Níbo ni Emir Ado Bayero fẹ́ kó lọ báyìí tí ìjọba Kano ní kó kúró láàfin, àwọn fẹ́ wó o fún àtúnṣe?

Oríṣun àwòrán, Kano state Government
Lẹyin agbekalẹ idajọ ile ẹjọ giga ti ijọba apapọ to waye lọjọbọ, nibi ti wọn ti kọyinsi alakalẹ ofin to nii ṣe pẹlu ọrọ Emir tilu Kano.
Ijọba ipinlẹ kano ti paṣẹ pe ki, Aminu Ado Bayero, Emir ti wọn yẹ aga ipo mọ nidi lati kuro laafin kekere to wa nilu Nassarawa lẹyẹ ọ ṣọka.
Nibi ipade awọn oniroyin kan ni adajọ agba ni ipinlẹ Kano, Haruna Isah Dederi ti salaye pe eredi asẹ ọun ni lati ṣe atunṣe Aafin naa, o tun tọka sii pe ijọba ipinlẹ ọhun lo ni dukia naa.
Adajọ agba ọun ṣalaye wipe, ile ẹjọ giga ti ipinlẹ Kano ti fidi ọrọ mulẹ pe, Muhammmad Sanusi ni ojulowo Emir tilu naa, o sọ pe Ado Bayero ti n tasẹ agẹrẹ nipa bo ṣe n duro ni Aafin kekere tilu Nassarawa naa.

Oríṣun àwòrán, Abba Kabir Yusuf
Tẹẹ ba gbagbe pe lọjọ kẹẹdọgbọn oṣu karun un ọdun 2024, ni Gomina Abba Kabir Yusuf ti ipinlẹ kano pasẹ ki wọn lọ fi pampẹ ọba gbe Ado Bayero fun ẹsun dida pakaleke silẹ laarin ilu lori ọrọ to nii se pẹlu iyọnipo rẹ .
Ẹwẹ, awọn oṣiṣẹ ologun ati awọn agbofinro miran dena igbesẹ ọhun nipa bi wọn ti duro wamu wamu lẹnu ọna abawọle Aafin kekere towa ni ilu Nassarawa naa, ti wọn ko lee ṣe ojuṣe wọn gẹgẹbi Gomina Abba Kabir Yusuf ti paṣẹ.

Oríṣun àwòrán, Facebook/sanusilamidoofficia
Ile ẹjọ giga to n jokoo nipinlẹ Kano ti wọgile ofin ti wọn fi yọ Aminu Ado Bayero gẹgẹ bii Emir ati awọn Emir mẹrin yooku kuro lori oye ati igbesẹ iyansipo Muhammadu Sanusi II gẹgẹ Emir ti Kano.
Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Onidajọ Abdullahi Muhammed Liman ni igbesẹ ti ijọba ipinlẹ gbe lati yọ Emir ni ko ba ofin mu.
Adajọ Liman palaṣẹ fun ijọba Kano pe ki wọn ma se yabara kuro loju ọna ofin.
Adajọ ni ile ẹjọ ṣetan lati lo gbogbo agbara rẹ lati ri pe awọn eeyan ti ọrọ kan tẹle aṣẹ ile ẹjọ.
O ni awọn olujẹjọ mọ ohun ti ofin wi ati aṣẹ ti ile ẹjọ gbe kalẹ sugbọn wọn kọ lati tẹle aṣẹ ile ẹjọ, ti wọn sure lọ se atunṣe si ofin.
Bakan naa ni Ile ẹjọ tun wọgile iyọnipo awọn ori ade mẹrin, Bichi, Rano, Karaye ati Gaya ti wọn yọ nipo pẹlu Emir Aminu Ado Bayero.
Ewẹ, Adajọ ti gbe ẹjọ naa lọ siwaju Adajọ Simon Amobeda lati tẹsiwaju igbẹjọ naa.
Saaju ni Ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Kano se atunse si ofin oba jijẹ eyi ti Gomina Abba Kabir Yusuf buwọlu, ti wọn si fi yọ Alhaji Aminu Aso Bayero gẹgẹ bii Emir Kano.
Gomina ipinlẹ Kano, Abba Yusuf lo da Emir ilu Kano tẹlẹ, Sanusi Muhammadu, pada sori itẹ rẹ gẹgẹ bii Emir Kano lẹyin ti wọn se atunṣe si ofin naa.
Lọjọ Ẹti, ọjọ kẹrinlelogun, ọdun 2024 ni gomina Abba Yusuf fun Sanusi ni lẹta idapadasipo rẹ ọhun.
Ẹwẹ, saaju igbesẹ Gomina ni Ile ẹjọ giga ijọba apapọ niluu Kano ti paṣẹ idaduro ofin ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa to tu ẹkun lọbalọba ipinlẹ Kano ka.
Ti ẹ o ba gbagbe, ijọba gomina ana ipinlẹ Kwara, Abdullahi Ganduje lo ṣe agbekalẹ ẹkun lọbalọba marun un ipinlẹ Kano yii lẹyin to rọ Lamido Sanusi loye gẹgẹ bi Emir ilu Kano lọdun 2019.
Ni Ọjọbọ ọjọ kẹtalelogun oṣu Karun un yii ni ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Kano tu ẹkun lọbalọba marun un naa ka ti gomina Abba Kabir Yusuf si kede ipadabọ sipo Sanusi gẹgẹ bi Emir ilu Kano.
Lórí ipò Emir Kano, Ilé ẹjọ́ yóò gbé ìdájọ́ kalẹ̀ fún Sanusi àti Aminu Ado Bayero lónìí

