Ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ elétò ìlera l’Ọyọ gbèrò láti bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì

Patako ijuwe ileewosan ijọba ipinlẹ Oyo

Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ eleto ilera ni orilẹ ede Naijiria, ẹka ti ipinlẹ Ọyọ ti bẹrẹ iyanṣẹlodi lati kilọ fun ijọba lori awọn ẹtọ wọn.

Ninu atẹjade ti akọwe ẹgbẹ ọhun, Suraju Alabi, fi lede ni wọn ti fun ijọba ipinlẹ Ọyọ labẹ iṣejọba Gomina Seyi Makinde ni gbedeke ọjọ mẹrinla lati fesi si awọn ohun ti wọn n beere fun, ko si di mimuṣẹ.

Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ eleto ilera ọhun ṣalaye ninu lẹta naa wi pe, ijọba ko ti i gbe igbesẹ kan lori gbogbo ibeere wọn titi di akoko yi.

Nidi eyi, ẹgbẹ naa ti fẹnuko lati bẹrẹ iyanṣẹlodi ọlọjọ meje ki wọn lee fi ṣekilọ fun ijọba ipinlẹ Ọyọ.

Ọjọ́ wo ni ìyanṣẹ́lódì oníkìlọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ elétò ìlera náà bẹ̀rẹ̀?

Aworan Gomina Seyi Makinde ti ipinlẹ Ọyọ

Oríṣun àwòrán, Oyo state Government

Iyanṣẹlodi naa lo ti gberasọ lati oru ọjọ Aje, ọjọ kẹrinlelogun, osu kẹfaK Ọdun 2024.

Ẹgbẹ naa kesi awọn ọmọ ẹgbẹ wọn gbogbo, tofimọ awọn ẹka miran to so mọ wọn lati tẹle aṣẹ ọhun ni kiakia.

Bakan naa, ni wọn ko sai tun fi lede pe lẹyin ti iyanṣẹlodi onikilọ ọlọjọ meje naa ba pari tan, ni wọn yoo mọ igbesẹ to kan lati gbe lori ọrọ naa.

Amọ abẹwo BBC si ileewosan ijọba ipinlẹ Oyo to wa ni agbegbe Ring Road niluu Ibadan, fihan pe iyanṣẹlodi naa ko fidimulẹ.

Akọroyin BBC sọ pe awọn oṣiṣẹ n da awọn alaisan logun, ti ohun gbogbo si n lọ deedee.

Ao maa mu ẹkunrẹrẹ iroyin naa wa fun yin to ba ṣe n lọ