Kọ́lẹ́rà: Wo fídíò àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa bí o ṣe lè dáàbò bo ara rẹ̀ lọ́wọ́ àìsàn tó ń gbilẹ̀ ní Nàìjíríà lọ́wọ́ yí

Àkọlé fídíò, Wo fídíò àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa bí o ṣe lè dáàbò bo ara rẹ̀ lọ́wọ́ Kọ́lẹ́rà
Kọ́lẹ́rà: Wo fídíò àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa bí o ṣe lè dáàbò bo ara rẹ̀ lọ́wọ́ àìsàn tó ń gbilẹ̀ ní Nàìjíríà lọ́wọ́ yí

Ọpọ eeyan lo ti padanu ẹmi wọn sọwọ aarun onigba meji lorilẹede Naijiria bayii, ọna si wa lati fopin aarun yii ni agbegbe wa.

Orisirisi nnkan lo le sokunfa aarun onigba meji sugbọn eyi to le ke n ka ju ni ai si imọ toto.

Ajọ to n gbogun ti ajakalẹ arun lorilẹede Naijiria, NCDC ṣalaye pe, kọlẹra to ṣẹṣẹ bẹ silẹ laipẹ yii ti mu ẹmi eeyan to le ni ogoji lọ.

Ẹwẹ, adari NCDC, dokita Jide Idris ti sọ pe awọn ko ni abẹrẹ ajẹsara to to lati koju arun kọlẹra.

Amọ o fi kun pe awọn ti bere abẹrẹ naa lọwọ awọn ajọ to n pin lọfẹẹ lati oke okun bo tilẹ jẹ pe ajọ naa ko mọ igba ti abẹrẹ ọhun yoo wọlesi Naijiria.

Kọlẹra to maa n mu eeyan nipasẹ ounjé tabi omi ẹlẹgbin maa n fa igbọnsẹ gbuuru, eebi ati ki omi ara gbẹ pata.

Ajọ NCDC to n ri si didena arun sọ pe arun onigba-meji yii ti de ipinlẹ ọgbọn (30) ninu ipinlẹ mẹrindinlogoji (36) ti Naijiria ni.

Wọn ni o si ti kan ijọba ibilẹ mẹrindinlọgọrun-un (96).

Koda, nipinlẹ Eko to jẹ ibusọ aje Naijiria, eeyan mẹẹẹdogun (15) lo ti ku latari arun yii.

Eeyan mẹtadinlogun mi-in ni akọsilẹ si tun wa pe Kọlẹra ti mu niluu naa.

Bakan naa ni wọn ni apẹẹrẹ t

Bí o bá ń rí àwọn ǹnkan wọ̀nyí nípa kọ́lẹ́rà, àpẹẹrẹ ni

Gẹgẹ bi ajọ ‘National Health Service’ (NHS) to n ri si ilera ni UK ṣe wi, eyi ni awọn apẹẹrẹ arun Kọlẹra:

  • Igbọnsẹ olomi gbuuru ti yoo mu ọ maa paara ile igbọnsẹ.
  • Aarẹ ara
  • Inu rírun
  • Ki omi gbẹ lara (dehydration)