Báwo ni Ellon Musk tún ṣe ṣeé láti tún gba $56 bílíọ̀nù lọ́wọ́ Tesla mọ́ owó tabua tó ní

Aworan Elon Musk

Oríṣun àwòrán, Reuters

Awọn olokowo ileeṣẹ Tesla ti ṣatilẹyin fun ọga ileeṣẹ naa, Elon Musk, lori sisan $56bn fun un.

Bakan naa ni wọn tun buwọlu igbesẹ lati gbe olu ileeṣẹ naa to n ri si ọrọ ofin lọ si Texas ni Amẹrika.

Ṣaaju ninu ọdun yii ni adajọ kan ni Delaware tako aba yii, lẹyin to kọminu pe igbesẹ naa ko dara fawọn olokowo.

Musk ti beere fun eleyii tẹlẹ wi pe ki wọn san $56bn foun.

Owo yii ju gbogbo owo ti Musk ri lọdun to lọ ni ọna odunrun un, o ṣi tun ju iye tawọn olori ileeṣẹ nla nla maa n gba lọ lọna bi ẹgbẹrun mẹta.

Amọ ṣa, ayipada si le ba igbesẹ yii, lẹyin t'awọn onimọ nipa ofin sọ pe ileẹjọ to dajọ tako sisan owo gọbọi yii fun Ọgbẹni Musk ṣi tun le tako b'awọn olokowo tun ṣe dibo lati buwọlu sisan owo ọhun.

Onimọ nipa ofin kan, Mathieu Shapiro, sọ pe igbesẹ awọn olokowo yii le maa nipa kankan.

Ọpọ lo ti tako bawọn alaṣẹ Tesla ṣe gba lati san owo tabua yii fun Ọgbẹni Musk.

Adajọ Kathaleen McCormick dajọ ninu oṣu Kinni ọdun 2024 pe owo ti wọn fẹ san Musk ọhun ti pọju, ati pe ọna aitọ ni wọn fẹ gba sanwo ọhun fun un.

Adajọ tun sọ pe Antonio Gracias to jẹ adari igbimọ alasẹ ileeṣẹ Tesla ni ibasepọ to dan mọran pẹlu Musk debi wi pe ni gbogbo igba lo maa n rinrin ajo igbafẹ pẹlu ẹbi Musk.

Lẹyin ti igbẹjọ waye tan ni Daleware ni Musk kede pe oun fẹ gbe olu ileeṣẹ ẹka to n ri si ọrọ ofin nile iṣẹ Tesla lọ si Texas.

Ọrọ ti pọ lori igbesẹ yii eyi to ti jẹ ki ọpọ bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu iṣedari Musk, papaa julọ lasiko ti okowo Tesla ti lọọlẹ bayii.

Amọ, Musk b'awọn olokowo to ni ibasepọ to dara pẹlu wọn sọrọ lati gba igbesẹ naa wọle.

Lẹyin o rẹyin, awọn olokowo to buwọlu aba lati sanwo yii fun Musk ju awon to tako aba ọhun lọ.

Owo tawọn olokowo yii gba lati san fun Musk ti jẹ ko ni ida mẹwaa okowo Tesla.

Njẹ Elon Musk gbewọn to $56bn ti Tesla fẹ san fun un?

Ileeṣẹ Tesla sọ pe afojusun Elon Musk ni awọn ipenija kan.

Amọ, igbẹjọ to waye nile ẹjọ Delaware fidi rẹ mulẹ pe nkan kan naa ni afojusun Musk ati eto idagbasoke Tesla ti ileeṣẹ naa pin pẹlu awọn banki.

Onimọ nipa ọkọ kan, Karl Brauer, ni ohun toun mọ nipa ọrọ aje Tesla ni pe o ti gberu sii daadaa.

Ṣugbọn o ni ọpọ awọn olori ileeṣẹ nla nla kii huwa bayii.

Ogagba ileeṣẹ Tesla tẹlẹ ri lẹkun iwọ oorun Yuroopu, George EII, sọ fun BBC pe ti oun ba jẹ olokowo ni Tesla to ti dokowo pẹlu owo nla lati ọdun 2018 ti akoko yii, idunnu lo maa jẹ foun tori oun yoo ti jere gọbọi lori idokowo oun.

Aworan bi owo Ellon Musk ṣe pọ si.

Ẹwẹ, igbimọ alasẹ Tesla ti sọ pe owo tawọn fẹ san fun Ọgbẹni Musk tọ si i.

Wọn ni gbogbo ileri ti o ṣe ni o ti musẹ.

Awọn abẹnugan ni ileeṣẹ Tesla naa ṣatilẹyin fun Musk loju opo ayelujara wọn.

Wọn ni o ṣiṣẹ fun ilọsiwaju ati aṣeyọri Tesla.

Elon Musk ti wa ṣeleri lati mawọn olokowo to dibo kaakiri ẹka ileeṣẹ Tesla to wa ni Texas.