Wo àwọn àǹfàní tó wà lára ẹ̀pà

Ẹ̀pà

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Káàkiri àdúgbò lásìkò yìí ni ẹ ó ti máa ri tí àwọn èèyàn ń ta ẹ̀pà yálà yíya tàbí sísè.

Bẹ́ẹ̀ náà ni ó ṣe rí káàkiri ìlú Dakar, Lomé Cotonue, tó fi dé Abidjan. Níbi yìí ni ẹ ó ti máa rí àwọn obìnrin tí wọ́n ń pàtẹ ayanran kalẹ̀ pẹ̀lú ìkòkò tí wọ́n bu ìyẹ̀pẹ̀ sí láti fi máa yan ẹ̀pà wọn.

Bákan náà ló gbajúmọ̀ láti rí kí àwọn èèyàn máa jẹ ẹ̀pà ní àjẹrìn láì náání pé ojú títì ni àwọ wà nítorí ìfẹ́ tí wọ́n ní sí èso yìí.

“Gbogbo nǹkan tó bá jẹ mọ́ ẹ̀pà ni mo fẹ́ràn, láti kékeré ni mo ti fẹ́ràn rẹ̀,” Ahmed òṣìṣẹ́ ilé ìfowópamọ́ kan sọ fún BBC bí ó ṣe ń jẹ ẹ̀pà lájẹrìn ní òpópónà kan ní ìlú Dakar.

“Mo lè fi ọ̀sẹ̀ kan jẹ ẹ̀pà láì jẹ oúnjẹ mìíràn,” ó bú sẹ́rìn-ín bí ó ṣe ń ṣàlàyé pé òun máa ń ní ẹ̀pà ní ọ́fíìsì tóun máa ń wọ́n sẹ́nu bó bá fẹ́ rẹ òun.

Ọ̀pọ̀ nǹkan ni wọ́n máa ń fi ẹ̀pà ṣe – kúlíkúlí, òróró, tó fi mọ́ ọbẹ̀. Ọbẹ̀ ẹ̀pà yìí ni àwọn èèyàn orílẹ̀ èdè Togo, Benin, Senegal àti Ivory coast máa ń lo láti fi jẹ fufu.

Ẹ̀wẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn tó fẹ́ràn láti máa jẹ ẹ̀pà kàn máa ń jẹ ẹ́ lásán nítorí ìfẹ́ tí wọ́n ní sí i ni, ọ̀pọ̀ ni kò mọ àǹfàní ìlera tí jíjẹ ẹ̀pà máa ń bí fún ara wọn.

Àwọn àǹfàní inú ẹ̀pà

Ìyà tó ń ta ẹ̀pà

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ẹ̀jà jẹ́ èso tó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àǹfàní àti ìwúlò fún ara. Ó ní àwọn èròjà aṣaralóore bíi lipids (49g), proteins(26g), àti carbohydrates(16g). Bákan náà ló ní fiber àti ṣúgà, òróró inú ẹ̀pà jẹ́ èyí tó dára gidi.

Onímọ̀ nípa ìmọ́tótó oúnjẹ, tó tún jẹ́ adarí ní iléeṣẹ́ NFS-Togo dietotherapy practice, Mathieu Kponou Tobossi ní èròjà aṣaralóore arachine àti cona-arachine ni ó pọ̀jù nínú protein tó wà nínú ẹ̀pà.

Bákan náà ló tún ní àwọn èròjà vitamin àti mineral tó fi mọ́ biotin, copper, vitamin B1, B3, B9, vitamin E, manganese, phosphorus, magnesium àti nitric oxide.

Tobossi ní gbogbo àwọn èròjà aṣaralóore yìí tó wà nínú ẹ̀pà jẹ́ ìdí tó ṣe yẹ kí àwọn èèyàn máa jẹ èso yìí fún ìlera tó péye.

