Ooru àmújù ṣekúpa èèyàn 577 nínú àwọn tó lọ fún Hajj lọ́dún yìí

Aworan awon musulumi ni Hajj

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Eeyan to din diẹ ni miliọnu meji(1.8m) lo lọ fun Hajj ọdun 2024 yii gẹgẹ bi ohun ti ijọba Saudi sọ.
    • Author, Isidore Kouwonou
    • Role, BBC Afrique

O kere tan, eeyan 577 ti wọn wa lati oniruuru orilẹede ni ooru amuju ṣekupa ninu awọn to lọ fun Hajj lọdun yii ni Saudi Arabia.

Gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin AFP ṣe sọ, ọpọ awọn eeyan to ku yii lo wa lati ilẹ Afirika.

O kere tan, 323 ninu awọn eeyan yii lo wa lati orilẹede Egypt nikan gẹgẹ bi iroyin ti AFP fidi rẹ mulẹ ṣe ṣalaye.

Eeyan to din diẹ ni miliọnu meji(1.8m) lo lọ fun Hajj ọdun 2024 yii gẹgẹ bi ohun ti ijọba Saudi sọ.

Ileeṣẹ ẹrọ amohunmaworan Saudi sọ lọjọ Aje to kẹyin iṣẹ Hajj ti ọdun yii pe oju ọjọ gbona ni iwọn 51.8c ni mosalaasi nla ilu Mecca.

Iṣẹ Hajj jẹ ọkan lara opo marun un to wa ninu ẹsin musulumi, eyi ti musulumi to ba lagbara rẹ gbọdọ lọ lẹẹkan o kere tan ni ọjọ aye rẹ.

Aworan oku awon to ku ni Hajj

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Aworan oku awon to ku ni Hajj

Awọn Musulumi wa si Hajj lati oniruuru orilẹede agbaye

Aṣoju ijoba ni Jeddah, Abdelilah Daddas lo kede ipapoda awọn alalhaji marun un lati Morocco.

O ni awọn to ku yii ni aisan bii itọ-ṣuga, ẹjẹ ruru lara tẹlẹ ki mẹta ninu wọn to ku sinu yara wọn nile itura ti wọn wa.

Aṣoju ijoba Tunisia naa kede pe awọn metalelogun ninu awọn to lọ si Hajj lati orileede naa lo ku.

Eeyan 11,227 lo rinrin ajo lọ si Mecca lọdun yii lati Tunisia.

Awon olujosin ninu oorun ni Mecca

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awon olujosin ninu oorun ni Mecca

Ileeṣẹ ijọba Senegal to n ri si ọrọ ilẹ okeere kede pe eeyan mẹta lo ku ninu awọn to lọ si Hajj lọdun yii lati orilẹede naa.

Ijọba Senegal ti sọ fun aṣojú rẹ pe ko ṣiṣẹ pọ pẹlu ijọba Saudi lati ri pe wọn sin oku awọn eeyan yii si Saudi ni ilana ẹsin musulumi.

Eeyan 12,860 lo lọ si Hajj lati Senegal lọdun yii.

Meji ninu awọn to lọ si Hajj lọdun yii lati orilẹede Naijiria ni a gbọ pe wọn ku sibẹ.

Ooru amuju

Aworan obinrin kan to n rin ni ibi isinku

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, O le ni eeyan 2,000 to ku ni Mina lodun 2015
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Iye eeyan to ku ni Hajj ti ọdun yii ju ilọpo meji ti ọdun 2023 lọ ti i ṣe eeyan 240.

Minisita fun eto ilera ni Saudi sọ pe "o ṣe pataki fáwọn to n ṣiṣẹ Hajj lati wa ninu yara wọn lasiko ti oju ọjọ ba gbona gan an, ayafi ti wọn ba lo aburada loku.

Ohun ti a sọ fáwọn eeyan ni pe ki wọn maa mu omi daadaa, ki wọn si maa lo aburada wọn, ati pe ki wọn ma duro sinu oorun.

Ẹwẹ, Ọba Mohammed bin Salman naa sọ pe ijọba Saudi yoo gbiyanju lati ri pe awọn olujọsin ṣiṣẹ Hajj lai si ewu.

Lọdọọdun ni ẹgbẹẹgbẹrun awọn olujọsin maa n gba ọna mii wa si Hajj tori ọwọngogo owo ati gba fisa.

Iru awọn olujọsin yii ni kii lanfaani sí awọn gbagede ti ẹrọ amuletutu wa ti ijọba Saudi ti pese.

Lọdun yii, iye awọn olujọsin ti ko forukọ silẹ lati Egypt pẹlu ijọba Saudi pọ si.

Ọpọ ninu wọn lo ku tori wọn ko ni omi lati mu tabi ounjẹ lati jẹ fun igba pipẹ.

Ẹwẹ, onimọ nipa ẹsin musulumi, Umar Haruna sọ fun BBC pe "anfani lo jẹ fun olujọsin lati ku si ilẹ mimọ ni Mecca.

Bo tilẹ jẹ pe awọn mọlẹbi awọn eeyan to ku le banujẹ ni tootọ, sugbọn awọn naa gbagbọ pe ibukun lati ọdọ Allah ni ki eeyan ku si Mecca.