Kí ni ìdí tí ooru àmújù fi ṣekúpa ọ̀pọ̀ èèyàn ní Hajj ọdún yìí?

Aworan awọn eeyan ni Hajj

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iṣẹ Hajj ti ọdun yii lọ jẹ eyi to ni ọpọ ohun ibanujẹ ati ajalu, o kere ju eeyan 922 ti wọn jẹ arin irinajo wa si Hajj lati oriṣiriṣi ẹya ati orilẹede lo ti padanu ẹmi wọn, pupọ wọn ni wọn jade laye nitori ooru amuju, gẹgẹ bii ile-iṣẹ iroyin AFP ṣe sọ.

Hajj, jẹ ọkan lara ibi ti ero ma n pọju lagbaye, to si n mu ọpọlọpọ miliọnu owo wa si Saudi Arabia ni ọdọọdun.

Irinajo yii jẹ ọranyan fun awọn ẹlẹsin Musulumi – to si jẹ ọkan to ma n waye lẹẹkan-ni-ọdun fun awọn Musulumi to ni owo ati ara pipe - eyi to pari ni Ọjọbọ.

BBC ko le ni anfani fidi iye awọn eeyan to ti jade laye mulẹ .

Ni ọjọ Kọkandinlogun ati Ogunjọ Oṣu Karun un, BBC beere lọwọ awọn alaṣẹ Saudi lati sọrọ lori awọn iṣẹlẹ iku ati awọn ọrọ abuku ti wọn n sọ si ijọba ṣugbọn a ko ri esi gba.

Aworan awọn eeyan ni Hajj

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ẹwẹ, ijọba ti kede aṣeyọri awọn eto ilera rẹ fun akoko Hajj ti ọdun yii.

"Akoko Hajj jẹ igba ti eyikeyi itankalẹ ko besile tabi dunkoko si ilera eeyan, pẹlu iye eeyan to jẹ arin irinajo ati ilakọja ooru amuju,” Minisita fun eto Ilera ni Saudi, Fahad al-Jallayel sọ ninu atẹjade ọrọ kan.

Awọn alaṣẹ Saudi sọ pe o fẹ to eeyan milọnu 1.83m awọn arin irin ajo to kopa ninu eto Hajj ni ọdun yii, pẹlu eeyan 1.6 milionu ti o de lati oke okun. Iye awọn eeyan to pọju, ti wọn jẹ alejo wa lati orilẹede Pakistan, Jordan ati Tunisia.

BBC wo ohun to le ṣokunfa iku ọpọlọpọ eeyan nibi Hajj ọdun yii:

Aworan

Ooru Amuju

Ooru gbigbona ni Saudi Arabia, to le ni ida 51.8, ni gbagbọ wa pe o jẹ iṣokunfa bi awọn eeyan ṣe n ku.

Pelu ikilọ lati Ile-iṣẹ Ilera Saudi Arabia lati yago fun ifihan ooru ati pe ki awọn eeyan ma mu omi, ọpọlọpọ awọn arin irinajo lo padanu ẹmi wọn nitori ipalara ooru ati igbona.

Aworan awọn eeyan ni Hajj

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọkunrin kan lati Arab sọ pe o fẹ to gbogbo awọn eeyan 658 to padanu ẹmi wọn ti wọn jẹ ọmọ ilẹ Egypt ni akoko ti ooru amuju naa bẹ silẹ.

Pupọ ninu awọn arin irinajo wọnyi ko ni awọn iwe aṣẹ igbanilaaye Hajj to jẹ ojulowo, eyi ti ko gba wọn laaye lati pese awọn ohun iranwọ tabi ni anfani si awọn ohun iranwọ..

“Anu Olorun nikan ni lo mu mi ye, nitori pe o gbona gan-an,” Aisha Idris, arin irinajo omo Naijiria kan, nigba to n ba akoroyin BBC World Service’s Newsday sọrọ.

"Wọn ti gbogbo ilẹkun si Kaaba (ile okuta ti o wa ni arin Mossalassi to se pataki julọ ni Islam). A ni lati lo gba oke ile, ti o n jo."

