Pásítọ̀, àwọn ọmọ ìjọ, lu Alfa àti àwọn ẹlẹ́hàá rẹ̀ ní àlùbami nítorí ẹran Ileya

Aworan Ori Alfa Abdulazeez ati Iyawo rẹ

Oríṣun àwòrán, Others

Alfa Sulaiman Abdulazee ati awọn iyawo rẹ meji ni wọn dero ile iwosan lẹyin ti ede-aiyede bẹ silẹ laarin wọn ati Olusọ aguntan to mule ti wọn.

Iṣẹlẹ yii lo waye lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kefa, ọdun 2024, eyi tii ṣe ọjọ ọdun Ileya, ni agbegbe Barracks, Odo Omu, Iseyin nipinlẹ Oyo.

Iroyin to tẹ wa lọwọ ni pe kete ti Alfa Abdulazeez kuro ni irun yidi, ti wọn dari pada si ile pa ẹran ọdun, ni wahala naa bẹ silẹ.

Bawo ni iṣẹlẹ se waye?

Nigba to n ba Ileeṣẹ BBC News Yoruba, Agbẹjọro fun Alfa Abdulazeez, Amofin A.A Olowonjaye ṣalaye pe lati bii ọdun mẹrin sẹyin ni ede aiyede ti n waye laarin onibaara rẹ ati Pasitọ Busari Stephen.

“Ni agbegbe Barracks Odo Omu niluu Iseyin ni Alfa Abdulazeez kọ ile si, lẹyin ọdun marun un ni Pasitọ Burasi naa wa mu ile ti wọn, to si n lo o lati fi se ile ijọsin.

“Eyi ko mu wahala da ni nitori Alfa ba awọn Ile ijọsin meji mii ladugbo naa sugbọn ojoojumọ ni Pasitọ Busari n ṣe ijọsin pẹlu ariwo ti ko se farada, laarọ, lọsan ati alẹ.

“Ariwo yii n bi awọn ara adugbo ninu sugbọn nitori ile Pasitọ yii wa niwaju ile Alfa, ariwo yẹn n daamu Alfa ati awọn Ẹlẹha rẹ pupọ.

“Ni nnkan bi ọdun mẹrin sẹyin, a kọ lẹta si Pasitọ Busari lori eyii pe ko gbiyanju lati mu adinku ba ariwo ọhun, tabi ki wọn dari rẹ si bi ti ko ni daamu awọn ara adugbo sugbọn Pasitọ Stephen kọjalẹ.”

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Gẹgẹ bii o ṣe ṣalaye fun akọroyin BBC, Olowonjaye ni eyii to bi ija to sẹsẹ bẹrẹ bayii ni eyi to waye lasiko ọdun Ileya nigba ti onibaara rẹ, Mallam Abdulazeez pada de lati Mọṣalasi ni ọjọ Ileya, to si gbe ẹran agbo sita lati pa ni ilana ẹsin Islam lori iẹ rẹ.

O ni eyi lo di ariwo ti Pasitọ si sọ fun Alfa pe ko lẹtọọ lati kọju ẹran pipa si ọna ile ijọsin oun.

O tẹsiwaju pe Pasitọ Stephen kesi ọmọ rẹ, Damilola, to jẹ ọmọ ologun orilẹede Naijiria, ti wọn si yawọ ile Alfa lati lu u ni alubami pẹlu awọn iyawo rẹ meji, ti ọkan wa ninu oyun.

“Ni ọjọ Aiku, to jẹ ọjọ Ileya, bi a se ti idi de, Alfa n pa ẹran ọdun lori ilẹ rẹ, nitori pe o jẹ ọjọ Aiku ti awọn Pasitọ naa n se isin wọn lọwọ.

“Pasitọ jade lọ ba Alfa nibi to ti n pa ẹran, pe ki lo de to fi da oju pipa ẹran kọ iwaju ile ijọsin rẹ.

