ṣe n fọ omi inu ọra naa.
Wahab ni awọn eeyan naa ni wọn ki se oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Eko tabi ti ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Eko to n risi ayika.
Gẹgẹ bii Kọmisana se ṣalaye, o ni iwadii fihan pe awọn eeyan naa lo jẹ oṣiṣe ajọ NAFDAC, ti wọn n gbe ogun ti awọn ileeṣẹ omi inu ọra ti wọn ko tẹlẹ ofin ati ilana ajọ naa.
“O se koko ki gbogbo araalu mọ pe a ko fofin de omi inu ọra , ti a ko si ni erongba lati se bẹ. “
Ni oṣu kinni ọdun yii ni Ijọba ipinlẹ Eko fi ofin de lilo ati pinpin igo onike ati abọ fukẹfukẹ ni ipinlẹ naa.
Kọmiṣọna ọrọ ayika ati awọn alumọni inu omi, Tokunbo Wahab naa lo fọrọ yii lede lọjọ Aiku loju opo X rẹ.
Fukẹfukẹ yii ni wọn maa n lo gẹgẹ bi abọ tawọn ti wọn fi n ta ounjẹ kaakiri ibi ti wọn ti n ta ounjẹ.
Wahab ni ijọba gbe igbesẹ yii latari ewu ti igo onike ati abọ fukẹfukẹ ti ko le jẹra n fa fun ayika nipinlẹ Eko.
Kọmiṣọna ni gbogbo koto idaminu ni igo onike ati abọ fukẹfukẹ n di bi tilẹ jẹ pe ajọ LAWMA n ko awọn koto idaminu naa ni gbogbo igba.
Ọgbẹni Wahab ni awọn abọ fukẹfukẹ lo pọju ninu awọn idọti ti awọn oṣiṣẹ ajọ LAWMA maa n gba lawọn ọja ati opopona lojoojumọ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post















