Olúwòó ṣí orí adé sílẹ̀ ní Meka ariwo sọ, àwọn èèwọ̀ tí ọba alaye kò gbọdọ̀ ṣe nílẹ̀ẹ Yorùbá rèé

Aworan Oluwoo ilu Iwo, Ọba Adewale Akanbi to ṣi ori silẹ ni Meka

Oríṣun àwòrán, oluwo/screenshot

Bo ṣe jẹ pe ọpọ igba ni awọn eeyan maa n ri nnkan sọ nipa Oluwoo ile Iwo, Ọba Abdulrasheed Adewale Akanbi, bẹẹ naa ni ariwo tun gbode nipa Kabiyesi naa laipẹ yii, pẹlu bo ṣe ṣi ori ade silẹ niluu Saudi Arabia, lasiko to n ṣe iṣe Haji lọwọ.

Loooto lo jẹ pe iṣẹ Haji ko kan ti pe eeyan jẹ ọba, olowo tabi ọlọrọ, to si tun jẹ pe aaye ti wọn ti n ṣiṣẹ ijọsin naa ko gba ki ọkunrin de fila, bo ti wu ki ẹni ọhun niyi to nibi to ti wa.

Eyi lo fi jẹ pe awọn eeyan to n bu ẹnu atẹ lu Oluwoo ko tori ai-de fila binu, ohun ti wọn n sọ gan-an ni pe ki ni Oluwoo tun gbe ori ọhun si gbagede aye fun, to n jẹ ki gbogbo aye ri i lori ayelujara.

Awọn eeyan n sọ pe ibi gẹrẹjẹ la a ba’gba, Yoruba ki i si fi ori ade wọlẹ nibikibi, ka ma ti i sọ ni gbogbo aye.

Wọn ni Oluwoo wulẹ fẹran ko maa ṣe nnkan tiẹ lọna to tako ori apeere ọba to jokoo si ni, o fẹran ko maa fi Yoruba wọlẹ lawujọ.

Bo tilẹ jẹ pe Oluwoo funra rẹ naa ti fesi si ọrọ yii, pe Ọba to ju awọn ọba aye lọ loun ṣi ori oun kalẹ fun, sibẹ, awọn eeyan n sọ pe eewọ lohun to ṣe.

Ọrọ Oluwoo to n ja ran-in yii lo mu BBC Yoruba tọ awọn agba to nimọ nipa eewọ ilẹ Yoruba ti ọba ko gbọdọ ṣe lọ.

Awiṣẹ ilu Oṣogbo, Oloye Ifayẹmi Ẹlẹbuibọn, ṣalaye iwa Kabiyesi Akanbi Oluwoo, eewọ ọba ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Bakan naa ni Oluọmo, Dokita oniṣegun oyinbo Oluṣeyi Atanda, Aarẹ awọn ẹlẹsin ibilẹ niluu Oṣogbo to tun jẹ Ajana Awo Oṣogbo naa tan imọlẹ si ọrọ naa bayii pe:

Ìwà Olúwòó kò gbọdọ̀ jọ èèyàn lójú mọ́, iṣẹ́ owó tó ń gbà lọ́wọ́ọ Saudi ló ń ṣe- Olóyè Ifayẹmi Ẹlẹbuibọn

Oloye Ifayemi Elebuibon

Oríṣun àwòrán, Others

Ninu ọrọ Awiṣe ilu Oṣogbo, Oloye ifayẹmi Ẹlẹbuibọn, baba sọ pe, ‘’Lara awọn eewọ ti ọba alaye o gbọdọ ṣe ni pe ko gbọdọ ṣi ori silẹ ni gbangba.

Nitori ẹ ni ọba ṣe maa n ni fila ti wọn n pe ni ‘ori o gbofo’. Fila kan pẹẹki abi ade pẹẹki.

Atari ọba naa ni wọn ti n mọ ẹni ti yoo jọba laye ọjọun.

Ni ti Oluwoo, gbogbo awọn iwa ti Oluwoo n hu lo fi n tapa si aṣa ati iṣe Yoruba.

O si n mọ-ọn-mọ ṣe e ni, nitori owo to n gba lọwọ awọn ara ilẹ Saudi, o gbọdọ maa fi han pe oun n ṣiṣẹ owo ti wọn n fun oun. Ohun ni gbogbo nnkan to n ṣe yẹn.

Ko yẹ ki ọrọ Oluwoo jọ wa loju mọ. Ko si nnkan kan to le ṣe, ko si iwa kan ti Oluwoo le hu ti eeyan le jẹ ko ya oun lẹnu, nitori o ti fi han, o si ti sọ ibi ti oun n lọ.

Ọrọ rẹ ki i ṣe tuntun mọ.

Oba Adewale Akanbi, Oluwoo ti ilu Iwo

Oríṣun àwòrán, Oluwoo @Instagram

Àwọn èèwọ̀ míì tí ọba alayé ò gbọdọ̀ ṣe?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Oloye Ẹlẹbuibọn ṣalaye pe, ‘’ọba ko gbọdọ jẹun nita, wọn o gbọdọ maa ri ẹnu ọba nita gbangba.

