Ṣọ́ọ̀ṣì wa tó jóná l’Eko ti fún wa lánfààní láti kọ́ ilé ìjọsin Christ Embassy míì tó tóbi ju ti tẹ́lẹ̀ lọ - Oyakhilome

Aworan Pasitọ Chris Oyakhilome

Oríṣun àwòrán, loveworldincorporated/Instagram

Oludasilẹ ijọ LoveWorld ti ọpọ eeyan mọ si Christ Embassy, Pasitọ Chris Oyakhilome to sọ pe ile ijọsin ijọ naa to jona lagbegbe Oregun ni Ikeja niluu Eko jẹ anfani lati kọ ṣọọṣi miran to tobi to ṣi tun rẹwa ju ti tẹlẹ lọ.

Pasitọ Oyakhilome sọrọ yii ni ipagọ ṣọọṣi naa to wa ni Asese nipinlẹ Ogun lọjọ Aiku ọjọ kẹtalelogun oṣu Kẹfa ọdun 2024 yii.

Laarọ ọjọ Aiku yii naa ni ile ijọsin ọhun to wa ni Ikeja jona, eyi ti ọpọ eeyan ṣi pin fidio bi ṣọọṣi ọhun ṣe n jona kaakiri itagun ori ayelujara.

Nigba ti o n ṣorọ lori iṣẹlẹ ijamba ina ọhun, oludasilẹ ijọ Christ Embassy sọ pe ‘’ko si nnkan kan to maa ṣẹlẹ si ọmọ Ọlọrun lai ro tẹlẹ.

Nigba ti ado oloro to bu gbamu ni bareke awọn sọja ni Ikeja lọdun 2001, ile ijọsin wa yii mi titi lasiko naa.

A tiẹ ro pe o maa wo lulẹ ni, nigba naa ni mo ro pe ti o ba fi le wo lulẹ, a yoo kọ omiran to tobi ju u lọ ni.

A ranṣẹ pe awọn onimọ ẹrọ nipa ile kiko lati ṣayẹwọ ile ijọsin naa, wọn ṣi sọ fun wa pe ko si nkan to ṣe ile ijọsin naa.

Ṣugbọn bayii ti iṣẹlẹ ina yii ti waye, a maa kọ ile ijọsin miran to tobi ju eleyii to jona lọ, Eṣu lo ni ibanujẹ.’’

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post

Ìjàmbá iná ṣọṣẹ́ nílé ìjọsìn Christ Embassy ní Eko

Àwòrán bí ilé ìjọsìn náà ṣe ń jó

Oríṣun àwòrán, CHANNELS TV

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Iléesẹ́ panápaná ìpínlẹ̀ Eko ti ní àwọn ti mójútó ìjàmbá iná tó bẹ́ sílẹ̀ ní oríko ilé ìjọsìn Christ Embassy Church tó wà ní agbègbè Oregun, Ikeja, ìpínlẹ̀ náà.

Àtẹ̀jáde tí iléeṣẹ́ náà fi sórí ayélujára X wọn lọ́jọ́ Àìkú, ọjọ́ Kẹtàlélógún oṣù Kẹfà, ọdún 2024 ní nǹkan bíi aago mẹ́jọ òwúrọ̀ kú ìsẹ́jú mẹ́rìnlélógún ni àwọn òṣìṣẹ́ panápaná láti àti Ikeja balẹ̀ sí ilé ìjọsìn náà.

Ṣaájú ni àwọn fídíò kan ti gba orí ayélujára tó ń ṣàfihàn bí ilé ìjọsìn náà jó, tí èéfín sì gba gbogbo àdúgbò náà kan.

Adarí ilé iṣẹ́ panápaná Eko, Margret Adeseye nínú àtẹ̀jáde náà ṣàlàyé pé gbọ̀ngán tí ìjọsìn ti máa ń wáyé ni ìjàmbá iná náà ti ṣọṣẹ́ jùlọ.

Ó ní àwọn lo àwọn ọkọ̀ ńlá àjọ tó ń mójúto ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní Eko ìyẹn LASEMA láti fi wó àwọn ilé kan kalẹ̀ láti lè dènà ìjàmbá iná ọ̀hún láti ràn kọjá àlà.

Lásìkò tí à ń kó ìròyìn yìí jọ, ó sọ pé òun kò ì tíì mọ ohun tó ṣokùnfà ìjàmbá iná náà àmọ́ àwọn ti rí iná náà pa.

Ó fi kun pé kò sí ẹnìkankan tó kú tàbí farapa nígbà tí àtẹ̀jáde náà fi ń jáde àti pé ìwádìí ń lọ lọ́wọ́ láti mọ ìdí ìjàmbá iná náà.

Ile ijọsin Christ Embassy to jona

Oríṣun àwòrán, @LagosRescue/X

Ile ijọsin Christ Embassy to jona

Oríṣun àwòrán, @LagosRescue/X

Ile ijọsin Christ Embassy to jona

Oríṣun àwòrán, @LagosRescue/X