Mọ̀ nípa ìtàn àti àwọn nnkan mìí nípa Ojude Oba, ọdún Ijebu tó n mi orí ayélujára tìtì

Awọn to n ṣe ajọyọ nibi ọdun Ojude Oba

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ninu awọn ọdun to gbajugbaja nilẹ Ijẹbu, nipinlẹ Ogun, eyi ti tọmọde-tagba, onile-talejo maa n kopa ninu rẹ ni ọdun Ojude Ọba jẹ, to si tun gbajugbaja nilẹ Yoruba.

Ọjọ kẹta ọdun ileya ni ọdun Ojude Ọba maa n waye.

Itan sọ pe ọdun 1892 ni ọdun naa bẹrẹ lasiko ti Ọba Adesunmbọ Tunwase fun awọn musulumi nilẹ lati kọ mọsalasi si.

Tọwọ tọwọ ni ayẹyẹ yii bade, Ojude Oba jẹ ọkan lara ayẹyẹ to lamilaka niluu Ijebu ati ipinlẹ Ogun.

Ṣe ka sọ nipa aṣọ ni, ẹsọ, ati awọn nnkan aṣaraloge ni ka sọ ni, gbogbo rẹ lo peju sibi ayẹyẹ naa.

Aworan awọn araalu ni Ojude Oba

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọdun awọn musulumi ni ọpọ eeyan ri ọdun Ojude Ọba si nigba to bẹrẹ.

Asiko yii si ni awọn musulumi maa n lọ si aafin ọba lati ki aku ọdun sọdọ rẹ lasiko ọdun ileya, lọna ati fi ẹmi imoore wọn han fun ọwọ aanu ati ọrẹ to se fun wọn.

Amọ kẹrẹkẹrẹ, se ni ọdun yii n fẹju si bi ọdun se n gori ọdun, to si kọja ọdun ẹlẹsin kan.

Lonii, ọdun Ojude Ọba ti di aayo nilẹ Ijẹbu, eyi ti oniruuru ẹlẹsin, ẹlẹyamẹya, tọmọde tagba n peju lati se ajọyọ rẹ, koda, awọn eeyan, paapa awọn ọmọbibi ilu Ijẹbu maa n ti ẹyin odi wa se ayẹyẹ naa.

Lasiko ọdun Ojude Ọba, faaji maa n pin silẹ Ijẹbu ni, ti awọn Ijẹbu kii si fi ọdun Ileya sere boya ẹlẹsin Kristiẹni ni, Musulumi tabi abọrisa, ti wọn yoo si wọ asọ ẹgbẹjọda lọkan o jọkan, ti gbogbo ilu yoo si maa gba yin-in lasiko ọdun Ojude Ọba.

Awọn ohun to yẹ kẹ mọ nipa ọdun Ojude Ọba

Awọn to n gun ẹṣin ni Ojude Oba

Oríṣun àwòrán, Adekunle Ajayi/Getty Images

Awọn to n jo nibi ọdun Ojude Oba

Oríṣun àwòrán, Toyin Adedokun/AFP/Getty Images

Afojusun ọdun Ojude Ọba ni lati se amugbooro awọn aṣa, ajogunba wa ati awọn ise adayeba gẹgẹ bi ọmọ Yoruba.

Eyi si maa n fi oju han pẹlu ọpọ ati oniruuru asọ ẹgbẹjọda ti ẹlẹgbẹjẹgbẹ maa n wọ lasiko ọdun Ojude Ọba.

Se ni asọ maa n pe asọ ransẹ lasiko ayẹyẹ naa, ti awọn ọkunrin yoo si ko si oniruuru agbada, tawọn obinrin naa yoo si lo asọ lọ bii rẹrẹ, asọ oke yoo maa pe asọ oke ransẹ ni, to fi mọ adirẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Oniruuru irun didi, asọ ibilẹ, ounjẹ ilẹ Ijẹbu tii se Ifọkọrẹ ati ijo ibilẹ ko si ni gbẹyin.

Idije ẹsin gigun, ibọn yinyin ati ijo jijo

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lara awọn ayẹyẹ to n mu ki ọdun Ojude Ọba jẹ manigbagbe nilẹ Ijẹbu ati nilẹ Yoruba lapapọ ni bi wọn tun ṣe n se afihan ara asa wa lọna miran, eyi to nii se pẹlu ibọn yinyin, gigun ẹsin bii ọlọla ati sise idije ijo jijo laarin awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ ati idile.

Awọn idile to n gun ẹsin yoo maa le ara wọn lare ni, ti wọn yoo si wọ oniruuru asọ ti wọn fi n se idije ẹsin gigun laarin awọn ọkunrin, tawọn obinrin naa yoo si maa tadi reke lati pa ara wọn layo lasiko ọdun Ojude Ọba.

Awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ ti wọn n pe ni Rẹgbẹrẹgbẹ to wa ni isọri-isọri ọjọ ori kọọkan ni yoo se afihan bi wọn se le tadireke si.

Ẹgbẹ to ba si gbegba oroke ni wọn yoo fun ni ẹbun to jọju lasiko ọdun Ojude Ọba, ninu eyi ti wọn yoo maa yin ibọn soke loore koore.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Aṣa sise Kade pẹ lori, ki bata pẹ lẹsẹ fun ọba

Lara awọn ohun pataki ti kii gbẹyin lasiko ọdun Ojude Ọba ni asa lilọ ki ọba pe ki ade pẹ lori, ki bata pẹ lẹsẹ, ki ẹsin ọba si jẹ oko pẹ.

Pẹlu orin, ijo, ilu ati ayọ ọkan si ni awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ lọkanojọkan fi maa n lọ ki ọba naa to wa nikalẹ, lati igba ti ọdun Ojude Ọba si ti bẹrẹ lati bii ọgọrun ọdun sẹyin ni asa yii ko ti parun.

Koda, wọn yoo tun mu ẹbun, eroja ounjẹ, lọwọ fun ọba gẹgẹ bii ẹbun ọdun.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọdun Ẹsin ni Ojude Ọba fi bẹrẹ

Awọn ẹtahoro musulumi kan lo bẹrẹ ọdun Ojude Ọba, ko to di pe o di itẹwọgba nilẹ Ijẹbu. Sugbọn lasiko yii, ọdun Ojude Ọba ti tayọ ẹsin kan soso, ti awọn oniruuru ẹlẹsin si ti n tẹwọgba ọdun naa nilẹ yii ati lẹyin odi.

Ọjọ kẹta Ileya ni ọdun Ojude Ọba maa n waye

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ni ọjọ kẹta ọdun Ileya ni awọn ọmọ bibi ilẹ Ijẹbu yoo korajọ pọ lati se ayẹyẹ ọdun Ojude Ọba pẹlu awọn ọrẹ, ẹbi ara ati ibatan wọn. Wọn si fi ayẹyẹ naa si ọjọ kẹta ọdun Ileya lọna ati fun awọn musulumi ni aaye ati anfaani lati gbadun ọdun Ileya ni ọjọ meji akọkọ.

Ni ọjọ kẹta yii ni awọn tọkunrin-tobinrin, ọmọde ati agba nilẹ yii ati lati oke okun yoo pe biba si gbagede kan lati se ọdun naa nilu Ijẹbu-Ode.

Bi ọdun Ojude Ọba si se n fẹju si, to si n di itẹwọgba, naa ni aayan n lọ lati jẹ ko di ilumọọka jakejado agbaye.

Ẹgbẹ obinrin nibi ọdun Ojude Oba

Oríṣun àwòrán, Getty Images