Oríṣun àwòrán, BLOCK OWNER/FACEBOOK
Ile ẹjọ giga to n jokoo niluu Kano ni ireti wa pe yoo gbe idajọ lori ọrọ Ọba jijẹ ati ilana ofin 2024.
Bakan naa ni ile ẹjọ yoo tan imọlẹ si awọn ori ade marun un, Kano, Rano, Karaye, Gaya ati Bichi ti wọn yọ nipo laipẹ yii.
Bẹẹ ba gbagbe ninu oṣu kanrun un ọdun 2024 ni Ijọba ipinlẹ Kano gbe ofin kalẹ pe ki ori ade ti rọ lole lasiko ijọba to kogba wọle pada sipo gẹgẹ Emir Kano, ti Gomina Abba Kabiru Yusuf si buwọlu ife ofin naa.
Gẹgẹ bii ofin ṣe sọ, Gomina wọgile iyansipo awọn ori ade to fi mọ ti Emir Kano, Alhaji Aminu Ado Bayero, to kede Muhammadu Sanusi gẹgẹ bii Emir lẹyin ti Gomina ana, Abdullahi Umar Ganduje yọ nipo lọdun 2020.
Lọjọ Kẹtalelogun oṣu karun un, ọkan lara awọn oloye Emir Kano, Alhaji Aminu Babba Son, to jẹ Emir fun Dawaki Babba morile ile ẹjọ giga niluu Kano, to si n pe fun pe ki ile ẹjọ wọgile ofin tuntun nipa iyansipo Ọba.
Lẹyin to gbọ atotonu lẹnu awọn olupẹjọ, adajọ Abdullahi Liman sun igbẹjọ si Ọjọbọ, ogunjọ oṣu kẹfa ọdun 2024.
Oba meji ni Kano
Fun bi oṣu meji bayii ni ija ti bẹ silẹ laarin Alhaji Aminu Ado Bayero, ẹni ti Gomina ana nipinlẹ Kano yan sipo gẹgẹ bii Emir ati Muhammadu Sanusi ii ẹni ti Gomina Abba Kabiru Yusuf dapada si ori itẹ lẹyin ọdun mẹrin.
Lati igba naa ni awọn mejeeji ti n pe ara wọn ni Emir, ti wọn si n se ojuṣe Emir ni ile ọtọtọ.
Nigba ti Muhammadu Sanusi II n se tirẹ ni ile Dabo, Aminu Ado n se tirẹ ni ile Ọba Nasarawa nibi ti aafin rẹ wa.
Ki ni Ileeṣẹ ọlọpaa sọ?
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kano ti jẹ ko di mimọ fun awọn araalu pe awọn ko ni fi aye gba rogbodiyan lati ọwọ ẹnikẹni.
Bakan ni Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ọmọ ogun ti wa kaakiri lati ri pe alaafia wa ni gbogbo agbegbe Kano.
Wọn ṣekilọ dun gbogbo awọn eeyan to ni erongba buburu lati da wahala silẹ nipinlẹ Kano pe ki wọn tọwọ ọmọ wọn bọ aṣọ.















