Iléèṣẹ́ ọlọ́pàá f’èsì lórí ẹ̀sùn ìjínigbé tí Laide Bakare fi kan àwọn ọlọ́pàá kan

Oríṣun àwòrán, Laide Bakare/INSTAGRAM
Lópin ọ̀sẹ̀ tó kọjá yìí ni gbajúgbajà òṣèré tíátà Laide Bakare figbé bọnú lórí ayélujára pé àwọn ọlọ́pàá Eko dá òun dúró lọ́nà àìtọ́ látàrí pé wọ́n fẹ́ gba owó lọ́wọ́ òun.
Nínú ọ̀pọ̀ fídíò tó fi sórí ìkànnì Instagram rẹ̀ ni Laide Bakare ti ṣàlàyé nǹkan tó ṣẹlẹ̀ láàárín òun àtàwọn ọlọ́pàá ní òpópónà Mile 12 ní ìpínlẹ̀ Eko.
Ó ṣàlàyé pé òun àti ọmọ òun, ọmọ ọdún mẹ́rìnlá ní àwọn jọ wà nínú ọkọ̀ tí àwọn ń lọ síbi ayẹyẹ ìgbéyàwó kan kí àwọn ọlọ́pàá tó dá òun dúró wí pé òun ń gba ọ̀nà tí kò tọ́.
Ó ní ọ̀kan nínú àwọn ọlọ́pàá bíi mẹ́ẹ̀dógún náà fa òun bọ́lẹ̀ nínú ọkọ̀ pẹ̀lú bí òjò ṣe ń rọ̀ tí wọ́n sì gbé ọkọ̀ òun lọ pẹ̀lú ọmọ òun nínú rẹ̀.
Ó sọ pé ó da òun lójú pé òun kò ṣẹ̀ sófin ìjọba nítorí òun kò fìgbà kankan lo ìgbé ayé òun lòdì sí sófin rí.
Òṣèré náà ní ó jọ wí pé àwọn ọlọ́pàá náà mọ̀ọ́mọ̀ mú àwọn ọlọ́kọ̀ tó ní ọkọ̀ ńláńlá nítorí àwọn mìíràn ń gba ọ̀nà tí wọ́n ti mú òun náà àmọ́ tí wọn kò ṣe nǹkankan fún wọn.
Ó ṣàfihàn bí àwọn ọkọ̀ mìíràn ṣe ń gba ọ̀nà yìí tí àwọn ọlọ́pàá kò sì ṣe ohunkóhun fún wọn.
Ó wòye pé àwọn ọlọ́pàá nílò láti yàgò fún bí wọ́n ṣe máa ń ṣe pẹ̀lú aráàlú nítorí ìfìyàjẹni lọ́nà àìtọ́ ni ọ̀rọ̀ náà jọ́.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 1
“Wọ́n ṣe ìkọlù sí èmi àti ọmọ mi tó jẹ́ ọmọdé pẹ̀lú ìbọn lọ́wọ́ nígbà tí a kò hu ìwà ọ̀daràn.”
“Àwọn ọlọ́pàá tó lé ní ọgbọ̀n ni wọ́n wà lórí èmi àti ọmọ mi nìkan nínú ojò.”
Bákan náà ni ọmọ Laide Bakare tí òun náà wà nínú fídíò tí ìyá rẹ̀ ṣe ṣàlàyé pé níṣe ni ẹ̀rù ba òun nígbà tí àwọn ọlọ́pàá náà ń gbé òun lọ nínú ọkọ̀ ìyá òun.
Ó ní òun kò rí ìyá òun bá sọ̀rọ̀ nígbà tí wọ́n ń gbé òun lọ nínú ọkọ̀ rẹ̀ nítorí inú ọkọ̀ náà ni àwọn fóònù ìyá òun wà.
Ó sọ pé àwọn ọlọ́pàá náà gbé òun lọ sí àgọ́ wọn tí ìyá òun sì wá bá àwọn níbẹ̀ nígbà tó fi fóònù èèyàn kan pé òun láti mọ ibi tí òun wà.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 2
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Eko fèsì
Ẹ̀wẹ̀, iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti fèsì sí ẹ̀sùn tí Laide Bakare fi kan àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ náà.
Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Eko, Benjamin Hundeyin nínú àtẹ̀jáde kan tó fi sórí ìkànnì ayélujára X rẹ̀ ní Laide Bakare ṣẹ̀ sófin tó dé ètò ìrìnnà ní ìpínlẹ̀ Eko ni wọ́n fi mu.
Hundeyin ṣàlàyé pé Laide Bakare gba ọ̀nà BRT tí kò yẹ kó gbà ni àwọn ọlọ́pàá náà fi mu tí wọ́n sì jáwèé fún-un láti lọ san owó ìtanràn tó yẹ.
Ó ní Laide Bakare mọ̀ọ́mọ̀ láti má tẹ̀lé àwọn ọlọ́pàá nígbà tí wọ́n ń gbé ọkọ̀ rẹ̀ lọ sí ọgbà LAMATA láti san owó ìtanràn tí wọ́n fun.
Ó sọ pé lẹ́yìn tó san owó náà ni wọ́n gbé ọkọ̀ rẹ̀ fún pẹ̀lú ìwé ẹ̀rí pé ó san owó náà láì sí pé àwọn ọlọ́pàá náà fi ọwọ́ kàn-án tàbí fìyà jẹ ẹnikẹ́ni lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún.

Oríṣun àwòrán, @BenHundeyin/X















