Wo ohun tí ọlọ́pàá Eko sọ lórí ikú okùnrin tí àwọn ọlọ́kadà ń tẹ orí rẹ̀ mọ́lẹ̀ láàrín ọ̀nà yìí

Oríṣun àwòrán, BIGWIG AUSTIN
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti bẹrẹ iwadii lori iku araalu kan ti wọn fi oku rẹ silẹ lẹgbẹ titi loju ọna marose Mile 2 si Oshodi nipinlẹ naa.
Iroyin ni awọn ọlọpaa kan to n ṣiṣẹ lọna aitọ lo ṣokunfa iku ọkunrin naa.
Ṣaaju ni fidio kan to gba omi loju eeyan ti kọkọ gba ri ayekjara kan lọjọ Ẹti, ninu eyii ti awọn ọlọkada kan ti n tẹ ori oku oloogbe naa kọja laarin titi.
Ẹni to pin fidio ọhun, Bigwig Austin, pe akiyesi ijọba ipinlẹ Eko si fidio ọhun, to si bẹbẹ fun iwadii ni kankan.
Ẹwẹ, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin ti sọ pe ọwọ ti tẹ awọn to ṣokunfa iku ọkunrin naa, iwadii si ti bẹrẹ.

Oríṣun àwòrán, Benjamine Hundeyin
Hundeyin ni awọn ọlọpaa kan to lọ ṣiṣe lọna aitọ lo ṣokunfa iku ọkunrin ọhun, wọn si ti wa ni ahamọ fun iwadii.
Ninu atẹjade kan loju po X rẹ, Hundeyin ni “ọlọpaa meji kan to wa ni ẹka ‘task force’ lo lọ ṣiṣẹ ti ko ba ofin mu lọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2024, ti wọn tun ko awọn araalu kann mọra ki wọn le pọ.
“Idi iṣẹ ti ko ba ofin mu naa ni awọn ọlọkada ti kọju ija si wọn, ti ọkan lara awọn araalu naa si jade laye.
“A ti bẹrẹ eto ifiyajẹni fun awọn ọlọpaa naa to ti wa ni atimọle bayii, a si sti bẹrẹ si n wa awọn ti wọn jọ ṣiṣẹ naa.
“A tun ti bẹrẹ iwadii lati fi ṣikun ofin mu awọn ti wọn n tẹ oku ọkunrin naa mọlẹ ki wọn le foju wina ofin.















