Èèyàn mẹ́wàá ló ti kú níbi ìkọlù ọlọ́pàá àtàwọn ọ̀dọ́ ‘Gen Z’ tó ń ṣèwọ́de

Aworan awọn oluwọde

Oríṣun àwòrán, EPA-EFE/REX/SHUTTERSTOCK

O kere tan, eeyan mẹwaa lo ti ku ninu ikọlu to waye laarin awọn ọlọpaa atawọn ọdọ Gen Z to n ṣe iwọde niluu Nairobi lorilẹede Kenya.

Ọkan lara awọn oṣiṣẹ eleto ilera lo fidi ọrọ naa mulẹ fun ileeṣẹ iroyin Reuters.

Iroyin sọ pe o ṣeeṣe ki iye awọn to ti ku ṣi tun pọ si tori awọn ọlọpaa ko tii dawọ ikọlu wọn sawọn olufẹhonuhan duro.

Awọn eeyan n ri bi ọkọ anbulansi ṣe n gbe awọn to farapa lọ loju titi fun itọju.

Bi iwọde yii ṣe n tẹsiwaju lawọn eeyan n pin fidio rẹ kaakiri ori ayelujara.

Ninu fidio kan to wa lori itakun ayelujara X ni fidio kan ti ṣafihan bi awọn ọkunrin kan ṣe n gbiyanju lati wo ọpa ti asia wa lori rẹ nile aṣofin lulẹ.

Bakan naa ni fidio ọhun tun ṣafihan bi ẹlomiran ṣe fi ipa gba ilẹkun ile aṣofin agba ti awọn eeyan ṣi n pariwo labẹ lẹ.

Aworan awọn olufẹhonuhan

Oríṣun àwòrán, Reuters

Aworan oluwọde

Oríṣun àwòrán, EPA-EFE/REX/SHUTTERSTOCK

O kere tan eeyan marunlelogoji to farapa ni wọn ti gbe lọ si ile iwosan ijọba Kenyatta national hospital to wa niluu Nairobi to jẹ ile iwosan to tobi julọ lorilẹede Kenya.

Awọn alaṣẹ ile iwosan naa sọ loju opo X wọn pe awọn eeyan kan n gba itọju nigba tawọn dokita n ṣiṣẹ abẹ fawọn mii ti wọn gbe wa.

Ile iwosan naa sọ pe obinrin meje lo wa ninu awọn to farapa ti wọn gbe wa naa, amọ, ko ti i si ẹni to ti gbẹmi mi.