Pẹ̀lú bí ooru àmújù ṣe ṣọṣẹ́ ní Hajj lọ́dún yìí, wo àwọn ohun tí o lè fi dènà ooru àmújù

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ooru amuju jẹ aṣiwaju orisun iku ọwọọwọ to niiṣe pẹlu oju ọjọ ati ayika lagbaye.
Bakan naa ni amuju ooru tun le ṣe agbodegba abẹnu fun awọn aisan miran lọpọ yanturu.
Bayii, ọwọja ooru amuju bayii ti wa n peleke sii lọdọọdun nitori ijamba oju ọjọ ati ayika to n waye lagbaye.
Amuju ooru maa n waye nigba ti ooru ti ko lẹgbẹ ba n mu lọsan ati loru. Bẹẹ ni wọja ooru, iye akoko ti ooru amuju fi n mu pẹlu lemọlemọ rẹ ti n gogo sii.
Ajọ Iṣọkan agba si ti sọ pe yoo maa pọ sii ni lọdọọdun nitori ijamba oju ọjọ ati ayika, ti oyinbo n pe ni ‘Climate change’.
Ni awọn ilu tabi agbegbe ti ọpọ eniyan ba n gbe, ooru amuju le da wahala ilera silẹ eyi to le fa iku ọwọọwọ ati awọn wahala miran to le mu ipadasẹyin ba awujọ. Fun apẹrẹ, irẹwẹsi lẹnu iṣẹ.
Bakan naa ni wọn le fa adinku ba ijafafa ẹka eto ilera paapaajulọ, bi aisi ina mọnamọna, aisi ipese omi to ja gaara ati igbokegbodo ọkọ to munadoko, ba tun wa pẹlu ooru amuju yii.
Awọn wo lọrọ ooru amuju yii kan?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ipenija ooru amuju n waye lawọn ẹkun ilẹ olooru nibi ti itanṣan oorun ti maa n waye tẹlẹri.
Gẹgẹbi ajọ ilera agbaye, WHO ṣe sọ, awọn oṣiṣẹ ti iṣẹ wọn nii ṣe pẹlu wiwa ni ta gbangba atawọn oniṣẹ kerejekereje, awọn elere idaraya atawọn ẹka iṣẹ miran maa n bọ sọwọ paṣan ooru amuju nitori pe iṣẹ wọn nilo ọpọ ohun amuṣagbara ni ẹya ara eyi to n tete mu ooru jade wa.
Awọn mẹkunu, yala ni ilu nla tabi ileto kerejekereje pẹlu maa n bọ sọwọ paṣan ooru amuju yii nitori pe wọn kii ni oreọfẹ tabi agbara lati gbe inu ile to jọju tabi ni awọn ohun elo amara tutu.
Bakan naa ni iṣẹda eniyan pẹlu a tun maa niiṣe lọpọlọpọ pẹlu bi ọwọja ooru amuju yoo ṣe ri lara. Fun apẹrẹ, ajọ ilera agbaye jẹ ko di mimọ pe awọn obinrin maa n foju wina ooru amuju lọpọlọpọ nitori pe awọn ni wọn maa n dana ounjẹ ninu ile lasiko ooru.
Bawo ni ooru amuju ṣe maa n pa ilera lara?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iye ooru ti o n pamọ si agọ ara eniyan niiṣe pẹlu aile dẹkun iye ooru ti eroja ara n gbe jade, (b) awọn aṣọ to n dena afẹfẹ alaafia si ara, (c) awọn ooru ti o kun ayika.
Bi ara kii ṣe lagbara lati ṣe eto amojuto ooru to wa ninu ara, ati dẹkun awọn ooru to n jade ni ayika kun ara nnkan to n fa ijamba rọparọsẹ nipa ooru. Eyi maa n fun ọkan ati kidirin ni ọpọ iṣẹ lati ṣe ju bi o ṣe yẹ lọ. Bakan naa lo tun le fa alekun wahala fun awọn to ti ni awọn aisan bi itọ ṣuga, aiṣedede ọkan ati aiṣe dede eemi tẹlẹ.
Awọn igbesẹ wo lo le gbe lati dẹkun ooru amuju atio ijamba to ọ mọ ọ?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Jinna si inu ooru
- Yẹra fun lilọ si ita tabi ṣiṣe awọn iṣẹ to lagbara lawọn asiko ti oorun ba kan atari loojọ.
- Maa duro si abẹ iboji
- Rii daju pe o nlo wakati meji si mẹta labẹ iboju nibi to ba tutu daadaa.
- Maṣe gbagbe ewu to wa ninu iwẹ wiwẹ bii ki omi gbeni lọ, nitori naa bi o ba fẹ lọ luwẹ lodo, rii daju pe o ko danikan lọ.
- Maa tẹti leko fun awọn iroyin nipa bi ọwọja ooru lagbegbe rẹ ba ṣe n lọ si.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Rii daju pe o n mu ki ile rẹ rẹ tutu daadaa
- Rii daju pe o n ṣi ferese ile rẹ silẹ lalẹ lati lo anfani afẹfẹ tutu aṣalẹ fi mu inu ile rẹ tutu nitori ojuju ọjọ yoo ti tutu diẹ lasiko yii.
- Ni ọsan, bi o ba rii pe ooru to n mu ni ita pọ ju ooru inu ile rẹ lọ, ti awọn ferese ile rẹ ki o si fi aṣọ ferese bo wọn.
- Tan faanu rẹ nigba ti iwọn ooru inu ile rẹ ba ti kere ju ida 40⁰C/ 104⁰F, amọṣa bi iwọn ooru inu ile rẹ ba ju 40⁰C/ 104⁰F lọ, faanu yoo tun maa da kun oru to wa ninu ile rẹ ni.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Mu ara rẹ tutu ki o si mu omi to to
- Rii pe awọn aṣọ to fẹlẹ ni o n wọ, aṣọ ti o si n tẹ sori ibusun rẹ pẹlu gbọdọ fẹlẹ.
- Rii daju pe o n fi omi tutu wẹ loorekoore
- Maa lo aṣọ ti o n ki sinu omi lati lati fi mọ ara rẹ.
- Maa mu omi loorekoore. (O kere ju, ife omi kan ni wakati si wakati, tabi lita omi meji si mẹta lojumọ)
- Maa bẹ awọn arugbo paapaa ti ọjọ ori wọn ti ju marundinlọgọrin lọ layika rẹ wo, atawọn ti o ni ipenija kan tabi omiran bii, aisan ọkan, ẹdọ, kidinrin tabi awọn akanda atawọn eeyan to n da gbe.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Maa daabo bo awọn ọmọde
- Maṣe da fi awọn ọmọde tabi ẹranko silẹ ninu ọkọ fun akoko k’akoko nitori ooru inu awọn ọkọ lee lọ soke nigbakugba.
- Rii wi pe awọn ọmọde ko wọ inu oorun lasiko ti oorun ba kan atari, fi wọn si abẹ iboji tabi inu ile rẹ.
- Maṣe wọ aṣo ti ko ba fẹlẹ fun ọmọde. Lo awọn fila ati iboju lati daabo bo wọn lọwọ oorun.