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

"Mo ni lati lo agboorun kan, ti mo si ni fi igbagbogbo mu omi Zamzam (omi mimọ) fun ara mi,"

"Mo ro pe mo le daku ni aaye kan, to jẹ pe ẹnikan ni lati ran mi lọwọ pẹlu agboorun. Emi ko reti pe ooru naa yoo lagbara, "o ṣe afikun.

Arin irinajo miiran, Naim, padanu ẹmi rẹ sọwọ ooru gbigbona, ti o fi idile rẹ silẹ lati wa idahun.

"Ibaraẹnisọrọ pẹlu iya mi ni o ge lojiji. A lo ọpọlọpọ ọjọ n wa iya, ki a toti gbọ pe o ti ku lakoko Hajj," ọmọ rẹ sọ fun BBC News Arabic, to si fikun pe ọn yoo bu ọla fun ifẹ rẹ lati sin si Mecca.

Aworan

Awọn arin irin ajo dojukọ awọn ewu nitori ooru ti wọn ko reti, to si ipa iṣẹ ti wọn wa se lara ati pe ọpọlọpọ to jẹ agbalagba tabi ailarẹ, tabi mejeeji ni wọn ko ni alaafia.

Ki eeyan ma ku nitori ooru lakoko Hajj kii ṣe tuntun ati pe o ti wa lati aaye ọdun 1400.

Ni ọdun to kọja, awọn oṣiṣẹ ijọba Saudi ni o to eeyan to le ni ẹgbẹrun meji ti ooru palara laarin awọn arin irinajo.

Awọn onimo ijinlẹ sayensi kilo pe ooru yii n buru si nitori bi agbaye se n moru.

Aworan awọn eeyan ni Hajj

Oríṣun àwòrán, EPA

“Hajj ṣiṣe lasiko ooru to gbona ti wa fun ọjọ pipẹ, ṣugbọn idaamu oju-ọjọ n buru si,” Carl-Friedrich Schleussner ti ile-iṣẹ iroyin Reuters ṣalaye.

Iwadii rẹ ni pẹlu ilosoke 1.5C ni awọn iwọn ooru agbaye ju, ewu ti ooru n fa lakoko Hajj ni o le si ilọpo marun un.

Awọn asọtẹlẹ lọwọlọwọ fihan pe ooru agbaye le to 1.5C ni ọdun 2030, to le fa ipalara fun awọn arin irin ajo ọjọ iwaju.

Aworan awọn eeyan ni Hajj

Oríṣun àwòrán, Getty Images

A pọ ju eeyan ati imọ toto

Gẹgẹ bii ọpọlọpọ eeyan ṣe sọ, aiṣedeede awọn alaṣẹ Saudi mu ki iṣẹlẹ lagbara si, to jẹ ki ọrọ naa buru si ni ọpọlọpọ awọn agbegbefun awọn arin irinajo.

Wọn sọ pe ibugbe ati awọn ohun elo ko ni iṣakoso daradara, pẹlu awọn agọ ti o kunju ti ko ni itutu agbaiye ati awọn ohun elo imototo.

Amina (kii ṣe orukọ rẹ), ẹni ọdun Mejidinlogun kan lati Islamabad, sọ pe: “Ko si ẹrọ amuletutu ninu ni itẹ wa lasiko ooru Mekka. Awọn ẹrọ tutu ti wọn gbe sita ni ko si omi ninu pupọ wọn.

Aworan awọn eeyan ni Hajj

Oríṣun àwòrán, Getty Images

“Ko si ibi a ṣe le mi labẹ itẹ naa, ti gbogbo wa si n lagun, iriri buruku yii,” o ṣafikun.

Fauziah, arin irin ajo kan lati Jakarta, gba, to sisọ pe, “Ọpọlọpọ ti daku nitori apọju eeyan ati ooru ninu itẹ.

“A duro fun ounjẹ alẹ titi di alẹ, nitorinaa ebi n pa awọn eniyan ti o wa labẹ itẹ naa,” o ṣafikun.

