EFCC nawọ́ gán òṣìṣẹ́ báǹkì méjì tó lẹ̀dí àpòpọ̀ gbowó N4.2m lákoto oníbàárà tó dolóògbé

Àwọn afurasí òṣìṣẹ́ tó gba owó jáde ní akoto olóògbé

Oríṣun àwòrán, EFCC/X

Àjọ tó ń gbógúnti ìwà àjẹbánu ní Nàìjíríà, ìyẹn Economic and Financial Crimes Commission, EFCC ní àwọn ti nawọ́ gán àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìfowópamọ́ méjì kan fẹ́sùn pé wọ́n gba owó mílíọ̀nù mẹ́rin náírà ní akoto owó olóògbé kan.

EFCC ní ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kọkànlélógún, oṣù Kẹfà, ọdún 2024 ni ọwọ́ tẹ àwọn afurasí, Idah Ogoh àti Agbo Okwute tó jẹ́ òṣìṣẹ́ tẹ́lẹ̀ rí ní ilé ìfowópamọ́ Union Bank ní ìlú Makurdi, ìpínlẹ̀ Benue.

Àtẹ̀jáde tí EFCC fi sórí ìkànnì X wọ́n lọ́jọ́ Àbámẹ́ta ní ilé ìfowópamọ́ ọ̀hún ló kọ ìwé ránṣẹ́ sí àwọn láti fi ẹjọ́ àwọn afurasí náà sùn lórí bí àwọn afurasí náà ṣe gba owó nínú akoto owó olóògbé náà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Emmanuel Azer Agenna.

EFCC ṣàlàyé pé àṣírí àwọn afurasí náà tú nígbà tí àwọnh ẹbí olóògbé náà kàn sí ilé ìfowópamọ́ láti bèèrè iye tó wà nínú akoto owó olóògbé náà láti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ tí wọ́n fi máa gba owó náà jáde.

Wọ́n ní iye tí ilé ìfowópamọ́ sọ wí pé ó wà nínú àkáǹtì jẹ́ ohun tó kéré jọ́jọ́ sí iye tí wọ́n ń retí láti gbọ́. Èyí ló mú wọn kọ̀wé sí ilé ìfowópamọ́ náà pé kí wọ́n bá àwọn ṣe ìwádìí bí owó ṣe jáde ní akoto olóògbé náà lẹ́yìn tó jáde láyé.

Lẹ́yìn náà ni ilé ìfowópamọ́ náà bẹ̀rẹ̀ ìwádìí tí ìwádìí sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé wọ́n ṣe káàdì ATM ní orúkọ olóògbé lọ́jọ́ Kẹwàá oṣù Karùn-ún ọdún 2023.

EFCC fi kun pé ìwadìí náà fi hàn pé Idah Ogoh ló gbé káàdì náà jáde tó sì fi lé Agbo Omwute lọ́wọ́ láti mu fún ará ìta mìíràn tí wọ́n fi gba owó jáde ní akoto ọ̀hún.

Àpapọ̀ iye owó tí wọ́n ti gbà jáde nínú àkáǹtì náà ti lé ní mílíọ̀nù mẹ́rin náírà.

EFCC tẹ̀síwájú pé ìwádìí ṣì ń lọ lórí ẹ̀sùn náà àti pé ní kété tí àwọn bá ti parí ìwádìí àwọn ni àwọn máa gbé àwọn afurasí náà lọ sí ilé ẹjọ́.

Àtẹ̀jáde tí EFCC fi sórí X

Oríṣun àwòrán, EFCC/X