Èèyàn kan kú, ọgbọ̀n míràn farapa níbi ìwọ́de àwọn ọ̀dọ́ 'Gen Z' tako ẹ̀kúnwó orí ní Kenya

Aworan ina ti awọn oluwọde da si opopo ni Nairobi

Oríṣun àwòrán, AFP

Eeyan kan ti ku, bẹẹni awọn to eeyan to le ni ọgbọn miran farapa lọjọbọ lasiko iwọde to waye jakejado orilẹede Kenya lati tako erongba ijọba lati fi kun owo ori lorilẹede naa.

Awọn dokita iṣegun oyinbo ni ọta ibọn lo ba ẹni to ku naa ni ilu Nairobi to jẹ olu ilu orilẹede Kenya, to si fi di pe o padanu ọpọlọpọ ẹjẹ.

Ẹgbẹ alagbelebu pupa lorilẹede naa sọ pe eeyan mẹjọ ninu awọn to farapa ni wọn wa ni ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun.

Ọpọlọpọ awọn oluwọde lawọn agbofinro ti ko si atimọle lasiko iwọde naa kaakiri awọn ilu ti iwọde ọhun ti waye.

Awọn ọdọ to n wọde naa n tako afikun owo ori ti ijọba orilẹede naa fi si inu abadofin iṣuna to ṣẹṣẹ gbe jade eyi to la igbesẹ keji kọja ni ile igbimọ aṣofin orilẹede naa.

Ohun ti awọn ọdọ naa n sọ ni pe eyi yoo ṣe akoba fun eto ọrọ aje orilẹede naa, bẹẹni yoo tun di kun ẹru inira awọn eeyan orilẹede naa.

Àwọn ọ̀dọ́ 'Gen Z' ṣèwọ́de tako èròngbà àfikún owó orí búrẹ́dì, epo ìsebẹ̀, páàdì ǹkan oṣù
Aworan odo Kenya

Oríṣun àwòrán, Reuters

Awọn ọdọ langba ṣe iwọde ni orilẹede Kenya lati tako erongba ijọba lati ṣe afikun owo ori ọja lorilẹede naa.

Bi ọrọ ibinu lasan an ni ifẹhonuhan ọhun ṣe bẹrẹ lori itakun ayelujara TikTok ko to ti di iwọde nla bayii.

Ẹgbẹlẹgbẹ awọn oluwọde lo bọ soju popo niluu Nairobi lọjọ Iṣẹgun lai nọọni tajutaju tawọn ọlọpaa n yin lati fi ẹhonu wọn.

Bi wọn ṣe n ṣe iwọde yii ni wọn n lo foonu wọn lati gbe fidio ifehonuhan naa sori ayelujara pẹlu bi wọn ti koju awọn agbofinro gan an nibi iwọde naa.

Aworan awon odo Kenya

Oríṣun àwòrán, EPA

Ifẹhonuhan yii t'awọn ọdọ pe orukọ rẹ ni "ẹ jẹ ka wọ ile aṣofin lọ" ni wọn ṣagbatẹru rẹ lori itakun ayelujara, yatọ si iwọde tawọn oloselu ṣe agbatẹru rẹ.

Awọn to ṣagbatẹru iwọde yii sọ fáwọn oluwọde naa lati wọ asọ dudu.

Ọpọ awọn ọdọ yii ni wọn n ṣe ifẹhonuhan fun igba akọkọ.

Nibi ti awọn kan ninu wọn ti n sọ pe "ẹ ma fi ipa gba owo ori lọwọ wa" l'awọn mii n sọ pe "Ruto gbọdọ lọ."

Aworan awon odo Kenya

Oríṣun àwòrán, AFP

Naserian Kasura to jẹ okan lara awọn olufẹhonuhan yii ni "igba akọkọ ti mo maa kopa ninu ifẹhonuhan niyi.

Mo ni igbagbọ pe nnkan maa yipada lẹyin iwọde yii."

Kasura koro oju si erongba ijọba lati gbe owo ori lori paadi t'awọn obinrin n lo fun nnkan oṣu.

Ẹwẹ, awọn ọlọpaa dina mawọn ọdọ naa lati gbe iwọde wọn lọ si ile igbimọ aṣofin.

O kere tan, igba awọn oluwọde yii l'awọn ọlọpaa fọwọ ofin mu, bo tilẹ jẹ pe pupọ ninu wọn pada gba ominira.

Aworan awon odo Kenya

Oríṣun àwòrán, Reuters

Koda, awọn ti ko le lọ sibi ti wọn ti n ṣe ifẹhonuhan ọhun n pin ọrọ atẹjiṣẹ, fọto ati fidio kaakiri ori ayelujara.

Iwọde yii yatọ si awọn iwọde to ti waye sẹyin eyi ti ọpọ awọn eeyan maa n lo ifehonuhan lati jale ati lati ba dukia jẹ.

Amọ, ko si ohun to jọ bẹẹ pẹlu iwọde tọtẹ yii.

Ifẹhonuhan yii ko ni nnkan kan ṣe pẹlu awọn oloṣelu tabi ẹya kankan.

Ijọba Kenya gbọ sawọn oluwọde lẹnu

Lẹyin ọpọ wakati ti iwọde yii waye, ni ileeṣẹ aarẹ Kenya kede pe oun yoo fagile diẹ lara awọn aba lati ṣe afikun owo ori to fi mọ 16% owo ori VAT lori burẹdi.

Kuria Kimani to jẹ alaga ile igbimọ aṣofin lori eto inawo sọ pe ijọba ti gbọ ohun tawọn eeyan Kenya n sọ.

Ijọba ti kọkọ sọ pe oun kede afikun owo ori lọ si $2.7bn ki adinku le ba bi ijọba ṣe n ya owo.

Awọn owo ori mii ti ijọba ti wọgile erongba rẹ lati ṣe afikun wọn ni owo ori lori epo isebẹ, owo ori lori gbigba owo lori foonu