Ìdí tí mo fi kúrò nínú ẹ̀sìn Islam, tí mo di Kristẹni rèé- Adewale Ayuba

Aworan Adewale Ayuba, gajumọ onifuji

Oríṣun àwòrán, Adewale Ayuba @Facebook

Gbajumọ olorin Fuji ni Adewale Ayuba, bo tilẹ jẹ pe awọn igba kan wa to jẹ pe oke okun lo fi ṣebugbe, sibẹ, awọn eeyan nilẹ yii ṣi n gbadun orin rẹ nigba gbogbo.

Laipẹ yii ni olorin Fuji Bonsue ẹ naa pe ẹni ọdun mọkandinlọgọta (59) loke eepẹ.

Musulumi ododo to lọ si Meka ni Adewale Ayuba tẹlẹ, ṣugbọn lọdun meloo kan sẹyin lo kuro ninu ẹsin naa to si di Kristẹni.

Nibi ifọrọwerọ ti Ayuba ṣe pẹlu sọrọsọrọ, Teju Baby Face, laipẹ yii lo ti ṣalaye idi to fi kuro ninu ẹsin Islam ti wọn bi i si, to si di Kristẹni lati ọdun 2010.

‘Mi ò déédé di Kristẹni, ohun tò ṣẹlẹ̀ rèé’

Aworan Adewale Ayuba, gajumọ onifuji

Oríṣun àwòrán, Adewale Ayuba @ Facebook

Nigba to n ṣalaye idi to fi di Kristẹni, Ayuba sọ pe,

‘’Mo yan Jesu Kristi laayo nitori ti o kede pe emi ni otitọ, ọna ati iye’’

‘’Ohun to wu mi lọkan mi ni, o si maa n munu mi dun. Ibaṣepọ eeyan pẹlu Ọlọrun to yan laayo maa n ti ọkan wa ni.

‘’Nigba ti mo n ṣe ẹsin Islam, ṣe wọn ri mi ni mọṣalaaṣi ni. Ko sẹni to waa ba mi pe mi o kirun wakati marun-un, ọrọ aye mi ko kan wọn.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

‘’Awọn obi eeyan lo le ba eeyan sọrọ lori aye rẹ, ara ita ko le ṣe e. Bi wọn ba sọ fun mi ti mo ni ki lo kan wọn nibẹ nkọ.

‘’Alaaja ni mama mi, baba mi o lọ si Meka ṣugbọn gbogbo wa la n ṣe Islam nile wa nigba yẹn. Ayuba lorukọ mi, Job ninu Bibeli.

‘’Mo di Kristẹni nitori ohun ti wọn n sọ ye mi, mi o mọ keu, mi o gbọ Larubaawa.

‘’Ti mo ba fẹẹ ba Ọlọrun sọrọ, ma a ṣẹṣẹ maa pe awọn aafaa ki wọn waa ba mi sọ ọ. Mo si beere lọwọ ara mi pe ṣe bi maa ṣe maa ba a lọ ree, mo ṣe ohun to yẹ ki n ṣe, nitori mo fẹẹ sun mọ Ọlọrun mi bo ṣe yẹ.

’’ Mo kuro ninu ẹsin Islam nitori ki n le jọsin nilana to rọ mi lọrun, ti mo si ri i pe Oluwa sun mọ mi pẹkipẹki.

‘’Mo maa ni lati lọ sile keu ti mo ba fẹẹ maa ṣe Islam lọ ki n too le ba Ọlọrun mi sọrọ, abi ki n maa ran eeyan si i.

‘’Mi o si ni asiko lati kọ keu tori iṣẹ mi ni mo ṣe mu eyi to rọ mi lọrun ti mo si sunmọ Ọlọrun mi.

‘’Mi o foju tẹmbẹlu ẹsin Islam ti wọn bi mi si, koda pupọ ninu awọn ọmọ ẹgbẹ mi ni wọn jẹ Musulumi ti a si jọ maa n gba adura papọ.’’

Ayuba ṣalaye nipa iyawo kan ṣoṣo to ni, to si loun ki i yan ale.

O ni nitori boun ko ba ṣẹ iyawo oun nipa iru iwa bẹẹ, oun yoo ṣẹ Ọlọrun.

Nipa bo ṣe da bii ọmọ ogoji ọdun lasiko yii to ti pe 59, Ayuba sọ pe oun maa n ṣọ ohun toun n jẹ ni.

Olorin Fuji naa sọ pe oun le mu tii nigba mi-in koun ma fi miliiki si i, koun si ma jẹ burẹdi si i pẹlu.

Lakootan, o ni ohun to ba ba kaluku lara mu ni ko jẹ.