Yoo gba awọn ilọsiwaju ṣugbọn o gbagbọ pe, “Eyi ni eto to dara julọ ti Hajj gbe kalẹ”.

Iṣoro irinsẹ

Wọn tun maa n fipa mu awọn arin irin ajo rin awọn irin to jin lakoko ooru gbigbona, pẹlu idalẹbi awọn idena oju ọna ati eto irinna ti ko dara.

Arinrin-ajo kan to jẹ ọmọ ilẹ Pakistan kan ti ko fẹ darukọ rẹ sọ pe: “Wọn gbe wa lọ si ọna to jin to kilomita meje laisi omi, ko si si iboji.

Gege bii o ti ṣe sọ, awọn ọkọ ayọkẹlẹ ijọba Saudi wa, ṣugbọn wọn ko lo wọn fun awọn arinrin ajo ti o ṣe aisan nitori ooru.

"Ninu awọn ibudo, wọn ko awọn eeyan pọ bi adie tabi ẹranko ni oko, ko si aaye lati kọja laarin awọn ibusun, ati pe awọn yara iwẹ diẹ ko to fun awọn ọgọọgọrun eniyan."

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Muhammad Acha, oluṣeto Hajj fun ẹgbẹ aladani kan, sọrọ.

"Eyi ni Hajj Kejidinlogun mi, ninu iriri mi, awọn alakoso Saudi kii ṣe awọn alakoso. Wọn ṣakoso, ṣugbọn wọn ko ki ṣe iranlọwọ, "o sọ.

Gẹgẹ bii Acha, lakoko ooru, arinrin ajo le ni lati rin fun o kere ju kilomita mẹdogun lọjọ kan. Eyi lo n ṣokunfa oorn to n pa wọn laraati ai ni omi mu, o sọ.

"Ni awọn ọdun iṣaaju, aye wa lati wọle si awọn itẹi, ṣugbọn ni bayii gbogbo awọn ọna ni wọn ti di pa.

Abajade rẹ lo fa ti awọn arinrin ajo, paapaa ti o ba wa ni itẹ Ẹka A ni Zone I, ni lati rin awọn kilomita meji ati abọ ninu ooru ooru lati de itẹ wọn," o salaye.

"Ti iṣẹlẹ pajawiri ba waye ni ọna yii, ko si ẹnikan ti yoo de ọdọ rẹ fun ọgbọn iṣẹju.

Ko si awọn eto lati gba ẹmi la, tabi awọn aaye omi ni awọn ọna wọnyi, "Acha ṣe afikun.

Iranwọ eto ilera pipẹ

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọpọlọpọ awọn arinrin ajo ni wọn ko ri itọju to peye gba.

Gẹgẹ bii nọmba awọn arin irin ajo, ọkọ pajawiri,ati ohun iranlọwọ kiakia noi ko si nilẹ fun awọn to ba lugadi ooru yii ati awọn ilera mii.

Amina sọ nigba ti arinrin ajo kanto jẹ akẹgbẹ rẹ nilo atẹgun nitori ailemi rẹ, o gba to iṣẹju mẹdọgbọn fun ọkọ pajawiri lati de pẹlu bi ọpọ ẹbẹ se pọ.

"Lakotan, ọkọ Pajawiri de, ti dokita ko si ri fun isẹju aya meji lọ, to si sọ pe 'ko si ohun ti o ṣẹlẹ si i' o si lọ," o fi kun.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ẹwẹ, Minisita Ilera ti Saudi ti ṣe afihan awọn ohun elo ti a pin lati rii daju pe alaafia wa fun awọn arin irin ajo.

Alaye kan ti ijọba fi lede ni ile-iwosan 189, awọn ile-iṣẹ ilera ati awọn ile-iwosan alagbeka pẹlu agbara apapọ to ni to ibusun 6,500, ati awọn osisẹ ilera 40,000, imọ-ẹrọ, oṣiṣẹ iṣakoso ati awọn oluyọọda.

