Èròjà olówó pọ́ọ̀kú márùn-ún tí ó le fi dípò tòmátò nínú ọbẹ̀

Aworan Tomato ninu ọja

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Pẹlu bi ọpọ eeyan se n pariwo pe Tomato wọn lode lasiko yii, BBC se akojọpọ awọn elo mii ti ẹ le fi dipo tomato ninu ọbẹ.

Yoo ya yin lẹnu pe ọpọ awọn nnkan yii lo wa ni ayika wa, ṣugbọn ti a ko fi oju si pe o le rọpo tomato gẹgẹ bi eroja isebẹ, paapaa lasiko ọwọn gogo ounjẹ yii.

Yatọ si pe awọn eroja yii le dipo tomato, wọn tun n ṣe ara loore pupọ.

Obẹ igba

Aworan ọbẹ ẹyin

Oríṣun àwòrán, Others

Igba, ti awọn eeyan kan tun mọ si ikàn, jẹ ounjẹ ti ọpọ mọ nipa sugbọn ti wọn ko mọ pe o le se iṣẹ ti tomato n ṣe ninu ọbẹ.

O le fi igba dipo tomato ninu ọbẹ pẹlu awọn elo ọbẹ mii bi i epo pupa, ẹja, ata, iru, ede ati iyọ lati mu dun.

Ọbẹ yii ni eeyan le fi jẹ irẹsi, iṣu ati ọgẹdẹ.

Lati fi igba se ọbẹ:

  • Ṣan igba ti o fẹ ẹ lo daadaa pẹlu omi
  • Se e fun iṣẹju diẹ ko le rọ
  • Lẹyin naa ni ki o fi ṣibi tabi orogun kekere tẹ ẹ ninu ike
  • Din ata diẹ pẹlu epo ati awọn eroja yooku
  • Da igba rẹ si
  • Ọbẹ ti delẹ niyẹn

Ọbẹ Cucumber

Aworan Ọbẹ Cucumber

Oríṣun àwòrán, Others

Bẹẹni, ẹ ma jẹ ko ya yin lẹnu pe o le fi cucumber dipo tomato ninu ọbẹ. Ti ẹ ba lọ Cucumber pẹlu ata ati alubọsa, ọbẹ de.

Ẹ ni lati ri pe ẹ yọ gbogbo awọn koro to wa ninu cucumber naa ko to o di pe ẹ lọ papọ mọ ata ati alubọsa.

Ọbẹ Carrot

Aworan Ọbẹ Carrot

Oríṣun àwòrán, Others

O tun ya yin lẹnu abi?

Carrot naa le dipo tomato ninu ọbẹ. Iwadii ti ẹ sọ pe ọbẹ carrot yii maa n mu ara dan, to si kun fun ọpọlọpọ eroja bii caroten, to le ṣe ara loore.

Adun carrot tun maa n han ninu ọbẹ, to si maa n mu ọbẹ dun pupọ.

Ẹ le fi ọbẹ carrot jẹ irẹsi, iṣu, ati bẹẹbẹẹ lọ.

Ọbẹ Banga

Aworan Ọbẹ Banga

Oríṣun àwòrán, Others

Wọn tun ma n pe ọbẹ yii ni ọbẹ Ofe Akwu ni ede Igbo.

Ọbẹ banga lo jẹ ọbẹ ti wọn n fi ẹyin ori ọpẹ se, ilẹ Igbo si ni wọn ti fẹran ọbẹ yii ju.

O le da bi pe o le gba akoko lati ṣe sugbọn o dun lati jẹ pupọ paapa ti ẹ ba pelo rẹ pẹlu awọn ẹfọ ẹlẹmi meje, ẹran, ẹja ati awọn elo mii.

Ọbẹ Baobab

Aworan ọbẹ Baobab

Oríṣun àwòrán, Others

Ọbẹ yii jẹ ohun ti wọn ni fẹ si lati jẹ pupọ ni apa ariwa orilẹeede Naijria.

Ewa Baobab ati kuka ti wọn gun to kuna ni wọn ma n fi se ọbẹ yii.

Irẹsi funfun ni wọn fi n jẹ ọbẹ yii ni ọpọ igba.