Wo àwọn òfin tuntun àtàwọn gbas-gbos tó wáyé nílé aṣòfin Naijiria láti ọdún kan sẹ́yìn

Senate

Oríṣun àwòrán, Tope brown

Ọjọ kẹtala, oṣu Kẹfa, ọdun 2024 yii ni awọn aṣofin Naijiria nile igbimọ aṣofin to wa niluu Abuja pe ọdun kan lẹnu iṣẹ naa.

Laarin ọdun kan ọhun, awọn aṣofin naa ti fọwọsowọpọ pẹlu awọn ẹka ijọba mii lati ṣe awọn ofin to yẹ fun ilọsiwaju Naiiria.

Awọn kan lara awọn abadofin ati ofin ti wọn gbe kalẹ naa ni inu awọn ọmọ Naijiria dun si, bẹẹ ni awọn araalu tun sọ pe awọn ofin mii ti wọn ṣe ni ko mu ọgbọn wa.

Iroyin ni ko din ni abadofin 279 ti awọn aṣofin naa ti jiroro le lori laain ọdun kan naa, ti lara rẹ ti di ofin nigba ti iṣẹ ṣi n lọ lọwọ lori awọn mii.

BBC Yoruba ṣe akojọpọ awọn awọn ofin to lamilaaka ti awọn aṣofin Kẹwaa yii ti gbe kalẹ laarin ọdun kan sẹyin atawọn rogbodiyan to waye niẹ.

Awọn ofin to lamilaaka ti ile aṣofin naa gbe kalẹ

Orin ogo orilẹede atijọ

Ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Karun un, ọdun 2024 yii ni ile igbimọ aṣofin Naijiria buwọlu ofin tuntun to ni ki Naijiria pada si n lo orin ogo orilẹede atijọ.

Yatọ si awọn abadofin to ṣaaju, ọjọ kan ṣoṣo naa ni awọn aṣofin ọhun ka abadifn ọhun ti wọn si bẹrẹ si n duro de ifọntẹlu Aarẹ Bola Tinubu.

Ofin naa wọgile orin ogo “Dide ẹyin ara” ti gbogbo araalu mọ tẹlẹ, ti wọn si fi orin atijọ “Naijiria a yin ọ” dipo rẹ.

Eto ẹyawo fun awọn akẹkọọ

Ọjọ kẹta, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii ni Aarẹ Bola Tinubu buwọlu ofin eto ẹyawo fun akẹkọọ fun awọn ọmọ Naijiria.

Afojusun ofin naa ni lati fun awọn akẹkọọ ti ko rọwọ họri lanfani lati ya owo kawẹ lọwọ ijọba, eyii ti wọn yoo maa san pada ti wọn ba bẹrẹ iṣẹ.

Idajọ iku fun awọn to n gbe oogun oloro

Ọjọ kẹsan an, oṣu karun un, ọdun 2024 ni awọn aṣofin buwọlu ofin naa.

Ofin ọhun ṣetọ idajọ iku fun gbogbo ẹni to ba jẹbi ẹsun gbigbe oogun oloro ninu Naijiria.

Sẹnetọ Mohammed Monguno, to n ṣoju ariwa ipinlẹ Bornu lati inu ẹgbẹ oṣlu APC lo ṣagbatẹru abadofin ọhun.

Awọn awuyewuye to waye nile aṣofin naa laarin ọdun kan sẹyin

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Owo adura sinu apo iṣuna awọn aṣofin

Awọn ọmọ Naijiria yari mọ awọn aṣofin naa lọwọ lẹyin ti fidio bi wọn ṣe n pin owo lu sita lori ayelujara.

Ninu fodio naa ni olori ile ti n ṣo fun awọn aṣofin pe akọwe ile naa ti fi owo ranṣẹ si wọn amọ o ti gbagbe pe awọn ileeṣẹ amohunmaworan n ka ọrọ naa silẹ.

Ọrọ naa bi awọn araalu ninu pupọ ti wọn fi bẹrẹ si n sokọ ọrọ si awọn aṣofin ọhun.

Awuyewuye orin iyin orilẹede

Pupọ ninu awọn ọmọ Naijiria lo bu ẹnu atẹ lu awọn aṣofin lori bi wọn ṣe wọgile ori iyin ti gbogbo araalu mọ ti wọn si pada si ti atijọ.

Ohun ti awọn ọmọ Naijiria n sọ ni pe kii ṣe ọrọ orin iyin lo kan ni Naijiria lasiko ti ebi n pa ọpọ araalu.

N100m fun awọn aṣofin

Lara awọn rogbodiyan to ti waye laarin ọdun kan yii ni ọrọ owo ti iye rẹ to ọgọrun miliọnu naira ti wọn ni awọn aṣofin pin funra wọn gẹgẹ bii owo iranwọ.

Ẹgbẹ oṣiṣẹ, NLC, lo kọkọ fi ọrọ naa lede pe awọn aṣofin n pin N100m funra wọn nigba ti wọn n pin apo irẹsi fun araalu.

Amọ ṣa, awọn aṣofin naa ni ko si otitọ kankan ninu iroyin naa ati pe awọn ko pin owo kankan funra wọn.