Àwọn àǹfàní ìlera inú ẹ̀pà

Ẹ̀pà

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Èròjà lipid tó wà nínú ẹ̀pà túmọ̀ sí pé wọ́n máa ń pèsè agbára láti fún èèyàn lókun tó bá jẹ ẹ́. Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn vitamin bíi biotin tó wà nínú ẹ̀pà dára púpọ̀ fán àwọn aláboyún nítorí wọ́n máa ń pèsè folic acid àti vitamin B9 èyí tí olóyun nílò fún ìlera ọmọ.

Bí èèyàn kò bá ní èròjà copper lára tó bí ó ṣe yẹ, ó ṣeéṣe kí onítọ̀hún ní ìpèníjà pẹ̀lú ọkàn rẹ̀ àmọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ copper ló wà nínú ẹ̀pà. Bẹ́ẹ̀ náà ni vitamin B3 tó wà nínú ẹ̀pà dára láti lé àìsàn ọkàn jìnà.

Phosphorus àti magnessium tó jẹ́ èròjà fún ìdàgbàsókè egungun pọ̀ nínú ẹ̀pà, tí vitamin E inú rẹ̀ sì jẹ́ sàgbàdèwe.

Bákan náà ni phytosterols tó wà nínú ẹ̀pà kìí fi àyè gba cholesterol tó kò dára láti dúró sínú ẹ̀yà ara tó máa ń lọ oúnjẹ.

Òróró ẹ̀pà

Òróró ẹ̀pà

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Dókítà Tobossi ní òróró ẹ̀pà jẹ́ èyí tó dára gidi ní jíjẹ pàápàá fún díndín nǹkan nítorí kò ní ohun tí àwọn olóyìnbó ń pè ní “saturated fatty acids”.

Ó ṣàlàyé pé kò ní cholesterol tó lè dìpọ̀ sí ọkàn tàbí àwọn iṣan ara.

Ó ní gbogbo àwọn èàyàn tó bá ní ìpèníjà bíi arunmọléegun, ìtọ̀ ṣúgà, kí ẹran ara máa dun èèyàn, ọgbẹ́ inú, kí ikùn máa tóbi àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ni àwọn máa ń rọ̀ láti máa jẹ òróró ẹ̀pà.

Àwọn àbùdá ẹ̀pà

Ẹ̀pà tútù tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ hú

Oríṣun àwòrán, Getty Images

  • Kò ní ọ̀rá tí olóyìnbó ń pè ní saturated fat
  • Ọ̀pọ̀ protein tó jẹ́ ti èso ló wà nínú rẹ̀
  • Ó ní calorie tó pọ̀ púpọ̀
  • Ó máa ń dá ààbò bo ọkàn èèyàn

Gbogbo àwọn àbùdá yìí jẹ́ kí ẹ̀pà jẹ́ èso tí wọ́n máa ń sọ fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti máa jẹ àmọ́ ní ìwọ̀túnwọ̀nsì.

Bí ẹ̀pà ṣe ní àǹfàní tó pọ̀ yìí náà ló jẹ́ pé tí àwọn mìíràn bá jẹ ẹ́, ó máa ń fa àwọn kùdìẹ̀kudiẹ kan sí ara wọn.

Àwọn kèdìẹ̀kudiẹ inú ẹ̀pà

Fún ẹni tó bá ní ìpèníjà ìlera ní ilé ìtọ̀ rẹ̀, kò dára fún irú ẹni bẹ́ẹ̀ láti máa jẹ ẹ̀pà nítorí oxalate tó wà nínú rẹ̀.

Dókítà Tobossi ní tí ẹlòmíràn bá jẹ ẹ̀pà, ara rẹ̀ yóò máa ṣú lójú, lábíyá àtàwọn ibòmíràn lára. Ó ní àwọn èèyàn báyìí gbọ́dọ̀ yàgò fún ẹ̀pà ní jíjẹ.

Ó ní ó ṣe pàtàkì láti yọjú sí àwọn onímọ̀ ìlera oúnjẹ nígbà tí èèyàn bá ṣe àkíyèsí kan pàtàkì lára rẹ̀ lẹ́yìn tó bá jẹ ẹ̀pà àbí àwọn oúnjẹ mìíràn.