Ohun táa mọ̀ nípa rògbòdìyàn tó bẹ́ sílẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ Rivers rèé

Oríṣun àwòrán, RIVERS STATE GOVERNMENT PRESS
Eeyan meji ti padanu ẹmi wọn nipinlẹ Rivers nigba ti awọn ọdọ kan yawọ awọn ọfisi ijọba ibilẹ nipinlẹ naa.
Lonii, Gomina Siminialayi Fubara kede sita ki awọn alaga kansu juwọ agbara wọn, to si bura fun awọn alaga tun tun.
Ọlọpaa wa lara eeyan meji ti wọn ṣekupa ni agbegbe Eberi Omumu nijọba ibilẹ Omuma lasiko ti ija bẹ silẹ laarin awọn ọdọ ni agbegbe naa..
Lati le fopin si rogbodiyan naa, Ileeṣẹ ọlọpaa kede sita pe awọn ti gba akoso gbogbo ọfisi ijọba ibilẹ mẹtalelogun nipinlẹ naa.
Saa ọdun mẹta awọn alaga kansu ti tẹlẹ ti pari lọjọ Aje sugbọn wọn kọ lati kuro ni ọfisi wọn, ti wọn si n tọka si iwe ofin ọdun 2024, ti ile igbimọ aṣofin ti Martin Amaewhulw gbe kalẹ pe o ṣe afikun oṣu mẹfa si saa wọn ninu ijọba.
Ki ni Gomina Fubara sọ sita to fa rogbodiyan?
Ni owurọ ọjọ kọkandinlogun oṣu kẹfa ni Gomina Siminialayi paṣẹ fun awọn alaga kansu tuntun pe ki wọn bẹrẹ iṣẹ.
O kede ọrọ naa lasiko to n ba awọn araalu sọrọ lẹyin ti saa awọn alaga kansu ti tẹlẹ paari lọjọ kẹtadinlogun oṣu kẹfa ọdun 2024.
Bakan naa ni Gomina ti ṣe iburawọle fun awọn alaga ijọba ibilẹ kansu tuntun mẹtalelogun nipinlẹ naa.
Gomina gbe igbesẹ naa lẹyin ti ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Rivers ṣe ayẹwo fun awọn alaga naa ni dede ago mẹjọ owurọ.
Eyi wa lara awọn to bi ija silẹ nipinlẹ Rivers nitori bi alaga kansu ana se kọ lati kuro ninu ijọba.
E kede ilu o faraọ nipinlẹ Rivers- APC rọ ijọba apapọ
Awọn olori ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress nipinlẹ Rivers ti kesi ijọba apapọ lati kede ilu o faraọ nitori rogbodiyan to bẹ silẹ nipinlẹ naa.
Alaga APC nipinlẹ naa, Oloye Tony Okocha lo pe fun ipe lasiko to n ba awọn akọyorin sọrọ niluu Abuja.
O ni; “Ogun ti bẹrẹ nipinlẹ Kwara, ti eeyan to n ṣekupa ara awọn eeyan si mọ ara rẹ.
“Ko si iranlọwọ fun Gomina, Ko si iranlọwọ fun awọn ọlọpaa, Fun idi eyi, ẹgbẹ oṣelu APC n rọ ijọba lati tete gbe igbesẹ lori rogbodiyan naa.
“Mo n ke pe ijọba apapọ lati ti tete gbe igbesẹ ni kiakia.”