Wọn tun ni atilẹyin ọkọ pajawiri 370, awọn ọkọ pajawiri afẹfẹ meje, ati ohun irin to pọ ja burata, atẹjade naa ṣalaye.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Awọn arin irinajo ti ko fi orukọ silẹ

Lati ṣe Hajj, alarinkiri gbọdọ beere fun fisa Hajj lọọtọ.

Ṣugbọn awọn eeyan maa n gba ọna eburu lọ ṣe si Hajj lai fọrukọ silẹ.

Ọrọ nipa "Hajj laigba aṣẹ" ni a gbagbọ pe o ṣe alabapin si awọn iku ojiji to n waye.

Awọn arinrin ajo ti ko gba iwe aṣẹ nigbagbogbo ma yago fun awọn alaṣẹ, paapaa nigba ti wọn nilo iranlọwọ.

Awọn alaṣẹ ti da wọn lẹbi fun bii awọn eeyan ṣe pọ labẹ itẹ.

Mustolih Siradj, alaga ti Igbimọ Hajj ati Umrah ti Orilẹ-ede Indonesia (Komnas Haji) sọ pe “A fura pe awọn ti n lo awọn iwe ayedẹru lo jẹ ki ero pọ niawọn agbegbe Hajj”.

AFP sọ ọrọ ọmọwe Arab kan ti o sọ pe o kere ju awọn ara Egipti 658lo ti ku ni akoko yii, ti awọn 630 si jẹ awọn ti ko gba iwe iyọọda wọ Hajj.

Saad Al-Qurashi, oludamọran si Igbimọ Orilẹ-ede fun Hajj ati Umrah, sọ fun BBC pe: “Ẹnikẹni ti ko ba ni iwe iwọlu Hajj ni ko le faye gba ati pe o gbọdọ pada si orilẹ-ede rẹ.”

Aworan

Oríṣun àwòrán, Nusuk Platform

Awọn arin irin ajo Hajj to jẹ Arugbo, ailarẹ

Ọpọlọpọ awọn arin irinajo ma lọ si Hajj si opin aye wọn, boya lẹyin to ti fowo fun igbesi aye rẹ, tabi ni ireti pe awọn yoo ku sibẹ.

Fun apẹẹrẹ agbegbe Musulumi ni Bangladesh ni wọn padanu ẹmi wọn lakoko ṣiṣe Hajj. Wọn gbagbọ pe yoo fun wọn ni ipo pataki kan.

Eyi jẹ ọkan ninu awọn idi ti awọn iku fi wa ni ọdọọdun ni Hajj. Ni akoko 2022-23, o le ni igba eeyan

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ki lo ma ṣẹlẹ ti eeyan ba ku lasiko to wa ni Hajj?

Nigba ti arin irin ajo Hajj ba ku lasiko ti o n ṣe Hajj, iku ni wọn n pe iṣẹ Hajj. Wọn ma lo awọn ẹgbaọwọ tabi awọn ohun idanimọ lati ṣe idanimọ naa. Lẹyin naa, wọn yoo pese iwe-ẹri dokita, ti Saudi Arabia fun iwe-ẹri iku.

Awọn adura isinku yoo waye ni awọn mọṣalaṣi pataki bii Masjid al-Haram ni Mekka tabi Mossalassi Anabi ni Medina, da lori ibiti iku naa ti waye. Wọn ma fọ ara, ti wọn a we, ati gbe sinu awọn firisa ti ijọba Saudi ti pese.

Awọn eto isinku jẹ rọrun, laisi awọn ami, nigba mii pẹlu ọpọlọpọ awọn ara ni ibi kan. Iwe itẹ oku naa ṣe akojọ awọn ti wọn sin nibẹ, lati fun awọn idile ni anfani lati ṣabẹwo si awọn iboji ti wọn ba fẹ.

Ijọba Saudi, pẹlu iranlọwọ lati awọn ẹgbẹ oriṣiriṣi ati Red Crescent, sọ pe o ni idaniloju "awọn ilana isinku ti o ni ọlá ati ọwọ".