Èyí làwọn ohun tó lè fa kí oyún wálẹ̀ lára obìnrin àtàwọn ọ̀nà láti dènà rẹ̀

Aláboyún

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Kí oyún máa wálẹ̀ lára obìnrin túmọ̀ sí kí oyún bàjẹ́ lára obìnrin nígbà tí kò ì tíì tó bí pàápàá tí kò bá ì tíì pé ọ̀sẹ̀ méjìdínlọ́gbọ̀n.

Dókítà nípa ìlera àwọn obìnrin, dókítà Osas Edokpolor sọ fún BBC pé ní àwọn orílẹ̀ èdè mìíràn, oyún tí kò bá ti kọjá ọ̀sẹ̀ ogún ni wọ́n máa ń gbà pé ó walẹ̀ ni.

Àmọ́ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, oyún tí kò bá ti kọjá ọ̀sẹ̀ méjìdínlọ́gbọ̀n ni ìgbàgbọ́ wà pé ó wálẹ̀.

Kí ni àwọn nǹkan tó le fa kóyún wálẹ̀?

Dókítà Edokpolor ṣàlàyé pé ohun kan gbòógì tó máa ń fa kí oyún wálẹ̀ ni tí oyún tó wà nínú aláboyún kò bá máa dàgbà bó ṣe yẹ.

Ó ṣàlàyé pé ìdá mẹ́wàá sí ogún oyún táwọn obìnrin máa ń ní ló máa ń wálẹ̀, tó sì jẹ́ pé obìnrin kan sí méjì nínú obìnrin mẹ́wàá ni oyún ti wálẹ̀ lára rẹ̀ rí.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ oyún tó ń wálẹ̀ gẹ́gẹ́ bí dókítà Edokpolor ṣe ṣàlàyé ló jẹ́ pé ó níṣe pẹ̀lú àìdúró dédé kúrómósóòmù, èyí tó túmọ̀ sí pé oyún náà kò dúró dáadáa.

“Àwọn oyún tí kò bá dúró dáadáa máa ń wálẹ̀. Ìdá ogún àwọn obìnrin tí kò bá ì tíì pé ogún ọdún àtàwọn tí ọjọ́ orí wọn bá ti lé ní ogójì ọdún ni oyún máa ń wálẹ̀ lára wọn.

“Èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé ó ṣeéṣe kí ẹyin àti ilé ẹyin wọn ní kùdìẹ̀kudiẹ kan tàbí òmíràn tó sì máa ń fa kóyún wálẹ̀.”

Ìtọ̀ ṣúgà: Dókítà Edokpolor ní àìsàn ìtọ̀ ṣúgà le mú kí oyún wálẹ̀ lára obìnrin àti pé ọ̀pọ̀ obìnrin ni kìí ms pé àwọn ní ààisàn yìí títí tí wan fi ma lóyún.

Kí ilé ọmọ má lè gba oyún dúró: Eléyìí ni dókítà Edokpolor pè ní kí ẹnu ọ̀nà orù ilé ọmọ má kajú òṣùwọ̀n. Ó ní tí obìnrin bá ní ìṣòro yìí, oyún bá ṣe ń dúró sára rẹ̀ náà ni yóò máa wálẹ̀.

Àìsàn ibà: onímọ̀ ìṣègùn náà tún sọ pé àìsàn ibà tí wọn kò bá tètè tọ́jú fún aboyún le mú kí oyún inú rẹ̀ wálẹ̀.

Ṣíṣe àwọn ìwà kò tọ́: Ó fi kun pé àwọn obìnrin tó bá máa ń mu ọtí, mú sìgá tàbí egbògi olóró nínú oyún le mú kí oyún wọn wálẹ̀.

Yàtọ̀ sí èyí, ó ṣàlàyé pé lílo àwọn ògùn kan nínú oyún le fa kí oyún wálẹ̀, tó sì ṣèkìls fáwọn aboyún láti dènà lílo oògùn tí kìí bá ṣe wí pé dókítà ló kọ ọ́ fún wọn.

Ṣé lóòótọ́ ni ṣíṣe wàhálà le ba oyún jẹ́?

Onímọ̀ ìṣègùn náà tún tẹ̀síwájú láti ṣàlàyé pé ọ̀pọ̀ nǹkan tí àwọn èèyàn gbàgbọ́ pé ó máa ń ba oyún jẹ́ ni kò rí bẹ́ẹ̀.

Ó ní lára rẹ̀ ni ìgbàgbọ́ pé ṣíṣe wàhálà máa ń ba oyún jẹ́. Dókítà náà ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wàhálà kìí ṣe ohun tó da fún àgọ́ ara yálà olóyún tàbí ẹni tí kò lóyún, ó ní sáyẹ́ǹsì kò fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ṣíṣe wàhálà máa ń ba oyún jẹ́.

