Wo bí àwọn ọmogun Israel ṣe so ọmọ Palestine to farapa mọ́ iwájú ọkọ̀ wọn

Aworan ọmọ Palestine

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ileeṣẹ ologun orilẹede Israel ti sọ pe awọn ọmogun oun ti wọn so ọmọ Palestine kan to ṣeṣe mọ iwaju ọko wọn nigba ti wọn ṣe ikọlu si ilu Jenin tapa si ofin.

Ileeṣẹ ologun Israel sọrọ yii lẹyin ti fidio bi wọn ṣe so ọmọ Palestine naa mọ iwaju ọkọ lu ori itakun ayelujara pa.

Ajọ ologun IDF naa sọ pe ọkunrin ọhun farapa lẹyin ti o doju ibọn kọ awọn ọmogun Israel lasiko ikọlu naa.

Ẹbi ọkunrin naa sọ pe nigba tawọn beere fun ọkọ anbulansi lati gbe e lọ fun itọju ni awọn ọmogun Israel fi aṣọ we e ti wọn ṣi so o mọ iwaju ọkọ wọn ti wọn ṣi wa a lọ.

Wọn pada gbe ọkunrin to ṣeṣe naa lọ sọdọ awọn ajọ alaanu Red Cross fun itọju.

Ileeṣẹ ologun Israel ti sọ pe awọn yoo ṣe iwadii iṣẹlẹ ọhun.

Awọn o ṣoju mi koro kan sọ fun ileeṣẹ iroyin Reuters pe awọn da ọkunrin naa mọ, wọn ni Mujahed Azmi lorukọ rẹ n jẹ.

‘’Ni aarọ ọjọ Abamẹta nibi ti a ti fẹ mu awọn afurasi agbesunmọmi kan lagbegbe Wadi Burquin lawọn agbesunmọmi ti doju ibọn kọ awọn ọmogun Israel, eyi tawọn naa ṣi yinbọn ti wọn naa pada.

Lasiko ti eyi n lọ lọwọ ni ọkan lara awọn afurasi agbesunmọmi yii farapa.

Bayii lawọn ọmogun IDF so afurasi naa mọ iwaju ọkọ wọn, eyi to lodi si ofin.

A n fi asiko sọ pe ihuwasi awọn ọmogun yii lodi si ohun ti ileeṣẹ ologun IDF gbagbọ ninu rẹ.

A o ṣi ṣe iwadii iṣẹlẹ naa bi a ṣe sọ laipẹ.

Ikọlu ti n waye lera lera lagbegbe West Bank lati igba ti ogun ti bẹ silẹ laarin Israel ati Palestine lẹkun Gaza, lẹyin ti ẹgbẹ Hamas ṣe ikọlu si apa guusu Israel lọjọ keje oṣu Kẹwaa to lọ.

Ajọ iṣọkan agbaye, UN sọ pe okoo din ni ẹẹdẹgbẹta(480) ọmọ Palestine lo ti gbẹmi mi lagbegbe West Bank.

Bakan naa, awọn ọmogun Israel mẹwaa lo ti ku lagbegbe naa.