Báwo làwọn ìjọba ìpínlẹ̀ ṣe lè dẹ́kun àìsàn kọ́lẹ́rà ní Nàìjíríà, àwọn onímọ̀ sọ̀rọ̀

Oríṣun àwòrán, WHO
Ọgbọn eeyan lo ti padanu ẹmi wọn sọwọ aarun onigba meji lorilẹede Naijiria bayii, ọna si wa lati fopin aarun yii ni agbegbe wa.
Orisirisi nnkan lo le sokunfa aarun onigba meji sugbọn eyi to le ke n ka ju ni ai si imọ toto.
BBC ba onimọ iṣegun kan sọrọ lori ohun to yẹ ki ijọba apapọ ati ipinlẹ gunle lati fopin si itankalẹ Aarun naa lorilẹede Naijiria.
Dokita Ismail Abayomi ṣalaye pe ohun pataki to yẹ ki ijọba mujuto ni akoko ni pi pese eto ẹkọ nipa aarun yii fun araalu.
O ni o ṣe koko ki awọn araalu mọ ọna ti wọn fi le lugbadi aarun yii ati ọna ti wọn le gba yago fun.
“Aarun onigba meji buru gan, sugbọn a le yago fun ti awọn araalu ba le yago fun.
“Mo mọ pe ijọba ti n gbe ọpọlọpọ igbesẹ sugbọn a si ni nilo ọpọlọpọ ẹkọ nipa aarun onigba meji ati ọna ti le fi yago.
“Ijọba nilo lati pe akiyesi awọn araalu lori ohun to yẹ ki wọn ṣe lati yago fun aarun yii.
“Asiko ojo ni wa yii, ọkan lara ipenija ti a ni bayii ni ọpọlọpọ awọn ibi ti omi n gba kọja lo di, to si n fa idọti, ijọba ba le pese iranlọwọ fun araalu lati se imọtoto awọn ibi ti omi gba kọja, yoo se ọpọlọpọ anfani lati gbe ogun ti itankalẹ yii.
Abayomi tẹsiwaju pe o ṣe koko ki ijọba bẹrẹ si na ma ṣe idanilẹkọ fun awọn eeyan to n ta ounjẹ lati ma fi omi to mọ pese ounjẹ fun awọn onibara wọn.
O ni ọni miiran ti eeyan ti le lugbadi aarun onigba meji ni jijẹ ti ko mọ tabi ti wọn ko fi omi to mọ pelo rẹ fun jijẹ.
“Ijọba ni mojuto awọn to n ta ounjẹ fun araalu pe wọn pese ọna wọn ni ilana to ni imọtoto.
“Ti ba a le se gbogbo awọn nnkan yii, o seese ki a fofin si aarun onigba meji lorilẹede Naijiria,’
Ki lawọn igbesẹ ti Ijọba Eko ti gbe ni tirẹ lati dẹkun ọwọja aisan onigba meji yii?
Kọmisọna fun eto ilera nipinlẹ Eko, Dokita Akin Abayomi ti kesi awọn araalu pe ki bẹrẹ sọ awọn nnkan ti wọn n ti bọ ẹnu wọn lasiko yii nitori itankalẹ aarun onigba meji to gbode.
Abayomi ni ijọba Ẹkọ ti gbọ ọpọlọpọ iroyin nipa aarun yii laarin wakati mejidinlaadọta.
Aarun onigba meji lo maa n mu eeyan nipasẹ ounjé tabi omi ẹlẹgbin, to si maa n fa igbọnsẹ gbuuru, eebi ati ki omi ara gbẹ pata.
Ajọ NCDC to n ri si didena arun sọ pe arun onigba-meji yii ti de ipinlẹ ọgbọn (30) ninu ipinlẹ mẹrindinlogoji (Ẹ sura fun aarun onigba meji- Ijọba Eko ṣe ikilọ fun araalu36) ti Naijiria ni.
“A ti pese iranlọwọ kaakiri. Ẹka eto ilera nipinlẹ Eko, ati Ẹka to n risi ayika nipinlẹ Eko pe ki wọn bẹrẹ iwadii awọn ohun to le sokunfa aarun naa.”