Bákan náà ló ni bíbẹ̀rẹ̀ kò ní nǹkan ṣe pẹ̀lú kí oyún bàjẹ́ nítorí kò sí ìwádìí tó fìdí rẹ̀ múlẹ̀.

Ó ṣàlàyé pé oúnjẹ náà kò ní kí oyún bàjẹ́ lára.

Ọ̀nà wo la lè fi dènà oyún bíbàjẹ́?

Alaboyun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Dókítà Edokpolor ní kò sí àtúnṣe tàbí ohun tí èèyàn le fi dènà oyún tí kò bá dúró dáadáa nítorí àgọ́ ara ló ṣokùnfà rẹ̀.

Ó ní fún àwọn àìleara mííràn bíi ìtọ̀ ṣúgà àti ibà, àwọn dókítà nílò láti tọ́jú àìlera náà kí wọ́n tó gba irú obìnrin bẹ́ẹ̀ nímọ̀ràn láti lọ lóyún.

Ó ní fún àwọn tí ilé ọmọ wọn máa ń ṣí sílẹ̀, wọ́n máa so okùn mọ́ ẹnu ọrùn ilé ọmọ wọn tí wọ́n títí di àsìkò tí yóò bímọ fi máa tó.

“Ohun pàtàkì ni pé kí wọ́n kọ́kọ́ ṣe ìwádìí ohun tó fa ìdí tí oyún náà fi ń wálẹ̀ láti mọ ìtọ́jú tí wọ́n máa fun àtàwọn ìmọ̀ràn tí wọ́n máa gba obìnrin bẹ́ẹ̀.”

Aláboyún jí ara rẹ̀ gbé ní ìpínlẹ̀ Ogun, ọ̀rọ̀ gba ibòmíràn yọ

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun ti ní obìnrin olóyún kan, Raheemat Lateef tí wọ́n sọ wí pé àwọn ajínigbé jí gbé lásìkò tó ń lọ sí ilé ìwòsàn ní agbègbè Ijaiye, Abeokuta lọ bímọ kìí ṣe pé wọ́n ji gbé ní tòótọ́.

Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Ogun, Omolola Odutola nígbà tó ń fi ìròyìn náà léde lórí ìkànnì X rẹ̀ lọ́jọ́ Ajé ní, àwọn ti ṣàwárí obìnrin náà.

Odutola ṣàlàyé pé Raheemat mọ̀ọ́mọ̀ sọ pé wọ́n jí òun gbé lẹ́yìn tó pàdánù oyún tó ní kí wàhálà má ba à ṣẹlẹ̀ láàárín òun àti ọkọ̀ rẹ̀.

Ó ní Raheemat ti máa ń pàdánù oyún látẹ̀yìn wá tó sì ti rò wí pé ọmọ ni òun ń lọ bí nígbà tó ń lọ sílé ìwòsàn ṣùgbọ́n tí ọ̀rọ̀ kò rí bó ṣe rò, tó pàdánù oyún náà.

Ó sọ pé èyí ló mu gba ìpínlẹ̀ Kwara lọ láti lọ bá bàbá rẹ̀, tó sì parọ́ fún ọkọ̀ rẹ̀ pé wọ́n ti jí òun gbé ni.

Agbẹnusọ ọlọ́pàá náà fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé Raheemat àti bàbá rẹ̀ ló padà sí ìlú Abeokuta fúnra wọn lẹ́yìn tí àwọn ọlọ́pàá ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti ṣàwárí rẹ̀.

Ṣáájú ni ọkọ Raheemat ti lọ sí àgọ́ wọn láti lọ fẹjọ́ sùn pé àwọn ajínigbé ti jí ìyàwó òun gbé nígbà tó ń lọ sílé ìwòsàn láti lọ bímọ.

“Kìí ṣe pé wọ́n jí Raheemat gbé rárá, òun fúnra rẹ̀ ló wọkọ̀ lọ sí ìpínlẹ̀ Kwara nítorí kò mọ ohun tí ọkọ rẹ̀ máa sọ lẹ́yìn tó pàdánù oyún inú rẹ̀.

“Ẹ̀ka tó ń rí sí ìgbógunti ìjínigbé ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ìjínigbé rẹ̀ kó tó di pé òun àti bàbá rẹ̀ yọjú sí àgọ́ ọlọ́pàá.”

Odutola ní Raheemat ti wà ní ilé ìwòsàn níbi tó ti ń gba ìtọ́jú.

Ní Ọjọ́bọ̀ ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni ọkọ̀ Raheemat, Ogunbunmi Lateef lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá láti lọ fẹjọ́ sùn pé òun gba àtẹ̀jíṣẹ́ kan lórí ìkànnì WhatsApp òun pé wọ́n ti jí ìyá òun gbé.