‘’Ọba ki i jade fotifoti bayii laye atijọ. O loju ode ti ọba gbọdọ lọ.

’’Ọba ki i jade lojoojumọ, ẹẹkan la maa n ri ọba lọdun nigba mi-in, ti wọn ba fẹẹ ṣe ọdun ibilẹ to kan ilu lọba maa n jade.

Ẹni ni ti ko ri ọba ri yoo ri i, ẹni ti wọn ko ti i bi nigba ti ọba jẹ, yoo ri ọba. Iyẹn ni wọn fi maa n sọ pe ma a tun ri ẹ lẹẹmi-in.

Ṣugbọn awọn tisinyi ro pe wọn n de awọn mọle ni.

‘’Ọlaju, ẹsin lo n da aṣa Yoruba ru, awọn oloṣelu lo ṣikẹta, awọn ni wọn tun waa gbe ọba yilẹẹlẹ, to fi jẹ pe awọn ọba wa ti di afuyẹ, wọn ki i ṣe alaṣẹ mọ, wọn ki i ṣe ẹrujẹjẹ adugbo mọ.

‘’Ẹrujẹjẹ, o-rin-kilẹ-o mi-titi, oro-n-ro, ọba ti i ro obinrin ẹ laṣọ, ọwọwọ ti i wọ talika lẹwu, o sunmọ-silẹ-sunmọ sẹni, o kunmọ losun-kunmọ lata.’’ Orukọ awọn ọba wa niyẹn tẹlẹ.

Nisinyi, ohun to wu awọn ọba wa ni wọn n ṣe, nigba ti wọn o tiẹ mọ ọ.

Ọba gbọdọ gbọ ilu.

Laye atijọ, awọn onilu lo maa n jẹ ki ọba mọ bi wahala ba fẹẹ ṣẹlẹ lagbo, wọn aa maa filu sọ fun un pe ile too lọ.

Ṣugbọn ọba ti ko gbọlu, bawo lo ṣe fẹẹ mọ pe ewu n bẹ. Omi-in ko wọ ipebi pari oro.

‘’O yẹ k’ọba mọ bi wọn ṣe n gbe ẹsẹ ijo, ko mọ ọwọ ti wọn n fi irukẹrẹ si, ko mọ oriki ati itan ilu rẹ nipa awọn ẹni iṣiwaju.

Ṣugbọn awọn tasiko yii fẹẹ maa yi oju aṣa ati itan Yoruba po, wọn fẹẹ maa dori aṣa kodo, ohun to n ṣẹlẹ n’Iwoo niyẹn, ko yẹ ko jọ wa loju.

Ko si ọba nilẹ Iwo, Raṣidi n dele laafin ni - Àjànà Awo Osogbo

Aworan Ajana Awo Osogbo, Dokita Oluseyi Atanda

Oríṣun àwòrán, BBC

Ajana Awo Oṣogbo, Dokita oniṣegun oyinbo, Oluṣeyi Atanda to tun jẹ Aarẹ awọn ẹlẹsin ibilẹ nipinlẹ Osun, sọ pe,

‘’Akọkọ, ọba yatọ si ọba. Ẹlomi-in wa ti awa n ro pe ọba ni, ṣugbọn ni aaye ara rẹ, oun naa mọ pe oun ki i ṣe ọba, nitori teeyan ko ba ṣe ohun to yẹ ko ṣe ti yoo fi maa jẹ ọba, ẹnu lasan lo fi n jẹ ọba.

‘’Ni ọdọ awa ajọ ẹlẹsin ibilẹ Ọṣun, ko si ọba nilẹ Iwo. A ti sọ ọ,ki i ṣe ana, ki i ṣe ijẹta. Oluwoo funra ẹ naa ti sọ ọ pe oun ki i ṣe ọba, o ni Emir loun.

‘’Rasidi n dele laafin ni, ko si ọba n’Iwoo. Fun idi eyi, gbogbo ohun to ba n ṣe, ko maa ṣe e.

‘’Ifa ni bi ọmọde kan n jẹ eewọ, bẹnikan o bi i, bo pẹ titi, ohun to n bi ni aa maa bi ni. Adifa fun ẹni ti baba rẹ o ku ti yoo jogun iya rẹ, ẹ ju u silẹ, eewọ aa si maa beere, eewọ o beere dandan ni.

‘’Ṣugbọn nigba ti yoo ba beere, ko ma dohun ti yoo kan ara ile, kan ara oko ni atototonu ti a n ṣe, nitori yoo kan awọn araale rẹ, o ṣee ṣe ki iran rẹ ma le de ori apeere mọ.

‘’Lorii pe o wa ṣi ori silẹ, ka ni pe ọba alade ni, to jẹ ọba gangan, ti ki i ṣe ade pafuẹlẹ, nitori Oluwoo yii ko de ade iṣẹmbaye Iwo, o mọ pe oun o ri ori gbe e.

