Ìkọlù àwọn agbébọn gbòde nílùú Ado Ekiti, èèyàn mẹ́ta kú, ará ìlú káyà sókè

Igboro ilu Ado Ekiti

Oríṣun àwòrán, others

Iṣọwọ awọn agbebọn kan to ṣọṣẹ nigboro ilu Ado Ekiti laarin osẹ yi ti gbẹmin lẹnu odindi eeyan mẹta ọtọọtọ.

Iroyin fidi iṣẹlẹ naa mulẹ pe, Lọjọ isẹgun ni awọn agbebọn tẹnikan o mọ kan kọkọ da ẹmi ọmọ ẹgbẹ ọlọkada kan torukọ rẹ n jẹ Ọmọyajowo Samuel legbodo, ni agbegbe agọ ọlọọpa to wa ladugbo okesa nilu Ado Ekiti legbodo.

Awọn araalu ṣi n pariwo kilobayiwa lawọn agbebọn naa ba tun ṣeku pa eeyan meji ni ibudo ọtọọtọ ni Ọjọbọ.

Ni nnkan bii agogo meje abọ ni awọn agbebọn yii tun lọ ṣe iku pa eeyan kan ti wọn pe ni Alfa to n ṣe POS lagbegbe ile ẹkọṣẹ iṣegun to wa nilu Ado Ekiti, ti wọn si ja apo owo rẹ gba salọ.

Gẹgẹ bi awọn to ṣe oju rẹ ṣe sọ, alupupu ọkada lawọn agbebọn naa gun wa ṣe iṣẹ ibi wọn ti wọn si ko ọpọ nnkan olowo iyebiye lọ.

Amọṣa awọn ọlọpaa ti gbe oku rẹ lọ si ile igbokupamọ si.

Nigba ti yoo tun fi di ọwọ ọsan ni nnkan bi agogo mẹta ni awọn agbebọn miran lori alupupu ọkada tun lọ ṣeku pa arakunrin kan to n kiri irẹsi lagbegbe ọja Bisi ni arigbungbun Ado Ekiti kan naa. Ọr naa di boolọ yago pẹlu bi gbogbo awọn ara ọja ṣe fọnka nigba ti wọn gbọ iro ibọ ati ohun to ṣẹlẹ si arakunrin naa.

Ọpọ awọn ontaja lọja naa ni wọn si ti fi idi mọle ni lẹyin iṣẹlẹ naa lori ibẹru fun ẹmi wọn.

Ọpọ araalu lo n kaya soke nitori ibi awọn oniṣẹ iku to n jẹ kaakiri ilu Ado Ekiti bayii

Aworan igboro Ibadan

Oríṣun àwòrán, other

Awọn olugbe ilu Ado Ekiti to ba BBC News Yoruba sọr ṣalaye pe inu fuu aya fuu ni awọn fi n gbe bayii nitori awọn agbebọn naa.

Awọn olugbe ilu Ado Ekiti naa ti wọn ko fẹ ka darukọ wọn nitori abo ẹmi wọn ni paroparo ni igboro ilu naa da lati igba ti iṣẹlẹ yii ti waye.

Wọn ni awọn eeyan ko lee rin bi wọn ṣe fẹ laarin igboro nitori ibẹru ti awọn iṣẹlẹ ikọlu naa ti da sọkan wọn.

koda awọn kan ni awọn ko tilẹ le gba ki awọn ọmọ awọn lọ si ile iwe nitori ibẹru awọn oniṣẹ ibi yii.

Ọwọ ti tẹ awọn afurasi kan lori iṣẹlẹ naa - Ileeṣẹ ọlọpaa

Alukoro ile iṣẹ ọlọọpa ni ipinlẹ Ekiti, ASP Sunday Abutu, ṣalaye wi pe iṣẹ iwadi ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa, O ni ọwọ ti tẹ awọn afurasi kan, bẹẹ ni wọn si ti n fọrọ wa wọn lẹnu wo ninu atimọle.

Sunday Abutu ko sai lọdi ohun to ṣokunfa iṣẹle ọhun mọ igbesẹ awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun lẹsẹ, bakan naa lo sọ pe ko si ofin koni o gbele nilu Ado Ekiti rara.

Awọn ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ẹwẹ, Alukoro ile iṣẹ ọlọọpa naa ṣalaye wi pe, wọn ti ko ọgọọrọ awọn oṣiṣẹ agbofinro si igboro lati bẹrẹ ayewo fini fini ṣiṣe, lati lee fi kun iṣẹ iwadi tiwọn n ṣe lọwọ.

O wa gba awọn ara ilu naa nimọran, lati fọwọsọwọpọ pẹlu awọn agbofinro ki ilu ọhun lee wa lalaafia, ati wipe awọn ọlọọpa naa ko ni tẹ ẹtọ awọn eeyan ilu loju mọlẹ nipasẹ iṣẹ naa.

Abutu wa rọ awọn ara ilu lati fi eyikeyi iroyin ti yoo ṣeranwọ fun iwadi ọhun to wọn leti, bẹẹ lo tọka sii pe alaafia ti bẹrẹ sini jọba nigboro ilu Ado Ekiti.