Aláwàdà di Igbákejì ààrẹ ní Malawi

Oríṣun àwòrán, AFP
Ọkunrin alawada kan to mu oṣelu mọ iṣẹ adẹrin p’oṣonu lorilẹede Malawi, Michael Usi, ni wọn ti bura fun bayii gẹgẹ bi Igbakeji aarẹ orilẹ-ede naa.
Oluilu Malawi ti i ṣe Lilongwe ni wọn ti bura fun Usi, ẹni ọdun marundinlọgọta (55) lọjọ Ẹti, ọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹfa ọdun 2024 yii.
Usi lo rọpo Saulos Chilima, igbakeji aarẹ Malawi to ku laipẹ yii ninu ijamba ọkọ ofurufu.
Ṣugbọn iyansipo Michael Usi yii ti pin awọn eeyan ilu naa si meji.
Bawọn kan ṣe n sọ pe ipo naa ko tọ si i nitori gbogbo nnkan lo maa n sọ di ere ati awada, bẹẹ lawọn mi-in n sọ pe o daa bi Aarẹ Chakwera ṣe yan an sipo naa .
Usi funra rẹ mọ pe iyansipo oun ti pin ilu si meji, eyi lo ṣe fi da awọn eeyan ti wọn n foju oniranu wo o loju pe oun yoo jọ wọn loju nipa ṣiṣe daadaa nipo naa.
O ni pẹlu ẹmi imoore ati ibanujẹ loun fi gba ipo tuntun yii, nitori ọrẹ oun ninu oṣelu ni Saulos to ku ninu baaluu to já lulẹ.
O dupẹ lọwọ Aarẹ Chakwera ti ko lọọ mu eeyan ninu ẹgbẹ mi-in, afi ẹgbẹ ti Oloogbe Saulos n ṣe nigba aye rẹ.
Ta ni Michael Usi ki o to di igbakeji aarẹ Malawi?

Oríṣun àwòrán, AFP
Ẹnu ki i sìn lara afọkeemu ni ọrọ Micheal Usi ni Malawi.
Idi ni pe ọpọ eeyan lo mọ ọn si orukọ kan, “Manganya”, to maa n jẹ ninu ere kan to gbajumọ lori amohumaworan.
Ipa alawada lo maa n ko ninu ere naa ti wọn n pe ni ‘Tikuferanji’, eyi ti awọn eeyan ko le ma wo.
Koda, lopin ọsẹ to kọja yii, Usi to di Igbakeji aarẹ bayii ṣi ya ere kan to fẹẹ gbe jade, gẹgẹ bi amugbalẹgbẹẹ rẹ ṣe sọ fun BBC.
O ti le logun ọdun ti Igbakeji aarẹ tuntun Malawi yii ti n sọrọ lorii redio to si n han lori amohunmaworan orilẹ-ede naa. Eyi to mu ki gbogbo ilu da a mọ daadaa.
Bakan naa ni Ọmọwe Usi maa n kede idagbasoke ẹka awọn onifiimu ni Malawi.
Ko si owo gidi nibi iṣẹ tiata niluu naa, eyi to fa a to fi jẹ ileewosan lo ti ṣiṣẹ to fi ri owo to ko lọ sidii tiata ati awada.
Ọmọwe Usi kẹkọọ nipa fifun awọn eeyan loogun to yẹ nileewosan, o si n rowo gba lasiko to n ṣiṣẹ lọsibitu ọhun, nitori Malawi ko ni dokita pupọ.
Nipasẹ iṣẹ to n ṣe lọsibitu naa, ọpọlọpọ awọn eeyan agbegbe alaini ni wọn ri iranlọwọ gba.
Usi tun ṣiṣẹ pẹlu ajọ ‘Adventist Development and Relief Agency’ (Adra), ajọ iranlọwọ nilana ẹsin Kristẹni ti ko kan ijọba.
Ọdọ awọn Adra lo ti di olori ẹka oriṣiiriṣii, nibẹ lo si ti n ṣagbatẹru awọn eto lorii redio ati tẹlifiṣan, eyi to n da wọn lẹkọọ lori arun ko gboogun (HIV) ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Igbakeji aarẹ Malawi tuntun yii ti niyawo, o si ni awọn ọmọbinrin meji.
O gboye Ọmọwe (PhD) nipa ẹkọ idagbasoke awọn ọdọ ni University of Bedfordshire, UK.
Gẹgẹ bii alawada to gbajumọ, nigba ti Usi da ẹgbẹ oṣelu kan silẹ lọdun meje sẹyin, ọpọ eeyan ro pe o n mu awọn ṣere bii iṣe rẹ ni.
Eyi ri bẹẹ nitori awọn eeyan mọ fun imuṣere pupọ.
Ọpọ igba lo ti mu awọn eeyan gbagbọ pe abẹṣẹku-bii-ojo loun nigba toun wa nileewe giga, ati pe oun fẹẹ pada sidi ẹṣẹ jija.
Usi ṣeto ija kan to ti loun yoo koju ẹlẹṣẹẹ to lagbara ju lorilẹ-ede naa, obitibiti ero si ya lọ sibẹ lati wo ija ọhun.
Aṣe ko si ija kankan ti yoo waye, o mu wọn ṣere nipa gbigbe ija to ja ninu ere rẹ kan jade fun wọn ni.!
Michael Usi gẹ́gẹ́ bíi olóṣèlú
Sugbọn ṣaa, igbesẹ Usi lati ṣe oṣelu ki i ṣe awada, o pada foju han pe ootọ lo darapọ mọ wọn.
Orukọ to fun ẹgbẹ rẹ (Odya zake alibe Mulandu )tumọ si pe ẹni ti ko ba mu ti ẹlomi-in mọ tiẹ, to n jẹ ohun to ni, o lominira, ko si nigbekun.
Lẹyin igba naa lo darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu UTM, ti Oloogbe Chilima jẹ olori fun.
Eyi waye ki wọn too dibo ọdun 2019, oun ati Chillima, si jọ n polongo ibo pọ ninu ẹgbẹ kan naa.
Ajọṣepọ awọn mejeeji maa n mu ero pupọ tẹle wọn lẹyin, nitori wọn gbo lohun bii ọ̀jẹ̀, wọn mọ bi wọn ti n sọrọ daadaa.
Nigba to di oṣu keji ọdun 2019, Chillima fi Usi ṣe igbakeji rẹ ninu ẹgbẹ UTM.
Ibo ti wọn di ni 2020 lo gbe Aarẹ Chakwera wọle, ti Chilima di igbakei rẹ, ti Usi si jẹ Igbakeji Chilima.
Usi ti figba kan jẹ minisita fun irinajo afẹ, aṣa ati igbo ọba laarin oṣu keje ọdun 2020 si oṣu keji ọdun 2023.
Ipo naa lo wa ti Chilima fi ku, ti Aarẹ Chakwera fi ranṣẹ si i lati waa maa ṣe Igbakeji oun lọ gẹgẹ bi ọrẹ rẹ, Chilima to doloogbe ṣe n ṣe e lọ ki iku too de.
Ṣugbọn awọn agbaagba ẹgbẹ UTM kan ko wa sibi ayẹyẹ ibura Usi, eyi to fi han pe ẹgbẹ ti pin si meji nitori iyansipo yii.
Ọmọwe Usi naa ko foju pa eyi rẹ, o ṣeleri lati mu ẹgbẹ naa pada di ẹyọkan, ki aṣesilẹ Chilima to doloogbe, ẹni ti wọn mọ fun kiko eeyan jọ, paapaa awọn ọdọ, le maa tẹsiwaju.