‘’Emi ti sọ ọ bii ọdun meji mẹta sẹyin, pe to ba to bẹẹ, ko de ade iṣẹmbaye Iwo, ki emi ati ẹ waa jọ pade, ka waa wo ohun ti yoo ṣẹlẹ, boya yoo ri aafin yẹn wọ pada abi nnkan mi-in yoo ti ẹyin rẹ jade.

‘’Ade pafuẹlẹ ti Oluwoo de, ti awọn asindẹ ṣe yatọ si ti Iṣẹmabaye o. Ọba ilẹ Yoruba to mọ pe ori oun ti di ori apẹsin ko gbọdọ ṣi i silẹ, eewọ ni, to ba ṣi i, ọ̀hun ni. Ohun to si n beere yoo maa beere.

Wọn ni bi ọmọde kan ba bu iroko to boju wẹyin, oojo kọ ni Oluwere n pa ni. Ẹ jẹ ka maa wo o lọ. Aja ti yoo sọnu ko ni i gbọ fere ọdẹ.

Aworan Emir ilu Sokoto ati Oluwoo

Oríṣun àwòrán, Oluwoo @Instagram

Ǹjẹ́ gbogbo aráàlú ni yóò fara gbá ìjìyà èèwọ̀ tí ọba dánwò?

Nigba to n dahun eyi, Ajana Awo Oṣogbo sọ pe, ‘’Ko ma baa di ohun ti yoo kan araalu naa lo jẹ kawọn awo maa ṣetutu.

‘’Awọn awo ko dakẹ lori ọrọ rẹ rara, ko ma baa dohun ti yoo kan gbogbo ilu.

‘’Imọran tiwa kan ni pe kijọba atawọn ọmọ iya wa n’Iwoo kiyesara, ko ma jẹ pe Rasidi ni yoo gbabọde fun ilẹ Yoruba.

‘’O ti n ba wọn ṣe nilẹ Hausa nisinyi, o tun ti n ba wọn ṣe ni Saudi. Ko ma lọọ jẹ ohun to ṣẹlẹ ogun Alimi ọjọsi ana ati ti Boko Haram nilẹ Yoruba lo n gunle.

‘’Oni kọ lawọn ọba alaye ti n ṣiṣẹ haji ti wọn n ṣi ori silẹ, ṣugbọn wọn n fi ọgbọn si i, wọn ki i gbe sori ayelujara.Ṣe ẹ mọ pee eeyan le ṣe nnkan eewọ kaye ma mọ, bi iya rẹ yoo tiẹ jẹ ẹ, yoo mọ niba. Ṣugbọn ẹni to ṣe nnkan eewọ to gbe e sita, to tun waa dẹjaa, o n sọ pe ko si eewọ ni.

‘’A n sọ pe ọba ki i ṣi ori silẹ, ṣe ọba ki i ṣi ori silẹ ninu ile rẹ ni. Ọba ki i jẹun nita gbangba, ṣe ọba ki i jẹun ninu ile rẹ ni.

Bi ọba ati eeyan meji m-eta ba wa papọ, ọba yoo ṣaa jẹun, ṣugbọn ki i ṣe pe ni ojutaye ni nnkan ti a n sọ.

‘’Ọba to ba ti n ṣe ohun to lodi sohun ti ohun ti wọn fi tẹlu rẹ do, nnkan yẹn yoo maa bi i. Ẹ maa ri ọba mi-in ti yoo kan deede fo ṣanlẹ, iyawo ni ẹlomi-in fi n di i, awọn nnkan yẹn ko deede ṣẹlẹ, ohun ti wọn n fọwọ ara wọn fa ni.

Eṣinṣin ò gbọdọ̀ kun orí ọba kó tún bà lé orí ẹlòmíràn Ọrangun Ìlá

Ọba Abdul Wahab Olukayode Oyedotun Bibiire I, Ọrangun ti ilu Ìlá, nipinlẹ Ọṣun naa sọrọ lori eewọ ọba pe,

‘’Ti ẹ ba de aafin ọba mi-in, ẹ maa ba ọba to ṣi ori silẹ, awọn araalu aa maa wo ori rẹ. Eewọ ni nilẹ Yoruba.

‘’Idi ni pe bi ọba ba ṣi ori silẹ nita gbangba, ti eṣinṣin ba fọwọ kan ori ọba, to tun lọọ fi kan ẹlomi-in, oriburuku ti ba ẹniyẹn.

‘’Nitori ọba ki i ṣe eeyan lasan.

‘’Ọba n jẹun lọwọ, iwọ naa gba a, o n jẹ ẹ. Ta lo bi ọ, eewọ ni.

‘’Ọpọ nnkan lọba n ṣe kilẹ too mọ, ipo ọwọ nipo ọba.

‘’Wọn maa n sọ ọ, pe bi wọn ba bi ọba niluu kan, lọjọ yẹn, wọn o ni i bi ọkunrin kankan mọ.

‘’Ki lẹ n fọba pe, ẹni to ba foju d’ọba, awowo aa wo o.’’