Kí ló wà nínú ìpàdé Putin, ààrẹ Russia àti adarí North Korea to ń fọ́ àwọn orílẹ̀èdè alágbara àgbáyé lórí?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aarẹ Vladimir Putin orilẹede Russia ti balẹ si ilu Pyongyang ti i ṣe olu ilu orilẹede North Korea fun àbẹwò rẹ si ilẹ naa.
Ileeṣẹ ijọba Russia, Kremlin lo fidi rẹ mulẹ pe Aarẹ Putin ti de si North Korea.
Ni oru ọjọ Iṣẹgun ni Putin balẹ si ilu Pyongyang fun igba akọkọ ni bii ọdun mẹrinlelogun.
Lara awọn to kọwọọ rin pẹlu Aarẹ Putin ni minisita eto aabo, Andrei Belousov, minisita ọrọ ile okeere, Sergei Lavrov ati awọn adari ajọ to n ri si ọrọ oju ọrun lorilẹede Russia.
O ṣeeṣe ki awọn olori orilẹede mejeeji lo abẹwo yii lati jẹ ki ibaṣepọ wọn tun dan mọran si.
Oludamọran si aarẹ Putin lori eto iṣejọba, Yuri Ushakov, sọ pe o ṣeeṣe ki wọn tun sọrọ nipa ibaṣepọ wọn lori eto abo.
Baalu agberapa awọn ọmogun tẹle Putin lọ si ila oorun ilu Yakutsk lọjọ Ìṣẹgun.
Igba akọkọ ree ti iroyin yoo gbe e jade pe baalu agberapa ọmogun yoo tẹle Aarẹ Putin rinrin ajo laarin Russia.
Tẹlẹ, awọn ẹṣọ ologun nikan lo maa n tẹle Putin lọ silẹ okeere.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Idi abẹwo Putin si North Korea ree
Oriṣiiriṣii ahesọ ọrọ lo ti tan kalẹ lori ayelujara lori abẹwo Putin si North Korea.
Amọ, o dabi ẹni pe ọrọ abo ni abẹwo rẹ da lori.
Sergei Markov to jẹ onimọ nipa eto oṣelu ati oludamọran aarẹ Russia sọ pe abẹwo Putin le da lori wiwa nnkan ija oloro, wiwa awọn oṣiṣẹ to fi mọ awọn to le fi ara wọn silẹ lati lọ koju Ukraine ninu ogun to n lọ lọwọ.
Bakan naa, Pyongyang naa le ri iranwọ gba lọwọ Russia lori ileeṣẹ ologun wọn.
Russia ni ajọṣepọ to ti pẹ pẹlu North Korea ti wọn jọ paala.
Koda, ijọba USSR gan an ṣe iranwọ fun idasilẹ orilẹede North Korea lẹyin ogun Korea ni nnkan bi ọdun 1950.
Lẹyin ti USSR wo lulẹ tan, Russia si wa lara awọn orilẹ-ede to ni ibasepọ to dan mọran pẹlu North Korea.
Bo tilẹ jẹ pe ibaṣepọ yii ko dabi ti aye igba USSR, o ti di ajọṣepọ to ni anfani ninu fun orilẹede mejeeji.
Igba keji ree ti Putin yoo ṣe abẹwo si North Korea lati igba to ti di aarẹ orilẹede Russia.
Ni ọdun mẹrindinlogun sẹyin ni Putin ṣabẹwo si Kim Jong Un to jẹ baba Kim Jong Keji.
Amọ, lori abẹwo yii, ileeṣẹ aarẹ Kremlin ni Russia ati North Korea n wa ọna ti ibaṣepọ to jinlẹ yoo fi wa laarin awọn mejeeji.
Kilode ti abẹwo Putin ṣe n kọ awọn adari agbaọjẹ orilẹede iwọ oorun agbaye lominu?
Ibasepo to n lọ lọwọ laarin ilu Moscow ati Pyongyang n kọ orilẹede Amerika at'awọn agbaọjẹ orilẹede iwọ oorun lagbaaye kan lominu.
Nipa abẹwo rẹ si North Korea, Putin le maa paroko fawọn ọta rẹ pe o le ṣe ohun to fẹ.
Abẹwo rẹ tun le tumọ si pe Putin le bọ lọwọ awọn ijiya t'awọn orilẹ-ede alagbara kede pe awọn o fi jẹ Russia.
O tun le lo abẹwo rẹ lati ta nnkan ija oloro ti Russia ṣe.
Putin tun le lo abẹwo rẹ lati ni ibasepọ pẹlu awọn orilẹ-ede agbaye mii.
Ileeṣẹ ijọba Russia ni Moscow sọ pe Putin yoo tun rinrin ajo lọ si Vietnam ti o ba ṣetan ni North Korea.















