Udiroko Festival yóù wáyé lónìí nílùú Ado Ekiti

Oríṣun àwòrán, Udiroko Festival Page
Ọdun Udiroko ti 2021 yoo waye lonii ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun 2021.
Ọdọdun ni wọn maa n ṣe ọdun Udiroko nilu Ado Ekiti lati ṣe ayẹsi awọn ijoye Elegbe nipinlẹ Ekiti.
Akọroyin BBC to wa niluu Ado Ekiti jabọ pe ayajọ ọdun naa ni Ewi ti Ado Ekiti, Ọba Rufus Adeyemo Adejugbe Aladesanmi kẹta yoo ṣe afihan ade rẹ.
- Mẹ́fà nínú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ Islamiyya Tegina ti kú, àwọn ajínigbé ṣì ń bèèrè N200m
- Tètè wá gbé òkú eèyàn rẹ bí bẹ́ẹ̀ kọ́ a ó sìn wọ́n papọ̀ mọ́ tí 200 lópin ọ̀sẹ̀- Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá
- Wọ́n búra fún Aarẹ tuntun ní Zambia, inú ará ìlú dùn fún ìlérí tó ṣe fún wọn
- Ǹkan mọ́kànlá tí o ni láti mọ̀ nípa Sẹnatọ Biyi Durojaiye tó d'Ólògbé
Ọdun Udiroko ọhun lo tun duro gẹgẹ bii ọdun iṣu tuntun fun Ewi ti Ado Ekiti.

Oríṣun àwòrán, Morakinyo Solomon Ogunniyi Kayegbo
To n tumọ si pe ọjọ ọdun naa ni ori ade ọhun yoo bẹrẹ si jẹ iṣu tuntun.
Gẹgẹ bii ohun ti itan ilu Ado Ekiti sọ, ọjọ ọdun Udiroko ni ayajọ ọdun tuntun ni ilu naa.
Yatọ si iṣu tuntun ati afihan ade Ewi ti Ado Ekiti, ayajọ ọdun naa ni wọn maa n gbe ilu ayaba jade lati ṣafihanrẹ fun awọn araalu.
BBC Yoruba ti wa niluu Ado Ekiti lati maa mu gbogbo bo ba ṣe n lọ fun yin.
- Adájọ́ pàṣẹ ìtúsílẹ̀ mẹ́rin lára 12 ọmọlẹ́yìn Igboho tó wà ní àhámọ́ DSS l'Abuja
- "Ó yẹ kí àwọn ẹ́ṣọ́ aláàbò lè mọ̀ pé àwọn jàndùkú fẹ́ kọlu ilé ẹ̀kọ́ ẹ̀kọ́ṣẹ́ ọmọogun Nàìjíríà, NDA kí ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó wáyé"
- Obìnrin di gómìnà ìpínlẹ̀ New York fún ìgba àkọ́kọ́ l'Amẹrika
- Ìjà ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni o, àwọn dókítà NARD tó ń yanṣẹ́lódì fárígá pẹ̀lú ìjọba
- Wo ọ̀nà márùn ún tí o lè gbà dáàbò bò ara rẹ lọ́wọ́ ìjàmbá láì gbé ìbọn!