“Alfa da l'oun pe o ni ilana bi wọn se maa n pa ẹran ninu ẹsin Islam ati pe ori ilẹ oun ni oun wa.

“Ọrọ yii ko ju bẹ lọ, ti Pasitọ si leri si Alfa. Ko ju isẹju diẹ, Pasitọ kesi ọmọ rẹ to jẹ Soja, a n pe ọmọ rẹ ni Damilola Stephen nigba to n bọ, o kesi awọn Soja mi ti orukọ wn n jẹ, Blessing Olusesi ati Azeez Taofeek.

“Lẹyin naa, a ri pe ọkan lara wọn ki n ṣe ọmọ ologun. Awọn ọmọ ologun yii pẹlu Pasitọ yabo ile Alfa pẹlu igi, apola, irin, ọbẹ.

“Eeyan marun un, Soja mẹta lo lu Alfa, bi wọn se n lu ni wọn n saa, ti wọn si tun ti i ṣubu.”

Awọn Soja yii tun ṣe Iyawo Alfa to jẹ alaboyun leṣe

Olowonjaye n tẹsiwaju wipe, bi wọn ṣe n lu Alfa ni awọn iyawo rẹ meji jade sita si wọn, ti awọn ẹlẹha naa si tun jade siya lọwọ awọn eeyan ti Pasitọ pe wa.

“Lilu ti wọn lu Alfa, eeyan marun lori eeyan kan ni awọn iyawo rẹ to jẹ ẹlẹha ṣe sare sita pe ki wọn ma lu Alfa awọn.

“Lilọ ti iyawo to loyun sinu lọ sibẹ, ti awọn ọmọ ijọ naa si ti jade sita ni wọn bẹrẹ si ni ma wọ ni ilẹ lati inu ile ọkọ rẹ lati lọ si nu ile ijọsin, eyi lo jẹ ki o farapa gan an, to si ti dero ile iwosan.

“Nigba ti a de si ile iwosan, wọn ni oyun naa farapa, ti a si n gbadura pe ki ọmọ naa ma ku, ki ẹnikẹni naa maku.

O tun fi ẹsun kan pe wọ fọ gi mọ iyawo kekere naa lori, ti ori rẹ si bẹ.

Olowonjaye ni awọn eeyan Pasitọ ko gba awọn eeyan Alfa laaye lati fi foonu wọn ka gbogbo nnkan to waye, ti wọn si n dunkoko mọ wọn sugbọn wọn ri diẹ ka.

Ko pẹ ti wọn wa ni ile iwosan ni wọn tun gbọ pe wọn tun ti yabo ile alfa lati kọlu awọn eeyan to n ran Alfa lọwọ lati pa ẹran.

“Wọn gun eeyan kan lọbẹ, to fi ọwọ gba nitori wọn gbe ọkunrin naa lọ sugbọn o kọ jalẹ.”

Kini ẹgbẹ CAN Oyo sọ si iṣẹlẹ yii?

Olori fun ẹgbẹ CAN niluu Iseyin, Olusọ Aguntan Ogundairo Adeniyi sọ pe awọn ti gbọ si iṣẹlẹ naa ti wọn si ti bẹrẹ si ni gbe igbesẹ alaafia lori rẹ.

Bakan naa, Adeniyi ni CAN ti fofin de pasitọ naa pe ko gbe ile ijọsin rẹ kuro ni agbegbe naa ni kiakia.

“Nigba ti emi de sibẹ gẹgẹ bi Alaga CAN ni ijọba ibilẹ Iseyin, mo ri pe Pasitọ lo kọja aye rẹ, nitori ko gba ifẹ laaye ati pe kii se iwaju ile ijọsin rẹ ni Alfa ti pa ẹran.

“Mo ti lọ kiri lọ si ọdọ awọn Alfa niluu Isẹyin lati petu si ija naa.

“A ti fofin de Pasitọ pe ko gbe Ile ijọsin naa kuro ni agbegbe naa ati fun ẹmi ara rẹ gan-an.”