Kò dín ní èèyàn 1,301 tó kú ní Hajj ọdún yìí – Saudi Arabia

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn alaṣẹ ni orilẹede Saudi Arabia, ti sọ pe ko din ni eeyan 1,301 to ku lasiko Hajj ọdun yii.
Inu ooru gbigbona ni irinajo Hajj ọdun yii waye, nibi ti oju ọjọ ti ma n gbona to ida aadọta, 50 degrees Celsius.
Gẹgẹ bi ohun ti ileeṣẹ iroyin SPA sọ, o le ni idaji awọn to ku, ti ko ni ẹkunrẹrẹ awọn iwe to fihan pe arinrinajo to wa si Saudi Arabia fun Hajj ọdun yii ni wọn jẹ.
Bakan naa ni wọn sọ pe arugbo ati awọn to ni aisan ninu ara lo pọ ju lara awọn to ku.
Minisita fun eto ilera ni orileede naa, Fahd Al-Jalajel, sọ pe awọn ti gbe gbogbo igbesẹ to yẹ lati jẹ ki awọn araalu mọ ewu to rọ mọ ooru gbigbona, ati bi awọn arinrinajo ṣe le daabo bo ara wọn.
Bakan lo sọ pe o le ni ẹẹdẹgbẹta arinrinajo ti wọn ti tju nileeosan.
Ọpọlọpọ orilẹede si lo ti sọrọ nipa iye arinrinajo lati ọdọ wn, to ku.
Ileeṣẹ iroyin AFP jabọ pe, eeyan 658 lo ku lati Egypt. Indonesia sọ pe o le ni 200 eeyan wọn to ku, ti India si ni 98 ni ti wọn to ku si Hajj ọdun yii nitori ooru.
Ẹwẹ, Pakistan, Malaysia, Jordan, Iran, Senegal, sudan ati Iraq naa ti sọ iye eeyan wọn to ku.
Iṣẹlẹ to waye yii ti mu ki olootu ijọba ni Egypt, Mostafa Madbouly, gbẹsẹ le iwe aṣẹ awọn ileeṣẹ ọkọ ofurufu kan to ko awọn arinrinajo lọ si Hajj.
Bakan naa ni Jordan ti fi ofin gbe awọn ileeṣẹ abani ṣeto irinajo, fun pe wọn gba ọna ti ko ba ofin mu ko arinrinajo wọ Saudi Arabia.
Ni Tunisia, aarẹ wọn ti gba iṣẹ lọwọ minisita fun ọrọ ẹsin.
Ki lo ma ṣẹlẹ ti eeyan ba ku lasiko to wa ni Hajj?
Nigba ti arin irin ajo Hajj ba ku lasiko ti o n ṣe Hajj, iku ni wọn n pe iṣẹ Hajj. Wọn ma lo awọn ẹgbaọwọ tabi awọn ohun idanimọ lati ṣe idanimọ naa. Lẹyin naa, wọn yoo pese iwe-ẹri dokita, ti Saudi Arabia fun iwe-ẹri iku.
Awọn adura isinku yoo waye ni awọn mọṣalaṣi pataki bii Masjid al-Haram ni Mekka tabi Mossalassi Anabi ni Medina, da lori ibiti iku naa ti waye. Wọn ma fọ ara, ti wọn a we, ati gbe sinu awọn firisa ti ijọba Saudi ti pese.
Awọn eto isinku jẹ rọrun, laisi awọn ami, nigba mii pẹlu ọpọlọpọ awọn ara ni ibi kan. Iwe itẹ oku naa ṣe akojọ awọn ti wọn sin nibẹ, lati fun awọn idile ni anfani lati ṣabẹwo si awọn iboji ti wọn ba fẹ.
Ijọba Saudi, pẹlu iranlọwọ lati awọn ẹgbẹ oriṣiriṣi ati Red Crescent, sọ pe o ni idaniloju "awọn ilana isinku ti o ni ọlá ati ọwọ".












