'Ọmọ mi ti pé ọmọ ọdún méje, àmọ́ ó sì dàbí ọmọ ọwọ́, kò sì le dá nkankan ṣe'

Àkọlé fídíò,
'Ọmọ mi ti pé ọmọ ọdún méje, àmọ́ ó sì dàbí ọmọ ọwọ́, kò sì le dá nkankan ṣe'

Ọdun 2017 ni wọn bi Suebat, amọ titi di asiko yii, ko tii le ṣe ohunkohun ti awọn ẹgbẹ rẹ n ṣe.

Awọn obi rẹ, Taiye ati Abdulganiyu Zakariyau, ṣi n ni ireti pe lọjọ kan, ọrọ aye rẹ yoo yii pada.

Ọmọ mẹrin ni awọn obi suebat, to n gbe niluu Ilorin, ti bi ṣaaju ati lẹyin ti wọn bi i, ko si si eyi to ni iru idagbasoke bẹẹ laarin wọn.

Iya Suebat sọ fun BBC ninu ifọrọwanilẹnuwo pe, ọmọ ọhun to ti pe ọmọ ọdun meje, kere pupọ to si dabi ọmọ ọdun kan.

“Ko le sọrọ, ko le rin, ko le lọ sile ẹkọ tabi ile keu bi awọn ẹgbẹ rẹ.

“Ko si nnkan to le da sẹ funra rẹ. Oju kan naa to n joko si lo n tọ si, to tun n ṣe igbọnsẹ si.”

O ni inu oun ko dun si ipo ti ọmọ naa wa.

“Gbogbo nnkan ti wọn ni ki n ṣe ninu oyun, ni mo sẹ. Amọ mi o mọ bi ọmọ mi ṣe wa a ri bayii.”

Ọdọ iya agba Suebat lo n gbe, ti iya naa si ti koju oriṣiriṣi idẹyẹsi ati ikorira lati ọdọ awọn alajọgbele ati aladugbo nitori ọmọ naa.

Iya suebat sọ pe niṣe ni wọn le iya agba naa kuro ninu ile to n gbe tẹlẹ, ‘ ti wọn si sọ fun pe awọn ko le fi aaye gba iru ọmọ bẹẹ ninu ile awọn”.

Yoruba sọ pe ọmọ ẹni ko le ṣe idi bẹbẹrẹ, ka fi ilẹkẹ sidi ọmọ ẹlomii.

Baba Suebat, Ọgbẹni Zakariyau sọ dun BBC pe, oun nifẹ ọmọ oun pupọ, lai fi ti ipo to wa ṣe.

Ki ni nnkan to le mu ki ọmọ ri bii ti Suebat?

Dokita Yusuf Mohammed, to jẹ dokita awọn ọmọde ni ileewosan ikọṣẹ iṣegun Fasiti ilu Ilorin, sọ pe aijẹ ounjẹ aṣaraloore, aarun tabi ajogunba le faa ki ọmọ o ma dagba daadaa.

Mohammed to jẹ olori ni ẹka itọju awọn ọmọde nileewosan ọhun ṣalaye fun BBC pe to ba jẹ ajogunba ni, o ṣoro lati tọju nitori pe ko ṣeeṣe lati mu ayipada ba nnkan to waninu ara ọmọ naa.

Bakan naa lo sọ pe lati ara obi, ni ọmọ ti ma n jogun iru rẹ.

Yatọ si eyi, onimọ iṣegun ọhun tun sọ pe iṣoro yii le jẹyọ ti aleebu ba wa lara eroja protein to wa ninu ara, aarun, tabi awọn iṣẹlẹ ayika ti ọmọ naa fi ara ko lẹyin ti wọn bi.

O ni iru itọju wọn yoo fun ọmọ ti ko ba dagba, yoo nii ṣe pẹlu nnkan to fa a .

Dokita wa a gba tọkọtaya ni imọran lati lọ fun ayẹwo, ki wọn to o bẹrẹ sii bimọ.